ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?
    Ilé Ìṣọ́—2014 | January 1
    • Ṣadé: Ó kà pé: “Wàyí o, ejò jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra jù lọ nínú gbogbo ẹranko inú pápá tí Jèhófà Ọlọ́run dá. Nítorí náà, ó sọ fún obìnrin náà pé: ‘Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?’ Látàrí èyí, obìnrin náà sọ fún ejò pé: ‘Àwa lè jẹ nínú àwọn èso igi ọgbà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti sọ nípa èso igi tí ó wà ní àárín ọgbà pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, rárá, ẹ kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án, kí ẹ má bàa kú.” Látàrí èyí, ejò náà sọ fún obìnrin náà pé: ‘Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ bá jẹ nínú rẹ̀ ni ojú yín máa là, ó sì dájú pé ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.’”

  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?
    Ilé Ìṣọ́—2014 | January 1
    • Bọ́lá: Lọ́nà kan, a lè sọ pé bó ṣe jẹ́ nìyẹn. Ṣùgbọ́n, ohun tí Sátánì sọ ju ìyẹn lọ. Ẹ tún wo ẹsẹ 5 yẹn lẹ́ẹ̀kan sí i. Ǹjẹ́ ẹ kíyèsí nǹkan míì tí Sátánì tún sọ fún Éfà?

      Ṣadé: Ó sọ fún un pé ojú rẹ̀ máa là tó bá jẹ èso yẹn.

      Bọ́lá: Ẹ ṣeun, ó tún sọ fún un pé ó máa dà “bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Torí náà, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé Ọlọ́run ń fawọ́ ohun rere sẹ́yìn fáwọn èèyàn.

      Ṣadé: Ẹ̀n ẹ́n.

      Bọ́lá: Ọ̀ràn ńlá sì nìyẹn jẹ́.

      Ṣadé: Kí lẹ ní lọ́kàn?

      Bọ́lá: Ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ wẹ́rẹ́ yẹn kan gbogbo èèyàn, Éfà nìkan kọ́ ló ń bá wí, gbogbo wa pátá lọ̀ràn náà kàn. Torí ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé nǹkan máa sàn fún àwa èèyàn láìsí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Bíi ti ẹ̀sùn àkọ́kọ́, Jèhófà mọ̀ pé ọ̀nà tó dáa jù láti yanjú ọ̀ràn yìí ni pé kí òun fún Sátánì láyè láti fi hàn bóyá òótọ́ lọ̀rọ̀ tó sọ yìí. Torí náà, Ọlọ́run fàyè gba Sátánì láti ṣàkóso ayé fún ìgbà díẹ̀. Ọlọ́run kọ́ ló ń ṣàkóso ayé, Sátánì ni, ìdí nìyẹn tí ìyà fi pọ̀ gan an láyé.d Àmọ́ o, ìròyìn ayọ̀ wà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́