ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bí Ayé Yìí Ṣe Máa Dópin
    Ilé Ìṣọ́—2012 | September 15
    • 15. Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀?

      15 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Sátánì máa fojú ara rẹ̀ rí bí gbogbo ètò rẹ̀ tó wà láyé ṣe máa pa run. Lẹ́yìn náà, Sátánì á wá gba ìdájọ́ tirẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù ṣàlàyé èyí nínú Ìṣípayá 20:1-3. (Kà á.) Jésù Kristi, ‘áńgẹ́lì tó mú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ dání,’ máa de Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, ó máa jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, wọ́n á sì wà níbẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún. (Lúùkù 8:30, 31; 1 Jòh. 3:8) Èyí ló máa jẹ́ apá àkọ́kọ́ nínú bí Jésù ṣe máa fọ́ ejò náà lórí.d—Jẹ́n. 3:15.

  • Bí Ayé Yìí Ṣe Máa Dópin
    Ilé Ìṣọ́—2012 | September 15
    • d Jésù Kristi máa fọ́ orí ejò yẹn pátápátá lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún náà nígbà tó bá fi Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò sínú “adágún iná àti imí ọjọ́.”​—Ìṣí. 20:7-10; Mát. 25:41.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́