ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jésù Di Mèsáyà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Lẹ́yìn tí Jòhánù batisí Jésù, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e lórí bí àdàbà

      Ẹ̀KỌ́ 74

      Jésù Di Mèsáyà

      Jòhánù ti ń wàásù fáwọn èèyàn pé: ‘Ẹnì kan tó tóbi jù mí lọ ń bọ̀.’ Nígbà tí Jésù pé ọmọ ọgbọ̀n (30) ọdún, ó wá sí Odò Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣèrìbọmi fáwọn èèyàn. Jésù fẹ́ kí Jòhánù ṣèrìbọmi fún òun, àmọ́ Jòhánù sọ pé: ‘Ìwọ ló yẹ kó o ṣèrìbọmi fún mi, kì í ṣe èmi ló yẹ kí n ṣèrìbọmi fún ẹ.’ Jésù wá sọ fún Jòhánù pé: ‘Jèhófà fẹ́ kó o ṣèrìbọmi fún mi.’ Torí náà, àwọn méjèèjì lọ sínú Odò Jọ́dánì, Jòhánù sì ri Jésù bọ inú omi náà pátápátá.

      Lẹ́yìn tí Jésù jáde kúrò nínú omi, ó gbàdúrà sí Jèhófà. Bí Jésù ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, ọ̀run ṣí sílẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tó dà bí ẹyẹ àdàbà sì bà lé Jésù. Jèhófà wá sọ̀rọ̀ látọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”

      Nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bà lé Jésù, Jésù di Kristi tàbí Mèsáyà. Àkókò wá tó báyìí fún Jésù láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Jèhófà rán an pé kó wá ṣe láyé.

      Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lọ sí aginjù, ó sì lo ogójì (40) ọjọ́ níbẹ̀. Nígbà tó kúrò ní aginjù, ó lọ sọ́dọ̀ Jòhánù. Bí Jòhánù ṣe rí Jésù lọ́ọ̀ọ́kán, ó sọ pé: ‘Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run ló ń bọ̀ yìí, òun ló sì máa kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.’ Ohun tí Jòhánù sọ yìí jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà. Àmọ́, ṣé o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù nígbà tó wà ní aginjù? Jẹ́ ká wò ó.

      “Ohùn kan sì dún láti ọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, àyànfẹ́; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.’”​—Máàkù 1:11

      Ìbéèrè: Kí nìdí tí Jésù fi ṣèrìbọmi? Kí nìdí tí Jòhánù fi sọ pé Jésù ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run?

      Mátíù 3:13-17; Máàkù 1:9-11; Lúùkù 3:21-23; Jòhánù 1:29-34; Àìsáyà 42:1; Hébérù 10:7-9

  • Èṣù Dán Jésù Wò
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù kọ̀ láti bẹ́ sílẹ̀ láti ibi tó ga jù ní tẹ́ńpìlì

      Ẹ̀KỌ́ 75

      Èṣù Dán Jésù Wò

      Jésù kọ̀ láti sọ òkúta di búrẹ́dì

      Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, ẹ̀mí mímọ́ darí ẹ̀ lọ sí aginjù. Jésù ò jẹ nǹkan kan fún ogójì (40) ọjọ́, ebi wá ń pa á gan-an. Bí Èṣù ṣe wá dán an wò nìyẹn, ó sọ fún Jésù pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́ lóòótọ́, sọ fáwọn òkúta yìí pé kí wọ́n di búrẹ́dì.’ Àmọ́, Jésù fi ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ dá a lóhùn, ó sọ pé: ‘A ti kọ ọ́ pé kì í ṣe oúnjẹ nìkan ló máa jẹ́ ká wà láàyè. A gbọ́dọ̀ máa fetí sí gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ.’

      Lẹ́yìn ìyẹn, Èṣù tún sọ fún un pé: ‘Tó o bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run lóòótọ́, bẹ́ sílẹ̀ láti ibi tó ga jù ní tẹ́ńpìlì yìí. Torí a ti kọ ọ́ pé Ọlọ́run á rán àwọn áńgẹ́lì ẹ̀ láti gbé ọ, kó o má bàa ṣubú.’ Jésù tún fi Ìwé Mímọ́ dá a lóhùn, ó sọ pé: ‘A ti kọ ọ́ pé, o ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.’

      Jésù kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba gbogbo ìjọba ayé tí Sátánì fẹ́ fún un

      Lẹ́yìn ìyẹn, Sátánì tún fi gbogbo ìjọba ayé yìí han Jésù, àti gbogbo ọrọ̀ àti ògo tó wà láyé, ó wá sọ fún un pé: ‘Màá fún ẹ ní gbogbo nǹkan yìí tó o bá jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.’ Jésù wá sọ fún Sátánì pé: ‘Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé, Jèhófà Ọlọ́run nìkan lo gbọ́dọ̀ jọ́sìn.’

      Èṣù kúrò lọ́dọ̀ Jésù, lẹ́yìn náà àwọn áńgẹ̀lì wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n sì fún un lóúnjẹ. Látìgbà yẹn ni Jésù ti ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run. Iṣẹ́ tí Jèhófà ní kí Jésù wá ṣe láyé nìyẹn. Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wọn, torí náà gbogbo ibi tí Jésù bá ń lọ làwọn èèyàn máa ń tẹ̀ lé e lọ.

      ‘Tí Èṣù bá ń pa irọ́, ṣe ló ń sọ irú ẹni tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́, torí pé òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ.’​—Jòhánù 8:44

      Ìbéèrè: Ọ̀nà mẹ́ta wo ni Èṣù gbà dán Jésù wò? Báwo ni Jésù ṣe dá Èṣù lóhùn?

      Mátíù 4:1-11; Máàkù 1:12, 13; Lúùkù 4:1-15; Diutarónómì 6:13, 16; 8:3; Jémíìsì 4:7

  • Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù fi ẹgba lé àwọn àgùntàn àti màlúù kúrò nínú tẹ́ńpìlì, ó sì da tábìlì àwọn tó ń ṣẹ́ owó nù

      Ẹ̀KỌ́ 76

      Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì

      Ní ọdún 30 Sànmánì Kristẹni, Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá sílùú yẹn láti wá ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Ara nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe nígbà àjọyọ̀ yìí ni pé wọ́n máa ń fi ẹran rúbọ nínú tẹ́ńpìlì. Àwọn kan máa ń mú ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ wá látilé, àwọn míì sì máa ń rà á ní Jerúsálẹ́mù.

      Nígbà tí Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì, ó rí àwọn tó ń ta màlúù, àgùntàn àti àdàbà níbẹ̀. Ńṣe làwọn èèyàn yẹn ń ṣòwò nínú ilé Jèhófà. Ẹ ò rí i pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà rárá! Kí ni Jésù wá ṣe? Ó fi okùn ṣe ẹgba, ó sì fi lé àwọn àgùntàn àti màlúù náà jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì. Ó da tábìlì àwọn tó ń ṣẹ́ owó nù, owó wọn sì dà sílẹ̀. Jésù wá sọ fáwọn tó ń ta ẹyẹ àdàbà níbẹ̀ pé: ‘Ẹ kó nǹkan yìí kúrò níbí! Ẹ má sọ ilé Bàbá mi di ọjà!’

      Ẹnu ya àwọn èèyàn sí ohun tí Jésù ṣe yìí. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wá rántí àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa Mèsáyà pé: ‘Ìtara fún ilé Jèhófà máa gbà mí lọ́kàn.’

      Nígbà tó di ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù tún lé àwọn tó ń tajà kúrò nínú tẹ́ńpìlì. Ìdí sì ni pé Jésù ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ ilé Bàbá ẹ̀ di ibi ìtajà.

      “Ẹ ò lè jẹ́ ẹrú Ọlọ́run àti Ọrọ̀.”​—Lúùkù 16:13

      Ìbéèrè: Kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí àwọn tó ń ta màlúù, àgùntàn àti àdàbà nínú tẹ́ńpìlì? Kí nìdí tí Jésù fi ṣe bẹ́ẹ̀?

      Mátíù 21:12, 13; Máàkù 11:15-17; Lúùkù 19:45, 46; Jòhánù 2:13-17; Sáàmù 69:9

  • Obìnrin kan Wá Pọn Omi Nínú Kànga
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù ń bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀ níbi kànga Jékọ́bù

      Ẹ̀KỌ́ 77

      Obìnrin Kan Wá Pọn Omi Nínú Kànga

      Lẹ́yìn tí àjọyọ̀ Ìrékọjá parí, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ń rìnrìn àjò pa dà sílùú Gálílì, àmọ́ ìlú Samáríà ni wọ́n gbà kọjá. Nígbà tí wọ́n détòsí ìlú Síkárì, Jésù sinmi nídìí kànga kan tí wọ́n ń pè ní kànga Jékọ́bù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sì lọ ra oúnjẹ wá.

      Kò pẹ́ sígbà yẹn, obìnrin kan wá pọn omi. Jésù sọ fún un pé: ‘Fún mi lómi mu.’ Obìnrin náà sọ pé: ‘Kí ló dé tó ò ń bá mi sọ̀rọ̀? Ọmọ ìlú Samáríà ni mí. Àwọn Júù kì í sì í bá àwa ọmọ ìlú Samáríà sọ̀rọ̀.’ Jésù wá sọ fún un pé: ‘Ká ní o mọ̀ mí ni, ìwọ lo máa béèrè omi lọ́wọ́ mi, màá sì fún ẹ lómi ìyè.’ Obìnrin náà wá sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ ẹ ò yé mi o, torí kò sí korobá kankan lọ́wọ́ ẹ.’ Jésù sọ fún un pé: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá mu omi tí mo sọ yìí, òùngbẹ ò ní gbẹ ẹ́ mọ́ láé.’ Obìnrin náà wá sọ fún un pé: “Ọ̀gá, fún mi ní omi yìí.”

