ORIN 61
Ẹ Tẹ̀ Síwájú, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí
- 1. Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pinnu - Láti máa fìgboyà wàásù lákòókò yìí. - Èṣù ń ta kò wá, ó sì ńgbógun. - Àmọ́, a dúró ṣinṣin ti Jèhófà. - (ÈGBÈ) - Ẹ tẹ̀ síwájú, Ẹlẹ́rìí onígboyà. - Ẹ máa yọ̀ pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́. - Ẹ sọ fáráyé pé Párádísè dé tán. - Ìjọba Ọlọ́run yóò bù kún wa. 
- 2. Ìránṣẹ́ Jáà, má ṣe gbé ayé fàájì. - Ṣọ́ra fún ìfẹ́ ayé, má ṣe bíi tiwọn. - Má jẹ́ kí wọ́n kó èérí bá ọ. - Jẹ́ adúróṣinṣin títí dé òpin. - (ÈGBÈ) - Ẹ tẹ̀ síwájú, Ẹlẹ́rìí onígboyà. - Ẹ máa yọ̀ pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́. - Ẹ sọ fáráyé pé Párádísè dé tán. - Ìjọba Ọlọ́run yóò bù kún wa. 
- 3. Wọ́n ń pẹ̀gàn Ọlọ́run àt’Ìjọba rẹ̀. - Wọ́n ń bà á lórúkọ jẹ́, wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa. - Ká jẹ́ kórúkọ rẹ̀ di mímọ́. - Ẹ jẹ́ ká kéde rẹ̀ fún gbogbo ayé. - (ÈGBÈ) - Ẹ tẹ̀ síwájú, Ẹlẹ́rìí onígboyà. - Ẹ máa yọ̀ pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́. - Ẹ sọ fáráyé pé Párádísè dé tán. - Ìjọba Ọlọ́run yóò bù kún wa. 
(Tún wo Ẹ́kís. 9:16; Fílí. 1:7; 2 Tím. 2:3, 4; Jém. 1:27.)