ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Mo Múra Tán Láti Lọ”
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 3
    • Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lẹ́yìn tó ti pọn omi kún korobá rẹ̀ tán, bàbá àgbàlagbà kan wá bá a. Bàbá náà sọ pé: “Jọ̀wọ́ fún mi ní òfèrè omi díẹ̀ láti inú ìṣà omi rẹ.” Ohun tí bàbá náà béèrè kò pọ̀ jù, ó sì béèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Rèbékà rí i pé bàbá náà ti rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn. Kíá ló gbé korobá omi náà sọ̀ kalẹ̀ léjìká, ó sì fún bàbá náà ní omi tútù débi tí bàbá náà fi mu ún tẹ́rùn. Rèbékà kíyè sí i pé, kò sí omi nínú ọpọ́n ìmumi tí àwọn ràkúnmí mẹ́wàá tí bàbá náà kó wá lè mu. Àánú ṣe é bó ṣe rí i tí bàbá náà ń wo òun, ó sì wù ú láti ṣoore fún bàbá náà. Torí náà, ó sọ pé: “Àwọn ràkúnmí rẹ ni èmi yóò tún fa omi fún títí tí wọn yóò fi mu tẹ́rùn.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:17-19.

      Wàá rí i pé kì í ṣe pé Rèbékà kàn fẹ́ fún àwọn ràkúnmí náà lómi mu nìkan, àmọ́ ó máa fún wọn títí wọn yóò fi mu ún tẹ́rùn. Tí òùngbẹ bá gbẹ ràkúnmí dáadáa, ẹyọ kan lè mú tó gálọ̀nù omi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ ṣe gbẹ àwọn ràkúnmí mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà, á jẹ́ pé iṣẹ́ ńlá ni Rèbékà fẹ́ ṣe. Àmọ́, ó jọ pé òùngbẹ kò fi bẹ́ẹ̀ gbẹ àwọn ràkúnmí náà lọ́jọ́ yẹn.a Àmọ́ ṣé Rèbékà mọ̀ bẹ́ẹ̀ kó tó sọ pé òun máa fún wọn lómi? Rárá o. Ńṣe ló wù ú látọkànwá pé kó ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti ṣaájò bàbá àgbàlagbà náà. Bàbá náà gbà pé kó fún wọn lómi. Ó sì ń wo Rèbékà bó ṣe ń lọ tó ń bọ̀, tó ń pọn omi, tó sì ń dà á sínú ọpọ́n ìmumi náà.—Jẹ́nẹ́sísì 24:20, 21.

      Rèbékà ń fún àwọn ràkúnmí tí ìránṣẹ́ Ábúráhámù kó wá lómi

      Òṣìṣẹ́ kára ni Rèbékà, ó sì lẹ́mìí àlejò ṣíṣe

  • “Mo Múra Tán Láti Lọ”
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 3
    • a Ó ti di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Ìtàn náà kò sì sọ pé Rèbékà wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Kò sì jọ pé àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti sùn kó tó délé tàbí pé ẹnì kan wá wò ó kó lè mọ ohun tó fà á tó fi pẹ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́