      Jésù sọ fún un pé: ‘Lọ pe ọkọ ẹ wá.’ Obìnrin náà dáhùn pé: ‘Mi ò ní ọkọ.’ Jésù sọ fún un pé: ‘Òótọ́ lo sọ. O ti ní ọkọ márùn-ún rí, ọkùnrin tó o sì ń fẹ́ báyìí kì í ṣe ọkọ ẹ.’ Obìnrin náà wá sọ fún un pé: ‘Mo ti rí i pé wòlíì ni ẹ́. Àwọn èèyàn wa gbà pé a lè jọ́sìn lórí òkè ńlá yìí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin Júù sọ pé Jerúsálẹ́mù nìkan ló yẹ ká ti máa jọ́sìn. Mo mọ̀ pé tí Mèsáyà bá dé, ó máa kọ́ wa bó ṣe yẹ ká máa jọ́sìn.’ Jésù wá sọ ohun kan tí kò tíì sọ fún ẹnikẹ́ni rí, ó ní: ‘Èmi ni Mèsáyà náà.’

      Jésù ń bá àwọn ará Samáríà sọ̀rọ̀

      Bí obìnrin yẹn ṣe sáré lọ sínú ìlú nìyẹn, ó sì lọ sọ fún àwọn ará Samáríà pé: ‘Ó dà bíi pé mo ti rí Mèsáyà o, torí pé gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi ló mọ̀. Ẹ wá lọ wò ó!’ Bí gbogbo wọn ṣe tẹ̀ lé e pa dà sídìí kànga nìyẹn, wọ́n sì tẹ́tí sóhun tí Jésù kọ́ wọn.

      Àwọn ará Samáríà yẹn ní kí Jésù wá sílùú àwọn. Torí náà, Jésù lo ọjọ́ méjì pẹ̀lú wọn, ó ń kọ́ wọn, àwọn èèyàn náà sì gba ohun tó sọ gbọ́. Wọ́n wá ń sọ fún obìnrin náà pé: ‘Lẹ́yìn tá a ti gbọ́ ohun tí ọkùnrin yìí ń sọ, a ti wá mọ̀ pé, òun ló máa gba aráyé là lóòótọ́.’

      “‘Máa bọ̀!’ kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́, gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”​—Ìfihàn 22:17

      Ìbéèrè: Kí nìdí tó fi ya obìnrin ará Samáríà yẹn lẹ́nu pé Jésù bá a sọ̀rọ̀? Kí ni Jésù sọ fún un?

      Jòhánù 4:1-42

  • Jésù Wàásù Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù àti ọmọ ẹ̀yìn kan ń wàásù

      Ẹ̀KỌ́ 78

      Jésù Wàásù Nípa Ìjọba Ọlọ́run

      Kò pẹ́ tí Jésù ṣèrìbọmi ló bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pé: ‘Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.’ Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ń tẹ̀ lé e bó ṣe ń wàásù nílùú Gálílì àti Jùdíà. Nígbà tó pa dà sílùú Násárẹ́tì tí wọ́n bí i sí, ó lọ sínú sínágọ́gù, ó ṣí àkájọ ìwé Àìsáyà, ó sì kà á sókè. Ó ní: ‘Jèhófà ti fún mi ní ẹ̀mí mímọ́ kí n lè wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn.’ Àmọ́, kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn fẹ́ kí Jésù máa ṣe iṣẹ́ ìyanu, ìdí tí Jèhófà fi fún un ní ẹ̀mí mímọ́ ni pé kó lè máa wàásù ìhìn rere. Ó wá sọ fáwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀ pé: ‘Lónìí, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ.’

      Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù lọ sí Òkun Gálílì, ibẹ̀ ló ti rí mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ apẹja. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ tẹ̀ lé mi, màá sọ yín di apẹja èèyàn.’ Orúkọ àwọn mẹ́rin náà ni Pétérù, Áńdérù, Jémíìsì àti Jòhánù. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù pè wọ́n ni wọ́n fi iṣẹ́ ẹja pípa sílẹ̀, tí wọ́n sì tẹ̀ lé e. Wọ́n ń wàásù nípa Ìjọba Jèhófà ní gbogbo ìlú Gálílì. Wọ́n wàásù nínú sínágọ́gù, nínú ọjà àti lójú ọ̀nà. Àmọ́ gbogbo ibi tí wọ́n ń lọ ni èrò ti ń tẹ̀ lé wọn. Ibi gbogbo làwọn èèyàn ti gbọ́ nípa Jésù, kódà wọ́n gbọ́ nípa ẹ̀ nílùú Síríà.

      Nígbà tó yá, Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan ní agbára láti wo àwọn èèyàn sàn kí wọ́n sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Àwọn míì sì wà pẹ̀lú ẹ̀ bó ṣe ń wàásù láti ìlú kan sí ìlú míì àti láti abúlé kan sí òmíì. Àwọn obìnrin olóòótọ́ kan máa ń ran Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lọ́wọ́. Lára wọn ni Màríà Magidalénì, Jòánà, Súsánà àtàwọn míì.

      Lẹ́yìn tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ dáadáa, ó rán wọn jáde láti lọ wàásù. Bí wọ́n ṣe ń wàásù ní gbogbo ìlú Gálílì, ọ̀pọ̀ èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn wọ́n sì ṣèrìbọmi. Àwọn tó fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn pọ̀ débi pé Jésù fi wọ́n wé àwọn èso tó ti pọ́n tó yẹ kí wọ́n ká. Ó wá sọ pé: ‘Ẹ gbàdúrà sí Jèhófà pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde kí wọ́n lè kórè oko náà.’ Nígbà tó yá, ó yan àádọ́rin (70) lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó sì rán wọn jáde ní méjì-méjì kí wọ́n lè wàásù ní gbogbo agbègbè Jùdíà. Wọ́n ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn. Nígbà tí wọ́n pa dà dé, inú wọn dùn láti sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Jésù. Ẹ ò rí i pé kò sóhun tí Èṣù lè ṣe láti dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró.

      Jésù rí i dájú pé òun kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun dáadáa kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ lẹ́yìn tí òun bá pa dà sí ọ̀run. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ wàásù ìhìn rere náà kárí ayé. Ẹ máa kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kẹ́ ẹ sì máa batisí wọn.’

      “Mo tún gbọ́dọ̀ kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú míì, torí pé nítorí èyí la ṣe rán mi.”​—Lúùkù 4:43

      Ìbéèrè: Iṣẹ́ wo ni Jésù gbé fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀? Báwo ni iṣẹ́ tí Jésù gbé fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣe rí lára wọn?

      Mátíù 4:17-25; 9:35-38; 28:19, 20; Máàkù 1:14-20; Lúùkù 4:14-21; 8:1-3; 10:1-22

  • Jésù Ṣe Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìyanu
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Àwọn aláìsàn ń wá sọ́dọ̀ Jésù kára wọn lè yá

      Ẹ̀KỌ́ 79

      Jésù Ṣe Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìyanu

      Jésù wá sáyé kó lè wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ká lè mọ àwọn ohun tí Jésù máa ṣe tó bá di Ọba Ìjọba yẹn, Jèhófà fún un ní ẹ̀mí mímọ́ kó lè ṣe iṣẹ́ ìyanu. Gbogbo àìsàn ni Jésù lè wò. Gbogbo ibi tó bá wà làwọn aláìsàn ti máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́, gbogbo wọn ló sì máa ń wò sàn. Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn adití ń gbọ́ràn, àwọn arọ ń rìn, kódà Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára àwọn èèyàn. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé etí aṣọ Jésù lásán ni wọ́n fọwọ́ kàn, ara wọn máa yá. Gbogbo ibi tí Jésù bá ń lọ làwọn èèyàn máa ń tẹ̀ lé e lọ. Kódà, nígbà tí Jésù fẹ́ dá wà, àwọn èèyàn ò fi í sílẹ̀, síbẹ̀ kò lé wọn.

      Nígbà kan, àwọn èèyàn gbé arọ kan wá sílé tí Jésù wà. Àmọ́, èrò pọ̀ nínú ilé náà débi pé kò sọ́nà láti wọlé. Torí náà, wọ́n dá ihò sí orí ilé náà, wọ́n sì sọ ọkùnrin náà kalẹ̀ síbi tí Jésù wà. Jésù wá sọ fún ọkùnrin náà pé: ‘Dìde, kó o sì máa rìn.’ Nígbà táwọn èèyàn rí i pé ọkùnrin náà ti ń rìn, ẹnu yà wọ́n gan-an.

      Jésù tún lọ sínú abúlé kan, ó sì rí àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó jẹ́ adẹ́tẹ̀. Àwọn ọkùnrin náà dúró sí ọ̀ọ́kán, wọ́n sì ń pariwo pé: ‘Jésù, ṣàánú wa!’ Nígbà yẹn, òfin ò gba àwọn adẹ́tẹ̀ láyè láti sún mọ́ àwọn míì. Jésù wá sọ fáwọn ọkùnrin náà pé kí wọ́n lọ sí tẹ́ńpìlì bí Òfin Jèhófà ṣe sọ pé káwọn adẹ́tẹ̀ máa ṣe tí ara wọn bá ti yá. Bí wọ́n ṣe ń lọ síbẹ̀, ara gbogbo wọn yá. Nígbà tí ọ̀kan lára wọn rí i pé ara òun ti yá, ó pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo. Àbí ẹ ò rí nǹkan, nínú àwọn mẹ́wàá tí Jésù wò sàn, ẹyọ kan péré ló pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀.

