ORIN 37
Máa Sin Jèhófà Tọkàntọkàn
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà Ọba Aláṣẹ, - Ìwọ ni mo fẹ́ máa gbọ́ràn sí. - Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ tọkàntọkàn. - Ìwọ ni màá fi ayé mi sìn. - Mo fẹ́ràn ìránnilétí rẹ, - Mo sì ń pàwọn àṣẹ rẹ mọ́. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an. - Màá fi gbogbo ọkàn mi sìn ọ́. 
- 2. Gbogbo iṣẹ́ rẹ ń gbé ọ ga; - Láyé lọ́run, wọ́n ń fògo rẹ hàn. - Èmi náà fẹ́ máa fokun mi - Kéde orúkọ rẹ fáráyé. - Màá fi gbogbo ayé mi sìn ọ́, - Màá sì jẹ́ olóòótọ́ sí ọ. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an. - Màá fi gbogbo ọkàn mi sìn ọ́. 
(Tún wo Diu. 6:15; Sm. 40:8; 113:1-3; Oníw. 5:4; Jòh. 4:34.)