ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Rírú Ẹbọ Tí Jèhófà Yóò Tẹ́wọ́ Gbà
    Ilé Ìṣọ́—1999 | February 1
    • Nígbà tó yá, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nígbà tí wọ́n ti di géńdé, Kéènì àti Ébẹ́lì rúbọ sí Jèhófà. Nígbà tó jẹ́ pé olùṣọ́ àgùntàn ni Ébẹ́lì, kò yani lẹ́nu pé “àwọn àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ̀ . . . , àní àwọn apá tí ó lọ́ràá nínú wọn” ló mú wá. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, “àwọn èso kan tí ilẹ̀ mú jáde” ni Kéènì fi rúbọ. Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì, ṣùgbọ́n “òun kò fi ojú rere kankan wo Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-5) Èé ṣe?

      Àwọn kan sọ pé ohun tó fà á ni pé ẹbọ Ébẹ́lì wá láti inú “àwọn àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ̀,” àmọ́ ti Kéènì jẹ́ “àwọn èso kan tí ilẹ̀ mú jáde.” Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn náà kì í ṣe bóyá ohun tí Kéènì fi rúbọ dára tàbí kò dára, nítorí àkọsílẹ̀ náà sọ pé Jèhófà fi ojú rere “wo Ébẹ́lì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀,” kò sì fi ojú rere kankan “wo Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” Nítorí náà, bí ọkàn-àyà olùjọsìn náà ti rí ni Jèhófà wò. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kí ló rí? Hébérù 11:4 sọ pé “nípa ìgbàgbọ́” ni Ébẹ́lì rú ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà, ó hàn gbangba pé, Kéènì kò ní ìgbàgbọ́ tó mú kí a tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì.

  • Rírú Ẹbọ Tí Jèhófà Yóò Tẹ́wọ́ Gbà
    Ilé Ìṣọ́—1999 | February 1
    • Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Kéènì má ronú jinlẹ̀ rárá nípa ẹbọ tó rú. Alálàyé Bíbélì kan ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún sọ pé: “Ẹbọ rẹ̀ jẹ́ wíwulẹ̀ gbà pé Ọlọ́run jẹ́ oníbú ọrẹ. Ó hàn kedere pé kò gbà pé ìṣòro kankan wà láàárín òun àti Ẹlẹ́dàá òun, tàbí pé ó yẹ kí òun jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí kí òun gbára lé ètùtù kan.”

      Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí, ìwà ọ̀yájú ti lè mú Kéènì ronú pé òun ni irú-ọmọ náà tí a ṣèlérí, ẹni tí yóò pa Ejò náà, Sátánì, run. Ó ṣeé ṣe kí Éfà pàápàá ti ní irú ipò ọlá bẹ́ẹ̀ lọ́kàn fún àkọ́bí rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 4:1) Àmọ́ ṣá o, bó bá jẹ́ ohun tí Kéènì àti Éfà ń rò nìyí, wọ́n mà kúkú ṣàṣìṣe o.

      Bíbélì kò sọ bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì. Àwọn kan sọ pé iná bọ́ sí i láti ọ̀run, ó sì jó o. Ọ̀nà yòówù kó jẹ́, gbàrà tí Kéènì ti mọ̀ pé a kò tẹ́wọ́ gba ẹbọ òun, “ìbínú Kéènì . . . gbóná gidigidi, ojú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀wẹ̀sì.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:5) Ìjàngbọ̀n mà ni Kéènì ń fà lẹ́sẹ̀ yìí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́