      Obìnrin kan tún wà tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìlá (12), ó sì ń wá ìwòsàn lójú méjèèjì. Obìnrin náà wá sáàárín èrò níbi tí Jésù wà, ó sì fọwọ́ kan etí aṣọ ẹ̀. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ara ẹ̀ yá. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Ta ló fọwọ́ kàn mí?” Àyà obìnrin náà já gan-an, àmọ́ ó wá sọ́dọ̀ Jésù, ó sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Jésù wá sọ̀rọ̀ tó fọkàn ẹ̀ balẹ̀, ó sọ pé: ‘Ọmọbìnrin, máa lọ ní àlàáfíà.’

      Lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin kan tí orúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Jáírù bẹ Jésù pé: ‘Jọ̀ọ́ wá sílé mi, ọmọbìnrin mi ń ṣàìsàn tó le gan-an.’ Àmọ́, kí Jésù tó dé ilé Jáírù, ọmọ náà ti kú. Nígbà tó débẹ̀, ó rí i tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sunkún. Jésù wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má sunkún mọ́, ó kàn ń sùn ni.’ Ó wá mú ọwọ́ ọmọ náà dání, ó sì sọ pé: “Ọmọ, dìde!” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọmọ náà dìde, Jésù sì sọ fáwọn òbí ẹ̀ pé kí wọ́n fún un lóúnjẹ. Ó dájú pé inú àwọn òbí ẹ̀ máa dùn gan-an!

      Jésù jí ọmọ Jáírù dìde

      ‘Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ àti agbára yàn án, ó sì lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ó ń ṣe rere, ó sì ń wo gbogbo àwọn tí Èṣù ń ni lára sàn, torí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.’​—Ìṣe 10:38

      Ìbéèrè: Kí ló mú kí Jésù lágbára láti wo gbogbo àìsàn? Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Jáírù?

      Mátíù 9:18-26; 14:36; Máàkù 2:1-12; 5:21-43; 6:55, 56; Lúùkù 6:19; 8:41-56; 17:11-19

  • Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù àtàwọn àpọ́sítẹ́lì ẹ̀ méjìlá

      Ẹ̀KỌ́ 80

      Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá

      Ní báyìí tí Jésù ti ń wàásù fún nǹkan bí ọdún kan àtààbọ̀, ó ti tó àkókò fún un láti yan àwọn tí wọ́n á jọ máa ṣiṣẹ́, ìpinnu ńlá sì nìyẹn. Àwọn wo ló wá máa yàn? Àwọn wo ló máa dá lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó ìjọ Kristẹni? Jésù ò fẹ́ dá ṣe àwọn ìpinnu yẹn, ó fẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà. Torí náà, ó lọ sórí òkè kan kó lè dá wà, ó sì gbàdúrà láti òru mọ́jú. Nígbà tílẹ̀ mọ́, Jésù pe àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó sì yan méjìlá (12) lára wọn láti di àpọ́sítélì. Èwo nínú wọn lo rántí orúkọ ẹ̀? Ó dáa, orúkọ wọn ni Pétérù, Áńdérù, Jémíìsì, Jòhánù, Fílípì, Bátólómíù, Tọ́másì, Mátíù, Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Tádéọ́sì, Símónì àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù.

      Áńdérù, Pétérù, Fílípì, Jémíìsì

      Áńdérù, Pétérù, Fílípì, Jémíìsì

      Àwọn Méjìlá (12) yìí láá máa rìnrìn àjò pẹ̀lú Jésù. Lẹ́yìn tí Jésù ti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó rán wọn jáde pé kí wọ́n lọ wàásù. Jèhófà fún wọn lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kí wọ́n sì mú àwọn aláìsàn lára dá.

      Jòhánù, Mátíù, Bátólómíù, Tọ́másì

      Jòhánù, Mátíù, Bátólómíù, Tọ́másì

      Jésù pe àwọn Méjìlá (12) yìí ní ọ̀rẹ́ òun, ó sì fọkàn tán wọn. Àwọn Farisí gbà pé àwọn àpọ́sítélì yẹn ò lọ síléèwé àti pé tálákà ni wọ́n. Àmọ́, Jésù kọ́ wọn dáadáa kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ wọn láṣeyọrí. Àwọn ló wà pẹ̀lú ẹ̀ láwọn àsìkò tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n wà pẹ̀lú Jésù kó tó kú, wọ́n sì tún wà pẹ̀lú ẹ̀ lẹ́yìn tó jíǹde. Gálílì tó jẹ́ ìlú Jésù lèyí tó pọ̀ jù lára wọn ti wá, àwọn kan sì ti níyàwó.

      Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Júdásì Ìsìkáríọ́tù, Tádéọ́sì, Símónì

      Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Júdásì Ìsìkáríọ́tù, Tádéọ́sì, Símónì

      Àwọn àpọ́sítélì yìí kì í ṣe ẹni pípé, torí náà wọ́n máa ń ṣe àṣìṣe. Nígbà míì, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ láìronú, wọ́n máa ń ṣe àwọn ìpinnu tí kò dáa. Ìgbà míì wà tí wọn kì í ní sùúrù, wọ́n sì máa ń jiyàn nípa ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọ̀gá láàárín wọn. Àmọ́, èèyàn dáadáa ni wọ́n, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àwọn ló máa bẹ̀rẹ̀ ìjọ Kristẹni lẹ́yìn tí Jésù bá lọ sí ọ̀run.

      “Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi.”​—Jòhánù 15:15

      Ìbéèrè: Àwọn méjìlá wo ni Jésù yàn láti jẹ́ àpọ́sítélì? Isẹ́ wo ni Jésù fún àwọn àpọ́sítélì ẹ̀?

      Mátíù 10:1-10; Máàkù 3:13-19; 10:35-40; Lúùkù 6:12-16; Jòhánù 15:15; 20:24, 25; Ìṣe 2:7; 4:13; 1 Kọ́ríńtì 9:5; Éfésù 2:20-22

  • Ìwàásù Orí Òkè
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù ń wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyan lórí òkè

      Ẹ̀KỌ́ 81

      Ìwàásù Orí Òkè

      Lẹ́yìn tí Jésù yan àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà, ó sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè, ó sì lọ síbi táwọn èrò rẹpẹtẹ jókòó sí. Àwọn èèyàn náà wá láti Gálílì, Jùdíà, Tírè, Sídónì, Síríà àtàwọn ìlú míì tó wà ní ìsọdá Odò Jọ́dánì. Wọ́n gbé àwọn tó ní oríṣiríṣi àìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù àtàwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu, ó sì wo gbogbo wọn sàn. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀. Ó sọ àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe tá a bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà, ká sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́, a ò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá ò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, ká sì máa ṣe dáadáa sí wọn títí kan àwọn tó kórìíra wa pàápàá.

      Jésù sọ pé: ‘Kì í ṣe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ nìkan ló yẹ kó o nífẹ̀ẹ́, ó yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá ẹ náà, kó o sì máa dárí jì wọ́n. Tẹ́nì kan bá sọ pé o ṣẹ òun, tètè lọ bá a, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó má bínú. Ohun tó o bá sì fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí ẹ ni kíwọ náà máa ṣe sí wọn.’

      Jésù ń wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyan lórí òkè

      Jésù tún sọ pé ká má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ owó ká wa lára jù. Ó sọ pé: ‘Ó dáa kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà ju kéèyàn jẹ́ olówó lọ. Torí pé àwọn olè lè jí owó èèyàn lọ, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè jí àwọn ìbùkún tá à ń rí látinú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ má dààmú jù nípa ohun tẹ́ ẹ máa jẹ, ohun tẹ́ ẹ máa mu tàbí ohun tẹ́ ẹ máa wọ̀. Ẹ wo àwọn ẹyẹ, wọn ò ṣiṣẹ́, àmọ́ Jèhófà máa ń rí i pé wọ́n ní oúnjẹ tó pọ̀ láti jẹ. Tẹ́ ẹ bá ń da ara yín láàmú jù, ìyẹn ò ní fi ọjọ́ kan kún ọjọ́ ayé yín. Ẹ rántí pé Jèhófà mọ gbogbo ohun tẹ́ ẹ nílò.’

      Àwọn èèyàn yẹn ò rẹ́ni tó sọ̀rọ̀ bíi Jésù rí. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn ò kọ́ wọn láwọn ohun tí Jésù kọ́ wọn. Àmọ́, kí ló mú kí Jésù mọ èèyàn kọ́ dáadáa? Ìdí ni pé ohun tí Jèhófà sọ ló ń kọ́ àwọn èèyàn.

      “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí, ara sì máa tù yín.”​—Mátíù 11:29

      Ìbéèrè: Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa ṣe sáwọn èèyàn?

