-
Ní Irú Ìgbàgbọ́ Tí Ábúráhámù Ní!Ilé Ìṣọ́—2001 | August 15
-
-
6, 7. Inú wàhálà wo ni Ábúrámù àti Sáráì kó sí, báwo sì ni Jèhófà ṣe kó Sáráì yọ?
6 Áà, èyí á mà fa ìbànújẹ́ púpọ̀ fún Ábúrámù àti Sáráì o! Sáráì ni wọ́n fẹ́ bá ṣèṣekúṣe yìí. Fáráò, tí kò kúkú mọ̀ pé aya aláya ni Sáráì, tún wá lọ ń kó ẹ̀bùn rẹpẹtẹ fún Ábúrámù, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó “wá ní àwọn àgùntàn àti àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àwọn ràkúnmí.”b (Jẹ́nẹ́sísì 12:16) Ẹ̀bùn wọ̀nyẹn ò tiẹ̀ ní jọ Ábúrámù lójú rárá! Nínú gbogbo pákáǹleke yìí, Jèhófà kò gbàgbé Ábúrámù.
-
-
Ní Irú Ìgbàgbọ́ Tí Ábúráhámù Ní!Ilé Ìṣọ́—2001 | August 15
-
-
b Ó ṣeé ṣe kí Hágárì, tó di wáhàrì Ábúrámù lẹ́yìn náà, wà lára àwọn ìránṣẹ́ táa fún Ábúrámù lákòókò yìí.—Jẹ́nẹ́sísì 16:1.
-