ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọlọ́run Pa Nóà “Mọ́ Láìséwu Pẹ̀lú Àwọn Méje Mìíràn”
    Ilé Ìṣọ́—2013 | August 1
    • Báwo ni nǹkan ṣe máa rí ná fún Nóà àti ìdílé rẹ̀ fún ogójì ọjọ́ àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí Jèhófà ti ilẹ̀kùn áàkì náà? Bí òjò tó ń dà yàà sórí áàkì náà lákọlákọ, ó ṣeé ṣe kí àwọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ti ní iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa tọ́jú ara wọn, kí wọ́n máa bójú tó ibi tí wọ́n ń gbé, kí wọ́n sì máa ṣètọ́jú àwọn ẹranko tó wà nínú áàkì náà. Àmọ́ nígbà tó yá, ọkọ̀ tó tóbi fàkìàfakia yìí mì jìgìjìgì, ó fì sọ́tùn-ún fì sósì. Bí áàkì náà ṣe gbéra nílẹ̀ nìyẹn! Torí pé omi ti bo ibi gbogbo, áàkì náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sókè díẹ̀díẹ̀ títí tó fi “léfòó lókè ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 7:17) Ẹ ò rí i pé agbára Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè pọ̀ gan-an!

  • Ọlọ́run Pa Nóà “Mọ́ Láìséwu Pẹ̀lú Àwọn Méje Mìíràn”
    Ilé Ìṣọ́—2013 | August 1
    • NÓÀ ÀTI ÌDÍLÉ RẸ̀ “LA OMI JÁ LÁÌSÉWU”

      Bí alagbalúgbú omi yẹn ṣe ń gbé áàkì náà lọ, àwọn tó wà nínú rẹ̀ kò ní ṣàì máa gbọ́ bí àwọn igi tí wọ́n fi kàn án ṣe ń dún, tí ó sì ń rọ́ kẹ̀kẹ̀. Ǹjẹ́ àyà Nóà bẹ̀rẹ̀ sí í já bí omi náà ti ń pọ̀ sí i tí ọwọ́ ìgbì náà sì ń le, àbí ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà á pé áàkì náà lè dà wó? Rárá o. Èrò yẹn lè wá sọ́kàn àwọn tó ń ṣiyè méjì nípa ìtàn yẹn lóde òní, àmọ́ Nóà kò ṣe iyè méjì rárá. Bíbélì sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà . . . kan ọkọ̀ áàkì.” (Hébérù 11:7) Ìgbàgbọ́ nínú kí ni? Jèhófà ti dá májẹ̀mú, ó ti ṣe àdéhùn tí kò lè yẹ̀ pé òun máa mú kí Nóà àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ la Ìkún-omi náà já. (Jẹ́nẹ́sísì 6:18, 19) Ṣé Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun alààyè tó wà nínú rẹ̀ ò wá lè ṣe é kí ọkọ̀ náà dúró digbí, kó má sì bà jẹ́? Ó dájú pé ó lè ṣe bẹ́ẹ̀! Nóà fọkàn tán Jèhófà pátápátá pé ó máa mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ. Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́, Nóà àti ìdílé rẹ̀ “la omi já láìséwu.”—1 Pétérù 3:20.

      Lẹ́yìn ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, òjò náà dá. Tí a bá fi kàlẹ́ńdà òde òní ṣírò rẹ̀, nǹkan bí oṣù December ọdún 2370 kí wọ́n tó bí Jésù ló bọ́ sí. Àmọ́ ìdílé yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn nínú áàkì ni. Áàkì tí àwọn ohun alààyè kún inú rẹ̀ fọ́fọ́ yìí nìkan ló léfòó téńté sórí omi tó kún bo gbogbo ayé, kódà ó yọ sókè ju àwọn òkè ńlá tí omi ti bò mọ́lẹ̀ lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 7:19, 20) Ẹ wo iṣẹ́ ńlá tí Nóà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ìyẹn Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì á máa ṣe bí wọ́n ṣe ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ, tí wọ́n ń tọ́jú ibi tí wọ́n kó wọn sí, tí wọn sì ń bójú tó wọn kí wọ́n má bàa ṣàìsàn. Kò yà wá lẹ́nu pé Ọlọ́run tó rọ gbogbo àwọn ẹranko rírorò lójú tó sì mú kí wọ́n rọrùn láti darí lè mú kí wọ́n wà bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àkókò tí wọ́n fi wà nínú áàkì náà.a

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́