-
Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn Lákòókò Hílàhílo YìíIlé Ìṣọ́—2005 | September 1
-
-
10, 11. (a) Báwo ni ìwà ìbàjẹ́ ṣe tàn kálẹ̀ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Énọ́kù wàásù rẹ̀, kí sì ni ìṣesí àwọn tó gbọ́ ọ?
10 Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀nà tí ìwà ìbàjẹ́ fi tàn kálẹ̀ kíákíá láàárín ìràn ènìyàn lẹ́yìn tí Ádámù ṣẹ̀ yẹ̀ wò. Bíbélì sọ fún wa pé Kéènì, àkọ́bí Ádámù lẹni tó kọ́kọ́ pànìyàn láyé, nígbà tó pa Ébẹ́lì, àbúrò rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 4:8-10) Lẹ́yìn tí Ébẹ́lì kú ikú oró yìí, Ádámù àti Éfà tún bí ọmọkùnrin mìíràn, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́ẹ̀tì. Òun la kà nípa rẹ̀ pé: “A sì bí ọmọkùnrin kan fún Sẹ́ẹ̀tì pẹ̀lú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ rẹ̀ ní Énọ́ṣì. Àkókò yẹn ni a bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:25, 26) Ó ṣeni láàánú pé bí wọ́n tilẹ̀ ń “pe orúkọ Jèhófà” wọ́n ti yapa kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.b Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Énọ́ṣì, àtọmọdọ́mọ Kéènì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lámékì kọ orin kan fún àwọn ìyàwó rẹ̀ méjèèjì tó sọ pé òun ti pa ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó dọ́gbẹ́ sí òun lára. Ó tún là á mọ́lẹ̀ pé: “Bí a óò bá gbẹ̀san Kéènì ní ìgbà méje. Nígbà náà, ti Lámékì yóò jẹ́ ní ìgbà àádọ́rin àti méje.”—Jẹ́nẹ́sísì 4:10, 19, 23, 24.
-
-
Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn Lákòókò Hílàhílo YìíIlé Ìṣọ́—2005 | September 1
-
-
b Jèhófà ti bá Ádámù sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó bí Énọ́ṣì. Ébẹ́lì rú ẹbọ kan tó ṣètẹ́wọ́gbà sí Jèhófà. Kódà, Ọlọ́run bá Kéènì sọ̀rọ̀ kó tó di pé owú jíjẹ àti ìbínú mú kí Kéènì dẹ́ṣẹ̀ ìpànìyàn. Nítorí náà, bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí i “pe orúkọ Jèhófà” yìí ní láti jẹ́ lọ́nà kan tó yàtọ̀, kì í ṣe lọ́nà ti ìjọsìn mímọ́.
-