ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mímọyì Ipa Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Tí Jésù Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́—2008 | December 15
    • “Irú Ọmọ” Náà

      18. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Ọlọ́run sọ lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, kí la sì wá mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí nígbà tó yá?

      18 Jèhófà Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ nípa Olùgbàlà kan nígbà tó dà bíi pé ìran èèyàn ti pàdánù gbogbo nǹkan nínú ọgbà Édẹ́nì, lára àwọn nǹkan tí wọ́n sì pàdánù ni àjọṣe tó dán mọ́nrán tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run, ìyè àìnípẹ̀kun, ayọ̀ àti Párádísè. Bíbélì pe Olùgbàlà yẹn ní “irú ọmọ.” (Jẹ́n. 3:15) Irú Ọmọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò tètè mọ̀ yìí ni ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ látìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Ó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Ó sì máa wá láti ìlà ìdílé Dáfídì Ọba.— Jẹ́n. 21:12; 22:16-18; 28:14; 2 Sám. 7:12-16.

      19, 20. (a) Ta ni Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù nìkan kọ́ ni irú ọmọ tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀?

      19 Ta ni Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí yìí? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú ìwé Gálátíà 3:16. (Kà á.) Àmọ́, nínú orí kan náà yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró pé: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, ẹ̀yin jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù ní ti tòótọ́, ajogún ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìlérí.” (Gál. 3:29) Báwo ni Kristi ṣe jẹ́ Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí, táwọn ẹlòmíì náà sì tún jẹ́ bẹ́ẹ̀?

      20 Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń sọ pé àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù làwọn, àwọn kan lára wọn sì máa ń ṣe bíi wòlíì. Àwọn ẹ̀sìn kan tiẹ̀ kà á sí pàtàkì gan-an pé káwọn wòlíì wọn jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. Àmọ́ ṣé Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí náà ni gbogbo wọn? Rárá o. Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fi hàn pé, kì í ṣe gbogbo àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ló lè pera wọn ní Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí. Ọlọ́run ò bù kún aráyé nípasẹ̀ àwọn ọmọ táwọn ọmọ Ábúráhámù yòókù bí, àmọ́ nípasẹ̀ Ísákì nìkan ni Ọlọ́run gbà bu kún aráyé. (Héb. 11:18) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ọkùnrin kan ṣoṣo, ìyẹn Jésù Kristi, tí Bíbélì fi hàn pé ó wá láti ìlà ìdílé Ábúráhámù, ni apá àkọ́kọ́ lára irú ọmọ tí Ọlọrun ṣèlérí yẹn.c Gbogbo àwọn tí wọ́n wá di apá kejì lára irú ọmọ Ábúráhámù láǹfààní yẹn torí pé wọ́n “jẹ́ ti Kristi.” Kò sí àníàní pé ipa tí Jésù kó nínú mímú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ ṣàrà ọ̀tọ̀ lóòótọ́.

  • Mímọyì Ipa Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Tí Jésù Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́—2008 | December 15
    • c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni ń rò pé Ọlọ́run máa ṣojúure sáwọn, nítorí pé àwọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, wọ́n ń retí ẹnì kan tó máa wá gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tàbí Kristi.—Jòh. 1:25; 7:41, 42; 8:39-41.

  • Mímọyì Ipa Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Tí Jésù Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́—2008 | December 15
    • ◼ Irú Ọmọ Náà. (Jẹ́n. 3:15) Jésù Kristi ni ọkùnrin kan ṣoṣo tó jẹ́ apá àkọ́kọ́ lára irú ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí yẹn. Gbogbo àwọn ẹlòmíì tó wá jẹ́ apá kejì lára irú ọmọ Ábúráhámù nígbà tó yá “jẹ́ ti Kristi.”—Gál. 3:29.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́