      Mátíù 4:24–5:48; 6:19-34; 7:28, 29; Lúùkù 6:17-31

  • Jésù Kọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Ẹ̀ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Gbàdúrà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Farisí kan ń gbàdúrà níta gbangba, àwọn èèyàn sì ń wò ó

      Ẹ̀KỌ́ 82

      Jésù Kọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Ẹ̀ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Gbàdúrà

      Àwọn Farisí máa ń ṣe nǹkan torí káwọn èèyàn lè máa yìn wọ́n. Tí wọ́n bá ṣoore fáwọn èèyàn, ojú ayé lásán ni. Kódà, wọ́n tún máa ń gbàdúrà níta gbangba. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń há àwọn àdúrà tó gùn sórí, wọ́n á wá máa gba àdúrà yẹn sókè lójú ọ̀nà àti nínú sínágọ́gù. Ìdí nìyẹn tẹ́nu fi ya àwọn èèyàn nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má ṣe gbàdúrà bí àwọn Farisí. Wọ́n rò pé Ọlọ́run á gbọ́ àdúrà wọn torí bí wọ́n ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ tó pọ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń gbàdúrà, Jèhófà lò ń bá sọ̀rọ̀, kì í ṣe èèyàn. Má ṣe máa sọ ohun kan náà ṣáá tó o bá ń gbàdúrà. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kó o sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ gangan.’

      Ọmọkùnrin kan kúnlẹ̀, ó sì ń gbàdúrà

      Jésù wá sọ pé, ‘Bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ máa gbàdúrà nìyí: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.” ’ Jésù tún sọ fún wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wọn lóúnjẹ tí wọ́n máa jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, pé kí Jèhófà dárí jì wọ́n, kó sì fún wọn láwọn nǹkan míì.

      Jésù sọ pé: ‘Ẹ má ṣe dákẹ́ àdúrà. Gbogbo ìgbà ni kẹ́ ẹ máa bẹ Jèhófà Bàbá yín pé kó fún yín láwọn nǹkan rere. Gbogbo òbí ló máa ń fẹ́ fún àwọn ọmọ wọn lóhun tó dáa. Torí náà, tọ́mọ ẹ bá ní kó o fún òun ní búrẹ́dì, ṣé wàá fún un ní òkúta? Àbí tó bá ní kó o fún òun ní ẹja, ṣé wàá fún un ní ejò?’

      Jésù wá sọ ẹ̀kọ́ tó fẹ́ kí wọ́n kọ́, ó ní: ‘Tẹ́ ẹ bá mọ bẹ́ ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín lẹ́bùn rere, ṣẹ́ ẹ wá rò pé Jèhófà, Bàbá yín tó wà lọ́run ò ní fún yín ní ẹ̀mí mímọ́ tẹ́ ẹ bá ní kó fún yín? Tiyín ni pé kẹ́ ẹ ṣáà ti béèrè lọ́wọ́ ẹ̀.’ Ṣó o máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù? Àwọn nǹkan wo lo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣe fún ẹ?

      “Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín.”​—Mátíù 7:7

      Ìbéèrè: Báwo ni Jésù ṣe ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbàdúrà? Ṣó o máa ń gbàdúrà nípa àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí ẹ?

      Mátíù 6:2-18; 7:7-11; Lúùkù 11:13

  • Jésù Fún Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lóúnjẹ
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Àwọn àpọ́sítélì ń pín oúnjẹ fún ọ̀pọ̀ èèyàn

      Ẹ̀KỌ́ 83

      Jésù Fún Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lóúnjẹ

      Nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá lọ́dún 32 Sànmánì Kristẹni, Jésù rán àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ jáde kí wọ́n lọ wàásù. Nígbà tí wọ́n fi máa pa dà dé, ó ti rẹ̀ wọ́n, torí náà, àwọn àti Jésù jọ wọ ọkọ̀ ojú omi lọ síbì kan tí wọ́n ti lè sinmi ní Bẹtisáídà. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ, wọ́n rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá dúró dè wọ́n níbẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù fẹ́ dá wà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì ẹ̀, ó wá àyè fáwọn èèyàn náà. Ó mú àwọn tó ń ṣàìsàn nínú wọn lára dá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Látàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni Jésù fi kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: ‘Ebi á ti máa pa àwọn èèyàn náà, sọ pé kí wọ́n máa lọ kí wọ́n lè lọ ra nǹkan tí wọ́n máa jẹ.’

      Ọmọkùnrin kan gbé apẹ̀rẹ̀ tí búrẹ́dì àti ẹja wà nínú ẹ̀ fún Jésù

      Jésù sọ pé: ‘Kò di dandan pé kí wọ́n lọ. Ẹ fún wọn lóúnjẹ níbí.’ Àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wá bi í pé: ‘Ṣó o fẹ́ ká lọ ra oúnjẹ fún wọn ni?’ Ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ tó ń jẹ́ Fílípì wá sọ fún un pé: ‘Tá a bá ní ká ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn èèyàn yìí, owó kékeré kọ́ la máa ná o!’

      Jésù bi wọ́n pé: ‘Báwo loúnjẹ tá a ní ṣe pọ̀ tó?’ Áńdérù sọ pé: ‘A ní búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja kéékèèké méjì, ó sì dájú pé ìyẹn ò lè débì kankan rárá.’ Jésù wá sọ pé: ‘Ẹ kó búrẹ́dì àti ẹja náà wá.’ Ó ní káwọn èèyàn náà jókòó sórí koríko ní àwùjọ àádọ́ta (50) àti ọgọ́rùn-ún (100). Jésù mú búrẹ́dì àti ẹja náà, ó wojú ọ̀run, ó sì gbàdúrà. Ó wá gbé oúnjẹ náà fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀, wọ́n sì pín in fáwọn èèyàn náà. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ló wà níbẹ̀, láìka àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. Gbogbo wọn ló sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn àpọ́sítélì náà kó oúnjẹ tó ṣẹ́ kù jọ sínú apẹ̀rẹ̀ kó má bàa ṣòfò. Odindi apẹ̀rẹ̀ méjìlá ló ṣẹ́ kù! Iṣẹ́ ìyanu ńlá mà nìyẹn o! Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

      Inú àwọn èèyàn náà dùn débi pé wọ́n fẹ́ fi Jésù jọba. Àmọ́, Jésù mọ̀ pé Jèhófà kò tíì fẹ́ kóun di ọba. Torí náà, ó ní káwọn èèyàn náà máa lọ, ó sì ní káwọn àpọ́sítélì òun sọdá sí òdìkejì Òkun Gálílì. Nígbà tí wọ́n wọnú ọkọ̀ ojú omi, Jésù dá lọ sórí òkè. Ṣó o mọ ìdí tó fi dá lọ síbẹ̀? Ìdí ni pé ó fẹ́ lọ gbàdúrà sí Bàbá ẹ̀. Kò sí bí iṣẹ́ Jésù ṣe pọ̀ tó, ó máa ń wáyè láti gbàdúrà.

      “Ẹ má ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó ń ṣègbé, àmọ́ ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó wà fún ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọmọ èèyàn máa fún yín.”​—Jòhánù 6:27

      Ìbéèrè: Kí ni Jésù ṣe tó jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn? Kí nìyẹn jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?

      Mátíù 14:14-22; Lúùkù 9:10-17; Jòhánù 6:1-15

  • Jésù Rìn Lórí Omi
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù ń rìn lórí omi, ó sì ní kí Pétérù máa bọ̀ lọ́dọ̀ òun

      Ẹ̀KỌ́ 84

      Jésù Rìn Lórí Omi

      Yàtọ̀ sí pé Jésù lè mú àwọn èèyàn lára dá, tó sì lè jí òkú dìde, ó tún lágbára lórí ìjì ìyẹn atẹ́gùn tó lágbára àti òjò. Lọ́jọ́ kan, Jésù lọ gbàdúrà lórí òkè, lẹ́yìn tó gbàdúrà tán, ó rí ìjì kan tó ń jà lórí Òkun Gálílì. Inú ọkọ̀ ojú omi làwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wà nígbà yẹn, wọ́n ń gbìyànjú láti wa ọkọ̀ náà kí ìjì má bàa dà á nù. Jésù wá sọ̀ kalẹ̀, ó sì ń rìn lórí omi lọ sọ́dọ̀ wọn. Nígbà tí wọ́n rí ẹnì kan tó ń rìn lórí omi, àyà wọn já, àmọ́, Jésù sọ fún wọn pé: ‘Èmi ni, ẹ má bẹ̀rù.’

      Jésù ń rìn lórí omi, ó sì ní kí Pétérù máa bọ̀ lọ́dọ̀ òun

      Pétérù wá sọ pé: ‘Olúwa, tó bá jẹ́ ìwọ ni lóòótọ́, sọ pé kí n wá bá ẹ lórí omi.’ Jésù sọ fún un pé: ‘Máa bọ̀.’ Bí ìjì yẹn ṣe ń jà, Pétérù jáde nínú ọkọ̀, ó sì rìn lọ bá Jésù lórí omi. Àmọ́, bó ṣe ń sún mọ́ Jésù, ó wo ìjì náà, àyà ẹ̀ sì já, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú omi nìyẹn. Pétérù wá pariwo pé: ‘Olúwa, gbà mí!’ Jésù di ọwọ́ ẹ̀ mú, ó sì sọ fún un pé: ‘Kí ló dé tó o fi ń ṣiyèméjì? Ṣé o ò nígbàgbọ́ ni?’

      Jésù àti Pétérù wá jọ pa dà sínú ọkọ̀ náà, ìjì náà sì dáwọ́ dúró. Ṣé o mọ bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára àwọn àpọ́sítélì Jésù? Ohun tí wọ́n sọ ni pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́ lóòótọ́.”

