ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 8 Tó bá rò bẹ́ẹ̀, àṣìṣe ńlá ló ṣe o. Tí òun àti Ádámù bá sì lọ gbìn èrò yìí sí Kéènì lọ́kàn bó ṣe ń dàgbà, kò sí bí ìyẹn ò ṣe ní sọ ọ́ dẹni tó jọra rẹ̀ lójú. Nígbà tí Éfà wá bí ọmọkùnrin kejì, wọn kò sọ irú ọ̀rọ̀ ìwúrí bẹ́ẹ̀ nípa rẹ̀. Orúkọ tí wọ́n sọ ọ́ ni Ébẹ́lì, tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Èémí Àmíjáde,” tàbí “Asán.” (Jẹ́n. 4:2) Àbí wọ́n ti rò pé Ébẹ́lì kò ní fi bẹ́ẹ̀ rọ́wọ́ mú ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní orúkọ yẹn, bíi pé wọn kò gbójú lé e tó Kéènì? A ò lè sọ.

  • “Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 10, 11. Irú iṣẹ́ wo ni Kéènì àti Ébẹ́lì ń ṣe? Ànímọ́ wo ni Ébẹ́lì wá ní?

      10 Ó jọ pé bí àwọn ọmọkùnrin méjèèjì ṣe ń dàgbà, Ádámù kọ́ wọn ní iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n á fi máa ṣètìlẹyìn fún ìdílé náà. Kéènì di àgbẹ̀, Ébẹ́lì sì ń da àgùntàn.

  • “Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 13 Ó dájú pé Ébẹ́lì máa ń fara balẹ̀ ronú nípa àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Fojú inú wò ó bó ṣe ń tọ́jú agbo ẹran rẹ̀. Àwọn darandaran sábà máa ń rìn káàkiri gan-an. Torí náà, yóò máa da àwọn ẹran ọ̀sìn náà lọ sí orí àwọn òkè àti àfonífojì, yóò kó wọn sọdá odò, yóò dà wọ́n lọ sí ibikíbi tí wọ́n bá ti lè rí koríko tútù yọ̀yọ̀ jẹ, ibi tí wọ́n ti máa rí omi mu gan-an àti ibi ààbò tí wọ́n ti lè sinmi. Ó jọ pé nínú àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run tí kò mọ bí wọ́n ṣe ń dáàbò bo ara wọn rárá, tàwọn àgùntàn yọyẹ́. Àfi bíi pé ṣe ni Ọlọ́run dìídì dá wọn lọ́nà tó fi jẹ́ pé èèyàn ní láti máa tọ́ wọn sọ́nà, kó sì máa dáàbò bò wọ́n. Ó ṣeé ṣe kí Ébẹ́lì wá rí i pé òun náà nílò ìtọ́sọ́nà àti ààbò àti ìtọ́jú Ọlọ́run tó ní ọgbọ́n àti agbára ju ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ irú èrò bẹ́ẹ̀ ni yóò máa bá Ọlọ́run sọ nígbà tó bá ń gbàdúrà, ìyẹn á sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ máa pọ̀ sí i.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́