-
Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun AsánIlé Ìṣọ́—2014 | September 15
-
-
3, 4. (a) Àṣẹ wo ni Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà? (b) Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n ṣègbọ́ràn sí àṣẹ yẹn?
3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà láǹfààní láti máa wà láàyè títí láé, wọn kì í ṣe ẹ̀dá tí kò lè kú. Kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó, wọ́n gbọ́dọ̀ máa mí, kí wọ́n máa jẹun, kí wọ́n máa mu, kí wọ́n sì máa sùn. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, wọ́n gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Olùfúnni-ní-ìyè wọn tí wọ́n bá fẹ́ máa wà láàyè nìṣó. (Diu. 8:3) Tí wọ́n bá fẹ́ máa gbádùn ìgbésí ayé wọn nìṣó, wọ́n gbọ́dọ̀ gbà kí Ọlọ́run máa tọ́ wọn sọ́nà. Jèhófà mú kí èyí ṣe kedere sí Ádámù kódà kí Éfà tó dé. Lọ́nà wo? Bíbélì sọ pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù Jèhófà Ọlọ́run sì gbé àṣẹ yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin náà pé: ‘Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.’”—Jẹ́n. 2:16, 17.
4 “Igi ìmọ̀ rere àti búburú” dúró fún ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti pinnu ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Èyí ò ṣàjèjì sí Ádámù torí pé ó mọ ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́; Ọlọ́run dá a ní àwòrán ara rẹ̀, ó sì ní ẹ̀rí ọkàn. Igi náà máa jẹ́ kí Ádámù àti Éfà mọ̀ pé wọ́n nílò ìtọ́sọ́nà Jèhófà nígbà gbogbo. Tí wọ́n bá jẹ èso yẹn, ohun tí wọ́n ń fi ìyẹn sọ ni pé, bó ṣe wu àwọn làwọn fẹ́ máa ṣe, èyí sì máa fa ìṣòro ńlá bá àwọn àti àwọn ọmọ tí wọ́n máa bí. Òfin tí Ọlọ́run fún wọn àti ìyà tó sọ pé wọ́n máa jẹ tí wọ́n bá rú òfin náà jẹ́ ká mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe tóbi tó.
-
-
Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun AsánIlé Ìṣọ́—2014 | September 15
-
-
7 Ọlọ́run ti sọ fún Ádámù tẹ́lẹ̀ pé: “Ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” Ó ṣeé ṣe kí Ádámù rò pé “ọjọ́” oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ni Ọlọ́run ní lọ́kàn. Lẹ́yìn tí wọ́n rú òfin Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe kó máa rò pé Jèhófà máa pa àwọn kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó ṣú. Àmọ́ ó bá tọkọtaya náà sọ̀rọ̀ ní “ìgbà tí atẹ́gùn máa ń fẹ́ yẹ́ẹ́ ní ọjọ́.” (Jẹ́n. 3:8) Ó pè wọ́n wá jẹ́jọ́, ó sì gbọ́ tẹnu Ádámù àti Éfà kó lè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. (Jẹ́n. 3:9-13) Lẹ́yìn ìyẹn ló wá dájọ́ fáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yẹn. (Jẹ́n. 3:14-19) Tó bá pa wọ́n lójú ẹsẹ̀ níbẹ̀, a jẹ́ pé ohun tó ní lọ́kàn fún Ádámù àti Éfà àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn já sásán nìyẹn. (Aísá. 55:11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dájọ́ ikú fún wọn, tí wọ́n sì di ẹlẹ́ṣẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ọlọ́run ṣì gba Ádámù àti Éfà láyè láti bí àwọn ọmọ tí wọ́n lè jàǹfààní nínú àwọn ohun míì tí Ọlọ́run máa ṣe. Nítorí náà, lójú Ọlọ́run, Ádámù àti Éfà kú lọ́jọ́ tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀. Bó sì ṣe rí nìyẹn lóòótọ́, torí wọ́n kú láàárín ẹgbẹ̀rún ọdún kan tó ṣàpẹẹrẹ “ọjọ́” kan lójú Ọlọ́run.—2 Pét. 3:8.
-