      Kì í ṣe àsìkò yìí nìkan ni Jésù lo agbára lórí ìjì. Nígbà kan tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wà nínú ọkọ̀ ojú omi, Jésù sùn sí ẹ̀yìn ọkọ̀ náà. Bí Jésù ṣe ń sùn lọ́wọ́, ìjì bẹ̀rẹ̀ sí í jà, omi sì kún inú ọkọ̀ wọn. Àwọn àpọ́sítélì wá sáré jí Jésù, wọ́n sì ń pariwo pé: ‘Olùkọ́, a ti fẹ́ kú o! Ràn wá lọ́wọ́!’ Ni Jésù bá dìde, ó sì sọ fún òkun náà pé: “Dákẹ́ jẹ́ẹ́!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìjì àti òkun náà sì ṣe wọ̀ọ̀. Jésù wá bi àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ò nígbàgbọ́ ni?” Àwọn àpọ́sítélì náà bá ń sọ láàárín ara wọn pé: “Ìjì àti òkun pàápàá ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.” Àwọn àpọ́sítélì náà kẹ́kọ̀ọ́ pé tí wọ́n bá fọkàn tán Jésù pátápátá, wọn ò ní bẹ̀rù ohunkóhun.

      “Ibo ni mi ò bá wà, ká ní mi ò ní ìgbàgbọ́ pé màá rí oore Jèhófà ní ilẹ̀ alààyè?”​—Sáàmù 27:13

      Ìbéèrè: Kí nìdí tí Pétérù fi bẹ̀rẹ̀ sí í rì? Kí làwọn àpọ́sítélì kọ́ lọ́dọ̀ Jésù?

      Mátíù 8:23-27; 14:23-34; Máàkù 4:35-41; 6:45-52; Lúùkù 8:22-25; Jòhánù 6:16-21

  • Jésù Wo Ẹnì Kan Sàn Lọ́jọ́ Sábáàtì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Àwọn Farisí ń da ìbéèrè bo ọkùnrin kan tó jẹ́ afọ́jú tẹ́lẹ̀

      Ẹ̀KỌ́ 85

      Jésù Wo Ẹnì Kan Sàn Lọ́jọ́ Sábáàtì

      Àwọn Farisí kórìíra Jésù, wọ́n sì ń wá bí wọ́n ṣe máa mú un. Wọ́n sọ pé kò gbọ́dọ̀ wo èèyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. Lọ́jọ́ Sábáàtì kan, Jésù rí afọ́jú kan tó ń tọrọ owó lójú ọ̀nà. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: ‘Ẹ máa rí bí agbára Ọlọ́run ṣe máa ran ọkùnrin yìí lọ́wọ́.’ Ni Jésù bá po itọ́ mọ́ iyẹ̀pẹ̀, ó sì fi sójú ọkùnrin náà. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún un pé: ‘Lọ fọ ojú rẹ nínú adágún Sílóámù.’ Ọkùnrin yẹn ṣe bẹ́ẹ̀, bó ṣe ríran fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé ẹ̀ nìyẹn.

      Ẹnu ya àwọn èèyàn gan-an. Wọ́n sì ń sọ pé: ‘Ṣé ọkùnrin tó máa ń tọrọ owó nìyí àbí ẹni yìí kàn jọ ọ́ ni?’ Ọkùnrin náà sọ pé: ‘Èmi náà ni.’ Àwọn èèyàn wá bi í pé: ‘Báwo ló ṣe wá ríran?’ Nígbà tó ṣàlàyé fún wọn, wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisí.

      Ọkùnrin náà sọ fáwọn Farisí pé: ‘Jésù fi iyẹ̀pẹ̀ pa ojú mi, ó sì ní kí n lọ fọ̀ ọ́ kúrò. Mo ṣe bẹ́ẹ̀, mo sì ti ríran báyìí.’ Àwọn Farisí wá sọ pé: ‘Tí Jésù bá ń wo èèyàn sàn lọ́jọ́ sábáàtì, á jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lagbára ẹ̀ ti wá.’ Àmọ́, àwọn kan sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ lagbára ẹ̀ ti wá, kò ní lè woni sàn rárá.’

      Àwọn Farisí pe àwọn òbí ọkùnrin náà, wọ́n sì bi wọ́n pé: ‘Báwo ni ọmọ yín ṣe ríran?’ Ẹ̀rù ń ba àwọn òbí ọkùnrin náà torí pé àwọn Farisí ti sọ pé tí ẹnikẹ́ni bá gba Jésù gbọ́, àwọn máa lé ẹni náà kúrò nínú sínágọ́gù. Torí náà, àwọn òbí ẹ̀ sọ pé: ‘A ò mọ bó ṣe ṣẹlẹ̀. Ẹ béèrè lọ́wọ́ ẹ̀.’ Àwọn Farisí wá bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bo ọkùnrin náà títí tó fi sọ pé: ‘Mo ti sọ gbogbo ohun tí mo mọ̀ fún yín, kí ló dé tí ẹ tún ń bi mí ní ìbéèrè? Inú bí àwọn Farisí yẹn gan-an, bí wọ́n ṣe ju ọkùnrin náà síta nìyẹn.

      Jésù lọ wá ọkùnrin yẹn, ó sì bi í pé: ‘Ṣé o nígbàgbọ́ nínú Mèsáyà?’ Ọkùnrin náà sọ pé: ‘Màá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ tí mo bá mọ̀ ọ́n.’ Jésù wá sọ fún un pé: ‘Èmi ni Mèsáyà náà?’ Ẹ ò rí i pé Jésù láàánú àwọn èèyàn gan-an. Kì í ṣe pé Jésù kàn la ojú ọkùnrin yẹn nìkan, ó tún ràn án lọ́wọ́ kó lè nígbàgbọ́.

      “Ẹ ti ṣàṣìṣe, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run.”​—Mátíù 22:29

      Ìbéèrè: Báwo ni Jésù ṣe ran ọkùnrin afọ́jú kan lọ́wọ́? Kí nìdí táwọn Farisí fi kórìíra Jésù?

      Jòhánù 9:1-41

  • Jésù Jí Lásárù Dìde
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Lásárù àtàwọn arábìnrin rẹ̀ Màríà àti Màtá

      Ẹ̀KỌ́ 86

      Jésù Jí Lásárù Dìde

      Jésù láwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mẹ́ta tó ń gbé ní Bẹ́tánì. Orúkọ wọn ni Lásárù, Màríà àti Màtá. Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wọ́n. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí Jésù wà ní òdì kejì Odò Jọ́dánì, Màríà àti Màtá ránṣẹ́ sí Jésù pé: ‘Ara Lásárù ò yá, ó sì le díẹ̀. Jọ̀ọ́, tètè máa bọ̀!’ Àmọ́, Jésù ò lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó dúró fún ọjọ́ méjì, lẹ́yìn ìyẹn ó wá sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: ‘Ẹ jẹ́ ká lọ sí Bẹ́tánì. Lásárù ń sùn, mo sì fẹ́ lọ jí i dìde.’ Àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé oorun ni Lásárù ń sùn, ìyẹn á jẹ́ kára ẹ̀ tètè yá.’ Jésù wá kúkú sọ fún wọn pé: ‘Lásárù ti kú.’

      Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú ni Jésù tó dé Bẹ́tánì. Àwọn èèyàn sì ti pé jọ láti tu Màríà àti Màtá nínú. Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ti dé, ó sáré lọ bá a. Ó wá sọ pé: ‘Olúwa, ká ní o tètè dé ni, arákùnrin mi ì bá má kú.’ Jésù wá sọ fún un pé: ‘Arákùnrin rẹ máa jí pa dà. Ṣé o gbà mí gbọ́, Màtá? Màtá sọ pé: ‘Mo gbà gbọ́ pé ó máa dìde nígbà àjíǹde.’ Jésù wá sọ fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.”

      Ni Màtá bá sáré lọ bá Màríà, ó sì sọ fún un pé: ‘Jésù ti dé.’ Màríà wá sáré lọ bá Jésù, àwọn èrò náà sì tẹ̀ lé e. Ló bá wólẹ̀ fún Jésù, ó sì bú sẹ́kún. Ó sọ pé: ‘Olúwa, ká ní o tètè de ni, arákùnrin mi ì bá má kú.’ Jésù rí bọ́rọ̀ náà ṣe ń dun Màríà tó, lòun náà bá bú sẹ́kún. Nígbà táwọn èrò náà rí i pé Jésù ń sunkún, wọ́n sọ pé: ‘Jésù mà nífẹ̀ẹ́ Lásárù gan-an o!’ Àmọ́, àwọn kan ń ronú pé: ‘Kí nìdí tí kò fi gba ọ̀rẹ́ ẹ̀ là kó má bàa kú?’ Kí ni Jésù máa ṣe báyìí?

      Jésù lọ síbi tí wọ́n sin Lásárù sí, òkúta ńlá kan ni wọ́n fi dí ibẹ̀. Jésù wá sọ pé: ‘Ẹ yí òkúta náà kúrò.’ Màtá sọ pé: ‘Ó mà ti pé ọjọ́ mẹ́rin! Á ti máa rùn.’ Síbẹ̀, wọ́n yí òkúta náà kúrò, Jésù wá gbàdúrà pé: ‘Bàbá, mo dúpẹ́ pé ò ń tẹ́tí sí mi. Mo mọ̀ pé gbogbo ìgbà lo máa ń tẹ́tí sí mi, àmọ́ mò ń gbàdúrà sókè kí gbogbo àwọn èèyàn yìí lè mọ̀ pé ìwọ lo rán mi.’ Ó wá pariwo pé: “Lásárù, jáde wá!” Ṣó o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Ńṣe ni Lásárù jáde wá láti inú ibi tí wọ́n sin ín sí pẹ̀lú gbogbo aṣọ tí wọ́n fi dì í. Jésù wá sọ pé: “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kó máa lọ.”

      Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó rí ohun tí Jésù ṣe yìí bẹ̀rẹ̀ sí í nígbàgbọ́ nínú ẹ̀. Àmọ́, àwọn kan lọ sọ ohun tí Jésù ṣe fáwọn Farisí. Látìgbà yẹn lọ, ńṣe làwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n á ṣe pa Lásárù àti Jésù. Bí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù tó ń jẹ́ Júdásì Ìsìkáríọ́tù ṣe yọ́ lọ bá àwọn Farisí nìyẹn, ó wá bi wọ́n pé: ‘Èló lẹ máa fún mi tí mo bá ṣe ọ̀nà bẹ́ ẹ ṣe máa rí Jésù mú?’ Wọ́n gbà láti fún un ní ọgbọ̀n (30) owó fàdákà, Júdásì sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa fa Jésù lé àwọn Farisí lọ́wọ́.

      “Ọlọ́run tòótọ́ ni Ọlọ́run tó ń gbà wá là; Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì ń gbani lọ́wọ́ ikú.”​—Sáàmù 68:20

      Ìbéèrè: Sọ bí Jésù ṣe jí Lásárù dìde. Kí làwọn Farisí fẹ́ ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lásárù?

      Mátíù 26:14-16; Jòhánù 11:1-53; 12:10

  • Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́

      Ẹ̀KỌ́ 87

      Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

      Ọdọọdún làwọn Júù máa ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe é ni pé kí wọ́n lè máa rántí bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íjíbítì tó ń fi wọ́n ṣẹrú àti bó ṣe mú wọn wá sí Ilẹ̀ Ìlérí. Lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá nínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n jẹun tán, Jésù sọ pé: ‘Ọ̀kan lára yín máa dà mí.’ Ẹnu ya àwọn àpọ́sítélì, wọ́n sì bi Jésù pé: ‘Ta ni ẹni náà?’ Jésù sọ pé: ‘Ẹni tí mo bá fún ní búrẹ́dì ni ẹni náà.’ Ó wá fún Júdásì Ìsìkáríọ́tù ní búrẹ́dì. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Júdásì dìde, ó sì jáde kúrò nínú yàrá náà.

      Lẹ́yìn náà, Jésù gbàdúrà, ó pín búrẹ́dì mélòó kan sí wẹ́wẹ́, ó sì fún àwọn àpọ́sítélì tó kù. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ búrẹ́dì yìí. Ó dúró fún ara mi tí màá fi rúbọ nítorí yín.’ Lẹ́yìn ìyẹn, ó gbàdúrà sórí wáìnì, ó sì gbé e fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀. Ó wá sọ pé: ‘Ẹ mu wáìnì yìí. Ó dúró fún ẹ̀jẹ̀ mi tí màá fi rúbọ kí Ọlọ́run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì. Mo ṣèlérí fún yín pé ẹ máa jọba pẹ̀lú mi ní ọ̀run. Ẹ máa ṣe èyí ní ọdọọdún láti fi rántí mi.’ Lónìí, àwa ọmọlẹ́yìn Jésù ṣì máa ń pàdé pọ̀ láti ṣe ìrántí ikú ẹ̀ lọ́dọọdún. Ìpàdé yìí la wá mọ̀ sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.

      Lẹ́yìn oúnjẹ náà, àwọn àpọ́sítélì tó kù bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn nípa ẹni tó máa jẹ́ ọ̀gá láàárín wọn. Jésù wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹni tó máa jẹ́ ọ̀gá láàárín yín lẹni tó rí ara ẹ̀ bí ẹni tó kéré jù láàárín yín.’

      Jésù tún sọ fún wọn pé: ‘Ọ̀rẹ́ mi ni yín. Gbogbo ohun tí Bàbá mi fẹ́ kí n sọ fún yín ni mò ń sọ fún yín. Láìpẹ́, mo máa pa dà sọ́dọ̀ Bàbá mi ní ọ̀run. Ẹ̀yín ṣì máa wà láyé, àmọ́ àwọn èèyàn máa mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn mi ni yín tí wọ́n bá rí bẹ́ ẹ ṣe nífẹ̀ẹ́ ara yín. Torí náà, ẹ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí èmi náà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.’

      Lẹ́yìn gbogbo ohun tí Jésù ṣe yìí, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó ní kí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè jọ máa ṣiṣẹ́ pọ̀ ní àlàáfíà. Ó tún gbàdúrà pé kí orúkọ Jèhófà di mímọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ kọrin ìyìn sí Jèhófà, wọ́n sì jáde lọ. Àsìkò ti wá tó báyìí táwọn èèyàn máa mú Jésù.

      “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, torí Baba yín ti fọwọ́ sí i láti fún yín ní Ìjọba náà.”​—Lúùkù 12:32

      Ìbéèrè: Ìlérí wo ni Jésù ṣe fún àwọn àpọ́sítélì ẹ̀? Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Jésù kọ́ àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?

      Mátíù 26:20-30; Lúùkù 22:14-26; Jòhánù 13:1, 2, 26, 30, 34, 35; 15:12-19; 17:3-26

  • Wọ́n Mú Jésù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Júdásì dalẹ̀ Jésù nínú ọgbà Gẹ́tísémánì

      Ẹ̀KỌ́ 88

      Wọ́n Mú Jésù

      Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ rìn gba àárín àwọn òkè tó wà ní Kídírónì kọjá, wọ́n sì lọ sí Òkè Ólífì. Òru ni, òṣùpá sì mọ́lẹ̀ yòò. Nígbà tí wọ́n dé ọgbà Gẹ́tísémánì, Jésù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dúró síbí, kẹ́ ẹ sì máa ṣọ́nà.’ Jésù wá rìn wọnú ọgbà náà, ó sì kúnlẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ìdààmú ńlá ni Jésù wà, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ.” Jèhófà wá rán áńgẹ̀lì kan sí i láti fún un lókun. Nígbà tí Jésù pa dà sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì, ó rí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n ń sùn. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dìde! Kì í ṣe àsìkò yìí ló yẹ kẹ́ ẹ máa sùn! Àkókò ti tó báyìí tí wọ́n máa fi mí lé àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́.’

      Júdásì gba owó

      Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn Júdásì dé, òun ló sì ṣáájú àwọn èrò tí wọ́n kó idà àti igi dání. Ó mọ ibi tí wọ́n ti máa rí Jésù, torí pé Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ sábà maá ń wá síbẹ̀. Júdásì ti sọ fáwọn ọmọ ogun yẹn pé òun máa fi Jésù hàn wọ́n láàárín àwọn àpọ́sítélì. Bí wọ́n ṣe dé báyìí, ọ̀dọ̀ Jésù ló lọ tààràtà, ó sì sọ pé: ‘Mo kí ẹ́ o, Olùkọ́,’ ó sì fẹnu kò ó lẹ́nu. Jésù wá sọ fún un pé: ‘Júdásì, ò ń fẹnu kò mí lẹ́nu kí wọ́n lè mú mi, àbí?’

      Jésù sún mọ́ iwájú, ó sì bi àwọn èrò náà pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” Wọ́n sọ pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.” Ó wá sọ fún wọn pé: “Èmi ni.” Bó ṣe sọ bẹ́ẹ̀, àwọn èrò náà sún mọ́ ẹ̀yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀. Jésù tún bi wọ́n pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” Wọ́n sì tún sọ pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.” Jésù wá sọ fún wọn pé: ‘Mo ti sọ fún yín pé èmi ni. Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn mi máa lọ.’

      Nígbà tí Pétérù rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó fa idà kan yọ, ó sì gé etí Málíkọ́sì, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ àlùfáà àgbà. Àmọ́, Jésù fọwọ́ kan etí ọkùnrin náà, ó sì wò ó sàn. Jésù wá sọ fún Pétérù pé: ‘Dá idà rẹ pa dà, torí pé tó o bá ń fi idà jà, idà ni wọ́n máa fi pa ìwọ náà.’ Bí àwọn ọmọ ogun ṣe mú Jésù nìyẹn, wọ́n so ọwọ́ ẹ̀, àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ sì sá lọ. Àwọn èrò náà mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Ánásì olórí àlùfáà. Ánásì béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ Jésù, ó sì rán an lọ sọ́dọ̀ Káyáfà Àlùfáà Àgbà. Àmọ́, kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì?

      “Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”​—Jòhánù 16:33

      Ìbéèrè: Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Gẹ́tísémánì? Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Jésù ṣe lálẹ́ ọjọ́ yẹn?

      Mátíù 26:36-57; Máàkù 14:32-50; Lúùkù 22:39-54; Jòhánù 18:1-14, 19-24

  • Pétérù Sọ Pé Òun Ò Mọ Jésù Rí
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Nínú ọgbà Káyáfà, Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù rí

      Ẹ̀KỌ́ 89

      Pétérù Sọ Pé Òun Ò Mọ Jésù Rí

      Nígbà tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wà ní yàrá òkè tí wọ́n ti jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, Jésù sọ fún wọn pé: ‘Gbogbo yín máa fi mí sílẹ̀ lálẹ́ òní.’ Pétérù wá sọ pé: ‘Èmi kọ́! Kódà, tí gbogbo àwọn tó kù bá fi ẹ́ sílẹ̀, mi ò ní fi ẹ́ sílẹ̀ láéláé.’ Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: ‘Kí àkùkọ tó kọ lóru yìí, ìgbà mẹ́ta ni wàá sọ pé o ò mọ̀ mí rí.’

