ORIN 126
Wà Lójúfò, Dúró Gbọn-in, Jẹ́ Alágbára
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Wà lójúfò, kó o dúró gbọn-in, - Kó o sì jẹ́ alágbára. - Ó dájú pé a óò ṣẹ́gun, - Lábẹ́ ìdarí Jésù. - A ṣe tán láti pàṣẹ rẹ̀ mọ́ - Bá a ti ń bá a lọ láti jagun náà. - (ÈGBÈ) - Dúró gbọn-in, má ṣe yẹsẹ̀ láéláé! - Fara dà á títí dópin! 
- 2. Wà lójúfò, kó o máa ṣọ́ra; - Múra láti ṣègbọràn. - Ẹrú olóòótọ́, olóye, - Àwọn alàgbà ìjọ; - Wọ́n ti ṣe tán láti bójú tó - Àwọn àìní wa nípa tẹ̀mí. - (ÈGBÈ) - Dúró gbọn-in, má ṣe yẹsẹ̀ láéláé! - Fara dà á títí dópin! 
- 3. Ẹ wà lójúfò níṣọ̀kan; - Máa fìgboyà wàásù lọ, - Báwọn ọ̀tá tilẹ̀ ń gbógun, - A ó wàásù títí dópin. - Máa fayọ̀ sọ ìhìn rere náà, - Ọjọ́ Jèhófà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé! - (ÈGBÈ) - Dúró gbọn-in, má ṣe yẹsẹ̀ láéláé! - Fara dà á títí dópin! 
(Tún wo Mát. 24:13; Héb. 13:7, 17; 1 Pét. 5:8.)