ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 17-21
Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Darí Èrò àti Ìṣe Rẹ
Jẹ́ amọ̀ tí ó rọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà
- Jèhófà lè fi ìmọ̀ràn tàbí ìbáwí tọ́ wa sọ́nà ká lè ní àwọn ìwà tó máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn 
- Bí amọ̀ tó rọ̀ ló ṣe yẹ ká rí lọ́wọ́ Jèhófà, ká sì jẹ́ onígbọràn 
- Jèhófà kì í fipá mú wa ṣe ohunkóhun 
Àrà tó bá wu amọ̀kòkò ló lè fi amọ̀ dá
- Torí pé Jèhófà ti fún wa lómìnira láti yan ohun tó bá wù wá, a lè gbà kí ó mọ wá tàbí ká kọ̀ jálẹ̀ 
- Ohun tá a bá ṣe nígbà tí Jèhófà bá ń tọ́ wa sọ́nà ló máa pinnu bí òun náà á ṣe máa ṣe sí wa