ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀?
    Jí!—2006 | July
    • Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, ó fi wọ́n sínú ọgbà ẹlẹ́wà kan tó kún fún oríṣiríṣi ohun ọ̀gbìn tẹ́nu ń jẹ àtàwọn igi eléso. Ọ̀kan ṣoṣo lára àwọn igi náà ni Ọlọ́run pàṣẹ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn, ìyẹn ni “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀dá tó lómìnira láti dá ṣèpinnu ni Ádámù àti Éfà, wọ́n lè yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run tàbí kí wọ́n ṣàìgbọràn sí i. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run kìlọ̀ fún Ádámù pé “ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú [igi ìmọ̀ rere àti búburú], dájúdájú, ìwọ yóò kú.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:29; 2:17.

      Kò Burú bí Òmìnira Wọn Ṣe Ní Ààlà

      Ohun kan ṣoṣo tí Ọlọ́run ní kí Ádámù àti Éfà má ṣe yìí ò fa ìnira kankan nítorí pé wọ́n lè jẹ lára èso gbogbo igi yòókù tó wà nínú ọgbà. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16) Àti pé ìkàléèwọ̀ ọ̀hún ò fi tọkọtaya náà hàn bí elérò búburú, bẹ́ẹ̀ ni ò sì fàbùkù kàn wọ́n. Bó bá jẹ́ pé ṣe ni Ọlọ́run sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá ẹranko lò pọ̀ tàbí tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ pààyàn ni, àwọn kan ì bá sọ pé àwọn èèyàn pípé náà lérò ibi kan lọ́kàn tí Ọlọ́run ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n hù níwà. Àmọ́ kò sí ohun tó burú nínú pé kí wọ́n jẹun.

      Ṣé ìbálòpọ̀ takọtabo tiẹ̀ ni èso ọ̀hún, báwọn kan ṣe máa ń sọ ọ́? Irú èrò bẹ́ẹ̀ ò bá ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ mu. Ohun tá ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ni pé nígbà tí Ọlọ́run ń sọ fún Ádámù pé kò gbọ́dọ̀ jẹ èso yẹn, òun nìkan ló wà, ó sì ṣe díẹ̀ tó fi wà bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:23) Èkejì ni pé, Ọlọ́run sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n “di púpọ̀, kí [wọ́n] sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ré òfin òun kọjá tán, kó tún wá sọ pé ikú ló tọ́ sí wọn nítorí pé wọ́n pa àṣẹ òun mọ́! (1 Jòhánù 4:8) Ẹ̀kẹta wá ni pé, Éfà ló kọ́kọ́ jẹ èso náà, lẹ́yìn náà ló fún ọkọ ẹ̀ ní díẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Látàrí èyí, ó ṣe kedere pé èso náà kì í ṣe ìbálòpọ̀.

      Wọ́n Fẹ́ Máa Ṣe Ìfẹ́ Inú Ara Wọn

      Igi ìmọ̀ náà ò yàtọ̀ sáwọn igi yòókù. Àmọ́, ó dúró fún ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní gẹ́gẹ́ bí Alákòóso láti pinnu fáwọn ẹ̀dá tó dá, pé ohun kan dára tàbí pé ó burú. Nítorí náà, béèyàn bá jẹ nínú èso igi náà, kì í ṣe pé ó jalè nìkan, ní ti pé ó mú ohun tó jẹ́ ti Ọlọ́run. Ó tún túmọ̀ sí pé onítọ̀hún fẹ́ máa ṣe ìfẹ́ inú ara ẹ̀, ó fẹ́ máa dá pinnu ohun tó wù ú. Ẹ kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Sátánì ti purọ́ fún Éfà pé bí òun àti ọkọ rẹ̀ bá jẹ nínú èso náà, wọn ò ní kú, ó sọ pé: “Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5.

  • Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀?
    Jí!—2006 | July
    • Ńṣe ni gbígbà tí Ádámù àti Éfà gbà láti máa ṣèfẹ́ inú ara wọn yìí ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ kọjá àlà, tí ẹ̀ṣẹ̀ sì jọba nínú ayé wọn, débi tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í ba àgọ́ ara wọn jẹ́ tó fi mọ́ àbùdá wọn tí Ọlọ́run dá ní pípé. Lóòótọ́ ni wọ́n gbé láyé fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, àmọ́ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kú ‘ní ọjọ́’ náà gan-an tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, bí ẹ̀ka tá a gé kúrò lára igi ṣe máa ń kú díẹ̀díẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 5:5) Síwájú sí i, ìgbà àkọ́kọ́ tí ọkàn wọn dà rú nìyẹn. Wọ́n rí i pé ìhòòhò làwọn wà, wọ́n sì gbìyànjú láti fara pa mọ́ fún Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:7, 8) Ọkàn wọn tún bẹ̀rẹ̀ sí í dá wọn lẹ́bi, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n, ojú sì ń tì wọ́n. Ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá kó ṣìbáṣìbo bá wọn, ẹ̀rí ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí dá wọn lẹ́bi pé wọ́n ti hùwà àìtọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́