ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’
    Ilé Ìṣọ́—2014 | November 1
    • Ní ti Jósẹ́fù, ìyà ló yọrí sí fún un. Ìyà tó sì jẹ lórí ọ̀rọ̀ yìí ò ṣeé kó. Ìyàwó Pọ́tífárì ti kanrí Jósẹ́fù mọ́nú pé òun máa gbẹ̀san lára rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kébòòsí, ó ń pe àwọn òṣìṣẹ́ tó kù pé kí wọ́n gba òun o. Ó tún purọ́ pé Jósẹ́fù fẹ́ fipá bá òun sùn lòun ṣe figbe ta. Èyí ló jẹ́ kó sá lọ láì mú ẹ̀wù rẹ̀. Obìnrin yìí ò sọ ẹ̀wù náà sílẹ̀ títí tí ọkọ̀ rẹ̀ fi dé. Nígbà tí ìyẹn dé, ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé Jósẹ́fù fẹ́ fipá bá òun sùn, ó sì dẹ́bi fún ọkọ rẹ̀ pé ká ní kò gba ẹrú burúkú yẹn sílé ni, irú ìyà àti ìwọ̀sí yìí ò ní ta lé òun. Nígbà tí Pọ́tífárì ọkọ rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, “ìbínú rẹ̀ ru”! Kò tiẹ̀ dúró gbọ́ àlàyé tó fi sọ Jósẹ́fù sẹ́wọ̀n.​—Jẹ́nẹ́sísì 39:​13-​20.

      ‘WỌ́N FI ṢẸKẸ́ṢẸKẸ̀ DE ẸSẸ̀ RẸ̀’

      A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ bí túbú wọn ṣe rí nílẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì. Àmọ́ ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí fi hàn pé ńṣe ni wọ́n mọ àwọn ilé náà bí odi gìrìwò, ó sì ní ẹ̀wọ̀n àtàwọn àjàalẹ̀ lóríṣiríṣi. Jósẹ́fù pe túbú náà ní “ihò ẹ̀wọ̀n,” èyí tó fi hàn pé ó jẹ́ ibi tó ṣókùnkùn tó sì ṣòro láti rọ́nà sá lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 40:15) Ìwé Sáàmù tún jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n fìyà jẹ Jósẹ́fù gan-an nínú túbú yẹn, ó ní: ‘Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ẹsẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì fi irin de ọrùn rẹ̀.’ (Sáàmù 105:​17, 18) Nígbà míì, àwọn ará Íjíbítì máa ń fi àwọn ìjàrá de àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́ ní àdè-sẹ́yìn ní ìgbọ̀nwọ́, àwọn míì sì rèé ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ onírin ńlá tó dà bí akọ́rọ́ ni wọ́n á fi kọ́ wọn lọ́rùn pa pọ̀ mọ́ra. Ẹ ò rí i pé ìyà ńlá ni Jósẹ́fù jẹ lẹ́wọ̀n, bẹ́ẹ̀ kò mọwọ́ kò mẹsẹ̀!

      Kì í ṣe ìgbà díẹ̀ ni Jósẹ́fù fi wà lẹ́wọ̀n yẹn o. Bíbélì sọ pé Jósẹ́fù “ń bá a lọ láti wà níbẹ̀ nínú ilé ẹ̀wọ̀n” náà, tó fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọdún ló lò nínú ẹ̀wọ̀n burúkú yẹn.a Wọn ò dá ọjọ́ tàbí ìgbà kankan fún un tí wọ́n á tú u sílẹ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọjọ́ ń gorí ọjọ́, ọ̀sẹ̀ ń yí lu ọ̀sẹ̀, oṣù ń yí lu oṣù. Síbẹ̀, Jósẹ́fù ò kárísọ, kò sì sọ̀rètí nù, báwo ló ṣe ṣe é?

  • ‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’
    Ilé Ìṣọ́—2014 | November 1
    • a Bíbélì jẹ́ ká mò pé Jósẹ́fù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún [17] tàbí méjìdínlógún [18] nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé lọ́dọ̀ Pọ́tífárì, ibẹ̀ ló wà fúngbà díẹ̀ tó fi dàgbà. Àmọ́ igbà tó máa fi jáde lẹ́wọ̀n, ó ti pé ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún.​—Jẹ́nẹ́sísì 37:2; 39:6; 41:46

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́