      Nígbà táwọn ọmọ ogun mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Káyáfà, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn àpọ́sítélì ló sá lọ. Àmọ́, méjì lára wọn ń tẹ̀ lé èrò náà lọ. Pétérù wà lára àwọn méjì náà. Ó tẹ̀ lé wọn wọ inú ọgbà ilé Káyáfà, ó sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ iná tí wọ́n dá sílẹ̀ kára ẹ̀ lè móoru. Torí pé ibẹ̀ mọ́lẹ̀, ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó ń ṣe ìránṣẹ́ níbẹ̀ rí ojú Pétérù, ó sì sọ pé: ‘Mo mọ̀ ẹ́! Mo máa ń rí ẹ pẹ̀lú Jésù!’

      Pétérù sọ pé: ‘Rárá o, èmi kọ́! Ohun tó ò ń sọ ò tiẹ̀ yé mi.’ Pétérù wá lọ sẹ́nu ọ̀nà ìta. Àmọ́, obìnrin míì tún rí i, ó sì sọ fáwọn tó wà níbẹ̀ pé: ‘Ọkùnrin yìí wà lára àwọn tó máa ń tẹ̀ lé Jésù!’ Pétérù sọ pé: ‘Mi ò tiẹ̀ mọ Jésù rí rárá!’ Ọkùnrin míì níbẹ̀ tún sọ pé: ‘Ọ̀kan lára wọn ni ẹ́! Èdè tó ò ń sọ ti jẹ́ ká mọ̀ pé ará Gálílì ni ẹ́, bí Jésù sì ṣe máa ń sọ̀rọ̀ nìyẹn.’ Àmọ́ ńṣe ni Pétérù búra, tó tún sọ pé: ‘Àní sẹ́, mi ò mọ̀ ọ́n rí!’

      Bí Pétérù ṣe sọ̀rọ̀ yẹn tán báyìí ni àkùkọ kọ. Jésù yíjú láti wo Pétérù, ojú wọn sì ṣe mẹ́rin. Ó wá rántí ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀, bó ṣe bọ́ síta nìyẹn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún gidigidi.

      Ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa gbẹ́jọ́ Jésù ní ilé Káyáfà. Wọ́n ti pinnu pé àwọn máa pa Jésù ni, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá irọ́ tí wọ́n máa pa mọ́ ọn. Àmọ́, wọn ò rí nǹkan kan. Nígbà tó yá, Káyáfà bi Jésù ní tààràtà pé: ‘Ṣé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́?’ Jésù sọ pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’ Káyáfà sọ pé: ‘Kí la tún ń wá? Ọ̀rọ̀ burúkú ni ọkùnrin yìí ń sọ!’ Ìgbìmọ̀ náà wá gbà pé kí wọ́n pa Jésù. Wọ́n gbá Jésù létí, wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n fi nǹkan bò ó lójú, wọ́n gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́, wọ́n sì ń sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé wòlíì ni ẹ́ lóòótọ́, dárúkọ ẹni tó gbá ẹ!’

      Nígbà tílẹ̀ mọ́, wọ́n mú Jésù lọ sínú yàrá tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ti máa ń gbẹ́jọ́, wọ́n sì tún bi í pé: ‘Ṣé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́?’ Jésù sọ pé: ‘Ẹ̀yin fúnra yín sọ pé Ọmọ Ọlọ́run ni mí.’ Bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ̀rọ̀ burúkú nìyẹn, wọ́n wá mú un lọ sáàfin Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà Róòmù. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

      “Wákàtí náà . . . ti dé, nígbà tí wọ́n máa tú ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ká sí ilé rẹ̀, ẹ sì máa fi èmi nìkan sílẹ̀. Àmọ́ mi ò dá wà, torí pé Baba wà pẹ̀lú mi.”​—Jòhánù 16:32

      Ìbéèrè: Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọgbà ilé Káyáfà? Irọ́ wo ni wọ́n pa mọ́ Jésù kí wọ́n lè pa á?

      Mátíù 26:31-35, 57–27:2; Máàkù 14:27-31, 53–15:1; Lúùkù 22:55-71; Jòhánù 13:36-38; 18:15-18, 25-28

  • Wọ́n Pa Jésù ní Gọ́gọ́tà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù wà lórí òpó igi, ọmọ ogun kan, Màríà, Jòhánù àtàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mí ì dúró nítòsí

      Ẹ̀KỌ́ 90

      Wọ́n Pa Jésù ní Gọ́gọ́tà

      Àwọn olórí àlùfáà mú Jésù lọ sáàfin gómìnà kan tó ń jẹ́ Pílátù. Nígbà tí Jésù débẹ̀, Pílátù bi àwọn àlùfáà náà pé: ‘Ohun búburú wo ni ọkùnrin yìí ṣe?’ Wọ́n dá a lóhùn pé: ‘Ó ń pe ara ẹ̀ lọ́ba!’ Pílátù wá bi Jésù pé: ‘Ṣé ìwọ ni Ọba àwọn Júù?’ Jésù dáhùn pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”

      Ni Pílátù bá ní kí wọ́n mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù alákòóso Gálílì, bóyá ó máa mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí Jésù ṣẹ̀. Àmọ́ Hẹ́rọ́dù náà ò rí ohun búburú kankan nípa Jésù, torí náà ó ní kí wọ́n mú un pa dà sọ́dọ̀ Pílátù. Pílátù wá sọ fáwọn èèyàn náà pé: ‘Èmi àti Hẹ́rọ́dù ò rí ohun búburú kankan nípa ọkùnrin yìí. Torí náà, màá tú u sílẹ̀ kó máa lọ.’ Àmọ́ àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: ‘Pa á! Pa á!’ Àwọn ọmọ ogun na Jésù lẹ́gba, wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n sì ń gbá a ní ẹ̀ṣẹ́. Wọ́n tún ṣe adé ẹ̀gún, wọ́n fi dé orí ẹ̀, wọ́n sì fi ṣe yẹ̀yẹ́ pé: ‘Ẹ ǹlẹ́ o, Ọba àwọn Júù!’ Pílátù tún lọ bá àwọn èèyàn náà, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Lójú tèmi, ọkùnrin yìí ò dẹ́ṣẹ̀ kankan.’ Ṣùgbọ́n wọ́n tún kígbe pé: “Kàn án mọ́gi!” Torí náà, Pílátù fa Jésù lé wọn lọ́wọ́ láti pa á.

      Wọ́n mú Jésù lọ síbì kan tí wọ́n ń pè ní Gọ́gọ́tà, wọ́n kàn án mọ́ òpó igi kan, wọ́n wá gbé igi náà dúró. Jésù wá gbàdúrà pé: ‘Baba, dárí jì wọ́n torí wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.’ Àwọn èèyàn ń fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́, gba ara rẹ là kó o sì bọ́ sílẹ̀ lórí igi yìí.’

      Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù sọ fún Jésù pé: “Rántí mi nígbà tó o bá dé inú Ìjọba ẹ.” Jésù sì ṣèlérí fún un pé: “O máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” Lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn, òkùnkùn ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà fún wákàtí mẹ́ta. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó igi tí wọ́n kan Jésù mọ́, Màríà ìyá Jésù náà wà pẹ̀lú wọn. Jésù wá sọ fún Jòhánù pé kó máa tọ́jú Màríà bí ìgbà tó ń tọ́jú ìyá ẹ̀ gangan.

      Níkẹyìn, Jésù sọ pé: “A ti ṣe é parí!” Ó tẹ orí ẹ̀ ba, ó sì kú. Lójijì, ilẹ̀ mì tìtì lọ́nà tó lágbára. Ohun ìyanu kan sì ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì, aṣọ ńlá kan tó wà láàárín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù lọ ya sí méjì látòkè délẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun tó wà níbẹ̀ wá sọ pé: ‘Dájúdájú Ọmọ Ọlọ́run nìyí.’

      “Bó ṣe wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di ‘bẹ́ẹ̀ ni’ nípasẹ̀ rẹ.”​—2 Kọ́ríńtì 1:20

      Ìbéèrè: Kí nìdí tí Pílátù fi jẹ́ kí wọ́n pa Jésù? Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn míì ṣe pàtàkì sí òun ju ti ara òun lọ?

      Mátíù 27:11-14, 22-31, 38-56; Máàkù 15:2-5, 12-18, 25, 29-33, 37-39; Lúùkù 23:1-25, 32-49; Jòhánù 18:28–19:30

  • Jésù Jíǹde
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Ó ya àwọn obìnrin kan lẹ́nu pé ibojì Jésù ṣófo

      Ẹ̀KỌ́ 91

      Jésù Jíǹde

      Lẹ́yìn tí Jésù kú, ọkùnrin olówó kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù gba àṣẹ lọ́wọ́ Pílátù láti gbé òkú Jésù kúrò lórí òpó igi náà. Ó wá fi aṣọ tó dáa di òkú Jésù, ó sì fi èròjà tó ń ta sánsán sí i, lẹ́yìn náà ló wá tẹ́ Jésù sínú ibojì, ó sì yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ibojì náà. Àwọn olórí àlùfáà wá sọ fún Pílátù pé: ‘Ẹ̀rù ń bà wá pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lè wá jí òkú ẹ̀ gbé kí wọ́n sì sọ pé ó ti jíǹde.’ Torí náà, Pílátù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dí ibojì náà, kẹ́ ẹ sì fi àwọn ẹ̀ṣọ́ síbẹ̀.’

      Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, àwọn obìnrin kan wá sí ibojì náà láàárọ̀ kùtù, wọ́n sì rí i pé wọ́n ti yí òkúta ńlá tó dí ẹnu ibojì náà kúrò. Nígbà tí wọ́n wọnú ibojì náà, áńgẹ́lì kan sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Jésù ti jíǹde. Ẹ lọ sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n lọ pàdé ẹ̀ ní Gálílì.’

