ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Máa Wo Ọ̀dọ̀ Jèhófà Fún Ìtùnú
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | November 1
    • 6. (a) Ìlérí tí ń tuni nínú wo ni Ọlọ́run ṣe lẹ́yìn tí aráyé ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ wo nípa ìtùnú ni Lámékì sọ?

      6 Nígbà tí ó ń dájọ́ fún ẹni tí ó súnná sí ìṣọ̀tẹ̀ ènìyàn, Jèhófà fẹ̀rí jíjẹ́ ‘Ọlọ́run tí ń pèsè ìtùnú’ hàn. (Róòmù 15:5) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣèlérí láti rán “irú-ọmọ” kan tí yóò dá àwọn ọmọ Ádámù nídè lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn kúrò lọ́wọ́ agbára ìdarí oníjàm̀bá tí ìṣọ̀tẹ̀ Ádámù ní. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Láìpẹ́, Ọlọ́run tún pèsè àrítẹ́lẹ̀ nípa ìdáǹdè yìí. Fún àpẹẹrẹ, ó mí sí Lámékì, àtọmọdọ́mọ Ádámù kan tí ó jìnnà sí i, tí Sẹ́ẹ̀tì ọmọkùnrin rẹ̀ bí, láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tí ọmọkùnrin Lámékì yóò ṣe pé: “Eléyìí ni yóò tù wá ní inú ní iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí OLÚWA ti fi bú.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:29) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí yìí, a sọ ọmọdékùnrin náà ní Nóà, èyí tí a lóye sí “Ìsinmi” tàbí “Ìtùnú.”

  • Ẹ Máa Wo Ọ̀dọ̀ Jèhófà Fún Ìtùnú
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | November 1
    • 8 Jèhófà pète láti fi ìkún omi kárí ayé pa ayé búburú yẹn run, ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́, ó mú kí Nóà kan ọkọ̀ láti gba ẹ̀mí là. Nípa báyìí, a gba ìran ènìyàn àti ọ̀wọ́ àwọn ẹranko là. Ẹ wo bí ara yóò ti tu Nóà àti ìdílé rẹ̀ tó lẹ́yìn Ìkún Omi náà bí wọ́n ti ń jáde kúrò nínú ọkọ̀ sínú ilẹ̀ ayé tí a fọ̀ mọ́ tónítóní! Ẹ wo bí yóò ti tù wọ́n nínú tó pé a ti mú ègún tí ń bẹ lórí ilẹ̀ kúrò, ní mímú kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ àgbẹ̀ rọrùn gidigidi! Ní tòótọ́, àsọtẹ́lẹ̀ Lámékì já sóòótọ́, Nóà sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, Nóà jẹ́ irinṣẹ́ ní mímú “ìtùnú” wá fún aráyé títí dé ìwọ̀n àyè kan. Bí ó ti wù kí ó rí, agbára ìdarí búburú ti Sátánì àti àwọn áńgẹ́lì ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò dópin pẹ̀lú Ìkún Omi náà, aráyé sì ń bá a nìṣó láti máa kérora lábẹ́ ẹrù ìnira ti ẹ̀ṣẹ̀, àìsàn, àti ikú.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́