-
“Mo Múra Tán Láti Lọ”Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 3
-
-
Wàá rí i pé kì í ṣe pé Rèbékà kàn fẹ́ fún àwọn ràkúnmí náà lómi mu nìkan, àmọ́ ó máa fún wọn títí wọn yóò fi mu ún tẹ́rùn. Tí òùngbẹ bá gbẹ ràkúnmí dáadáa, ẹyọ kan lè mú tó gálọ̀nù omi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ ṣe gbẹ àwọn ràkúnmí mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà, á jẹ́ pé iṣẹ́ ńlá ni Rèbékà fẹ́ ṣe. Àmọ́, ó jọ pé òùngbẹ kò fi bẹ́ẹ̀ gbẹ àwọn ràkúnmí náà lọ́jọ́ yẹn.a Àmọ́ ṣé Rèbékà mọ̀ bẹ́ẹ̀ kó tó sọ pé òun máa fún wọn lómi? Rárá o. Ńṣe ló wù ú látọkànwá pé kó ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti ṣaájò bàbá àgbàlagbà náà. Bàbá náà gbà pé kó fún wọn lómi. Ó sì ń wo Rèbékà bó ṣe ń lọ tó ń bọ̀, tó ń pọn omi, tó sì ń dà á sínú ọpọ́n ìmumi náà.—Jẹ́nẹ́sísì 24:20, 21.
Òṣìṣẹ́ kára ni Rèbékà, ó sì lẹ́mìí àlejò ṣíṣe
-
-
“Mo Múra Tán Láti Lọ”Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 3
-
-
Ó dájú pé Rèbékà máa kíyè sí i pé bàbá àgbàlagbà yẹn ń wo òun. Kì í ṣe pé bàbá náà ní èròkérò lọ́kàn ló ṣe ń wò ó, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń wò ó tìyanu-tìyanu, inú rẹ̀ sì ń dùn. Nígbà tí Rèbékà ṣe tán, bàbá náà fún un lẹ́bùn ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye. Lẹ́yìn náà, ó wá béèrè pé: “Ọmọbìnrin ta ni ìwọ? Jọ̀wọ́, sọ fún mi. Yàrá ha wà ní ilé baba rẹ fún wa láti sùn mọ́jú bí?” Nígbà tí Rèbékà sọ ọmọ ẹni tó jẹ́ fún un, ayọ̀ bàbá náà túbọ̀ kún. Pẹ̀lú ara yíyá gágá ni ọmọbìnrin náà tún fi sọ pé: “Èérún pòròpórò àti oúnjẹ ẹran púpọ̀ wà lọ́dọ̀ wa, àyè tún wà láti sùn mọ́jú.” Oore ńlá lèyí jẹ́, torí pé àwọn míì wà pẹ̀lú bàbá àgbàlagbà náà. Rèbékà sí ṣíwájú wọn lọ sílé kó lè lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ìyá rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 24:22-28, 32.
-