      Màríà Magidalénì sáré lọ wá Pétérù àti Jòhánù. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹnì kan ti wá gbé òkú Jésù o!’ Ni Pétérù àti Jòhánù bá sáré lọ sí ibojì náà. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọn ò bá òkú Jésù níbẹ̀, wọ́n wá pa dà sílé wọn.

      Nígbà tí Màríà pa dà sí ibojì náà, ó rí áńgẹ́lì méjì nínú ibẹ̀, ó wá sọ fún wọn pé: ‘Mi ò mọ ibi tí wọ́n gbé Olúwa mi lọ.’ Lẹ́yìn náà, ó rí ọkùnrin kan, ó sì rò pé ẹni tó ń ṣọ́ ọgbà ni. Ó wá sọ fẹ́ni náà pé: ‘Ẹ jọ̀ọ́ sà, ẹ sọ ibi tẹ́ ẹ gbé òkú Jésù lọ fún mi.’ Àmọ́ bí ọkùnrin náà ṣe sọ pé, “Màríà!” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Màríà mọ̀ pé Jésù ni. Ló bá pariwo pé: “Olùkọ́!” ó sì dì mọ́ ọn. Jésù wá sọ fún un pé: ‘Lọ sọ fáwọn arákùnrin mi pé o ti rí mi.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Màríà sáré lọ bá àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, ó sì sọ fún wọn pé òun ti rí Jésù.

      Lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọmọlẹ́yìn méjì ń rìnrìn àjò láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Ẹ́máọ́sì. Ṣàdédé ni ọkùnrin kan dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìrìn àjò náà, ó sì béèrè pé kí ni wọ́n ń sọ. Àwọn ọmọlẹ́yìn náà dá a lóhùn pé: ‘Ṣé o ò tíì gbọ́ ni? Àwọn olórí àlùfáà pa Jésù níjẹta. Àmọ́ a gbọ́ táwọn obìnrin kan ń sọ pé ó ti jíǹde!’ Ni ọkùnrin yìí bá bi wọ́n pé: ‘Ṣé ẹ gba ohun táwọn wòlíì sọ gbọ́? Wọ́n ní Kristi máa kú ṣùgbọ́n ó máa jíǹde.’ Lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin náà ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún wọn. Nígbà tí wọ́n dé Ẹ́máọ́sì, àwọn ọmọlẹ́yìn náà sọ fún ọkùnrin yẹn pé kó wá báwọn jẹun. Nígbà tí ọkùnrin náà gbàdúrà sórí búrẹ́dì tí wọ́n fẹ́ jẹ ni wọ́n wá mọ̀ pé Jésù ni. Bó ṣe pòórá láàárín wọn nìyẹn.

      Àwọn ọmọlẹ́yìn méjèèjì wá sáré lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì níbi tí wọ́n kóra jọ sí ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n wà nínú ilé kan níbẹ̀, Jésù yọ sí gbogbo wọn lójijì. Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń lálàá. Jésù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ wo ọwọ́ mi, ẹ fọwọ́ kàn mí. Ìwé Mímọ́ ti sọ pé Kristi máa jíǹde.’

      “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.”​—Jòhánù 14:6

      Ìbéèrè: Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn obìnrin kan lọ sí ibojì Jésù? Kí ló ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà Ẹ́máọ́sì?

      Mátíù 27:57–28:10; Máàkù 15:42–16:8; Lúùkù 23:50–24:43; Jòhánù 19:38–20:23

  • Jésù Fara Han Àwọn Apẹja
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ̀rọ̀ bó ṣe ń yan ẹja lorí iná

      Ẹ̀KỌ́ 92

      Jésù Fara Han Àwọn Apẹja

      Lẹ́yìn ọjọ́ tí Jésù fara han àwọn àpọ́sítélì ẹ̀, Pétérù lọ sí òkun Gálílì láti lọ pẹja. Tọ́másì, Jémíìsì, Jòhánù àtàwọn ọmọlẹ́yìn míì sì tẹ̀ lé e lọ. Wọ́n wá ẹja láti alẹ́ mọ́jú, àmọ́ wọn ò rí ẹja kankan pa.

      Láàárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, wọ́n rí ọkùnrin kan tó dúró létí òkun. Ọkùnrin náà wá béèrè lọ́wọ́ wọn pé: ‘Ṣé ẹ rí ẹja pa?’ Wọ́n dáhùn pé: “Rárá!” Ọkùnrin náà wá sọ pé: ‘Ẹ ju nẹ́ẹ̀tì yín sápá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi náà.’ Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, nẹ́ẹ̀tì wọn kó ẹja tó pọ̀ gan-an débi pé wọn ò lè fà á sínú ọkọ̀ ojú omi wọn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jòhánù ti rí i pé Jésù ni ọkùnrin tó ń bá wọn sọ̀rọ̀, ló bá pariwo pé: “Olúwa ni!” Pétérù wá bẹ́ sínú omi, ó sì wẹ̀ lọ sétí òkun láti pàdé Jésù. Àwọn tó kù sì wa ọkọ̀ lọ bá a.

      Nígbà tí wọ́n dé etí òkun, wọ́n rí i pé ẹja àti búrẹ́dì wà lórí iná. Jésù ní kí wọ́n mú díẹ̀ wá nínú ẹja tí wọ́n pa, kí wọ́n sì fi kún èyí tó wà lórí iná. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ wá jẹ oúnjẹ àárọ̀ yín.’

      Pétérù sáré lọ bá Jésù létíkun, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù ń bọ̀ nínú ọkọ ojú omi

      Lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán, Jésù béèrè lọ́wọ́ Pétérù pé: ‘Ṣó o fẹ́ràn mi ju iṣẹ́ ẹja pípa lọ?’ Pétérù dáhùn pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn ẹ.’ Jésù sọ pé: ‘Torí náà máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.’ Jésù tún béèrè lẹ́ẹ̀kejì pé: ‘Pétérù, ṣó o fẹ́ràn mi?’ Pétérù dáhùn pé: ‘Olúwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn ẹ.’ Jésù sọ pé: ‘Máa ṣe olùṣọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.’ Jésù tún béèrè nígbà kẹta. Ẹ̀dùn ọkàn wá bá Pétérù, ó sì sọ pé: ‘Olúwa, o mọ ohun gbogbo. O mọ̀ pé mo fẹ́ràn ẹ.’ Jésù sọ fún un pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” Jésù tún sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.”

      “[Jésù] sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa tẹ̀ lé mi, màá sì sọ yín di apẹja èèyàn.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa àwọ̀n wọn tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.”​—Mátíù 4:19, 20

      Ìbéèrè: Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù ṣe fáwọn apẹja? Kí nìdí tí Jésù fi béèrè lọ́wọ́ Pétérù nígbà mẹ́ta pé: ‘Ṣó o nífẹ̀ẹ́ mi?’

      Jòhánù 21:1-19, 25; Ìṣe 1:1-3

  • Jésù Pa Dà sí Ọ̀run
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jésù ń gòkè lọ sọ́run, àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ sì ń wò ó

      Ẹ̀KỌ́ 93

      Jésù Pa Dà sí Ọ̀run

      Nígbà tí Jésù wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ní Gálílì, ó gbé iṣẹ́ pàtàkì kan lé wọn lọ́wọ́. Ó pàṣẹ fún wọn pé: ‘Ẹ lọ, kẹ́ ẹ sì máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. Ẹ máa kọ́ wọn ní ohun tí mo ti kọ́ ọ yín, kẹ́ ẹ sì ṣèrìbọmi fún wọn.’ Jésù wá ṣèlérí pé, ‘òun máa wà pẹ̀lú wọn.’

      Láàárín ogójì (40) ọjọ́ lẹ́yìn tí Jésù jí dìde, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó pọ̀ ní Gálílì àti Jerúsálẹ́mù. Ó kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì, ó sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wá bá a lórí Òkè Ólífì fúngbà ìkẹyìn, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dúró ní Jerúsálẹ́mù kẹ́ ẹ sì máa retí ohun tí Baba ṣèlérí.’

      Àmọ́ ohun tó ń sọ ò yé àwọn àpọ́sítélì ẹ̀. Wọ́n wá béèrè pé: ‘Ṣó o ti fẹ́ di Ọba Ísírẹ́lì báyìí ni?’ Jésù dáhùn pé: ‘Kò tíì tó àkókò tí Jèhófà yàn fún mi láti di Ọba. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, ẹ̀mí mímọ́ máa fún yín lágbára, ẹ ò sì máa wàásù nípa mi. Torí náà, ẹ lọ máa wàásù ní Jerúsálẹ́mù, Jùdíà, Samáríà àtàwọn apá ibi tó jìnnà jù láyé.’

      Lẹ́yìn náà, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í gòkè lọ sí ọ̀run títí ìkùukùu fi bò ó. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wá tẹ́jú mọ́ òkè, àmọ́ wọn ò rí i mọ́.

      Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà wá kúrò lórí Òkè Ólífì, wọ́n sì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n máa ń pàdé pọ̀ déédéé láti gbàdúrà nínú yàrá òkè nílé kan. Wọ́n ń dúró de Jésù kó wá sọ ohun tí wọ́n máa ṣe.

      “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”​—Mátíù 24:14

      Ìbéèrè: Àṣẹ wo ni Jésù pa fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀? Kí ló ṣẹlẹ̀ lórí Òkè Ólífì?

      Mátíù 28:16-20; Lúùkù 24:49-53; Jòhánù 20:30, 31; Ìṣe 1:2-14; 1 Kọ́ríńtì 15:3-6

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́