ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò Tí wọn Ò Láyọ̀ Ló “Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì”
    Ilé Ìṣọ́—2007 | October 1
    • Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ tó túbọ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé àárín Rákélì àti Léà ò gún ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn máńdírékì kan tí Rúbẹ́nì, ọmọ Léà rí he. Àwọn èèyàn rò pé èso yìí máa ń jẹ́ kéèyàn lóyún. Nígbà tí Rákélì ní kó fóun ní díẹ̀ níbẹ̀, tìbínú-tìbínú ni Léà fi dáhùn pé: “Ohun kékeré ha nìyí, lẹ́yìn tí ìwọ ti gba ọkọ mi, o tún fẹ́ gba àwọn máńdírékì ọmọkùnrin mi pẹ̀lú?” Ohun táwọn kan gbà pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí túmọ̀ sí ni pé Jékọ́bù máa ń wà lọ́dọ̀ Rákélì lọ́pọ̀ ìgbà ju ọ̀dọ̀ Léà lọ. Ó ṣeé ṣe kí Rákélì rí i pé ó yẹ kí Léà bínú lóòótọ́, nítorí ó fèsì pé: “Nítorí ìdí yẹn, òun yóò sùn tì ọ́ ní òru òní ní pàṣípààrọ̀ fún àwọn máńdírékì ọmọkùnrin rẹ.” Látàrí èyí, bí Jékọ́bù ṣe ń dé lálẹ́ ọjọ́ náà ni Léà ti ń sọ fún un pé: “Èmi ni ìwọ yóò bá ní ìbálòpọ̀, nítorí pé mo ti fi àwọn máńdírékì ọmọkùnrin mi háyà rẹ pátápátá.”—Jẹ́nẹ́sísì 30:15, 16.

  • Àwọn Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò Tí wọn Ò Láyọ̀ Ló “Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì”
    Ilé Ìṣọ́—2007 | October 1
    • Àwọn máńdírékì yìí kò ṣèrànwọ́ kankan. Ẹ̀yìn ọdún mẹ́fà tí Rákélì ti wà lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ ló tó wá lóyún tó sì bí Jósẹ́fù, ohun tó sì mú kíyẹn ṣeé ṣe ni pé Jèhófà “rántí” rẹ̀, ó sì dáhùn àdúrà rẹ̀. Ìgbà yẹn ni Rákélì tó lè sọ pé: “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn mi kúrò!”—Jẹ́nẹ́sísì 30:22-24.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́