-
‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’Ilé Ìṣọ́—2014 | November 1
-
-
Bí àníyàn Jósẹ́fù ṣe pọ̀ tó, kò jẹ́ kí ọkàn òun pami. Ó fọkàn síṣẹ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ̀, Jèhófà sì fi ìbùkún sí i. Pọ́tífárì rí i pé Jèhófà Ọlọ́run táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sìn ń wà pẹ̀lú ọ̀dọ́kùnrin yìí, òjò ìbùkún rẹ̀ sì ń rọ̀ dé ilé òun. Èyí mú kí Jósẹ́fù di ààyò lójú Pọ́tífárì ọ̀gá rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó fi yàn án ṣe olórí ilé rẹ̀, gbogbo ohun tí ó sì jẹ́ tirẹ̀ ni ó fi lé e lọ́wọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 39:3-6.
-
-
‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’Ilé Ìṣọ́—2014 | November 1
-
-
Ọ̀rọ̀ Bíbélì tá à ń bá bọ̀ sọ síwájú sí i pé, ‘Jósẹ́fù di ọkùnrin tó rẹwà, ìrísí rẹ̀ sì dùn ún wò.’ Ọmọ àná ti wá di géńdé báyìí. Àmọ́ wàhálà ńlá ni ẹwà rẹ̀ yìí ṣì ń bọ̀ wá dá sílẹ̀ fún un. Ẹ̀bùn ni ẹwà lóòótọ́, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, àtẹni tá a fẹ́ àtẹni tá ò fẹ́ ló máa ń gbá tọni lẹ́yìn nítorí ẹwà ẹni.
Aya Pọ́tífárì kíyè sí pé Jósẹ́fù jẹ́ adúróṣinṣin
-