ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé (mwbr20) | September
    • Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Áárónì ò lè sọ pé òun ò mọ̀ nípa aṣemáṣe mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wáyé náà, ó hàn pé òun kọ́ ni òléwájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jọ pé ṣe ló gbà káwọn míì mú kóun lọ́wọ́ sóhun tí kò tọ́ tàbí kẹ̀, ṣe ló fi ìtìjú kárùn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní kó ṣe ọlọ́run kan fún àwọn, ó yẹ kó rántí kó sì ronú lórí òfin Ọlọ́run tó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ èèyàn láti hùwà ibi.” (Ẹk 23:2) Láìfi gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn pè, Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ Áárónì dáadáa, Jésù Ọmọ Ọlọ́run sì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nígbà tó wà láyé, kódà ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ara ìṣètò Ọlọ́run ni báwọn ọmọ Áárónì ṣe ń ṣiṣẹ́ àlùfáà.​—Sm 115:​10, 12; 118:3; 133:​1, 2; 135:19; Mt 5:​17-19; 8:4.

  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé (mwbr20) | September
    • Ọlọ́run ò fẹ́ kéèyàn máa fi igbá kan bọ̀kan nínú tó bá dọ̀rọ̀ ìgbẹ́jọ́ tàbí kéèyàn máa ṣègbè. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ẹni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ wé ẹni tó dijú sí òtítọ́ tàbí afọ́jú. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Òfin Mósè rọ àwọn aṣáájú tàbí àwọn adájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọn ò si gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn nǹkan yìí lè mú kí wọ́n gbé ẹ̀bi fún aláre kí wọ́n sì gbé àre fún ẹlẹ́bi. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí àwọn tó ríran kedere lójú.” (Ẹk 23:8) Níbòmíì, ó sọ pé: “Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí ọlọ́gbọ́n lójú.” (Di 16:19) Bí adájọ́ kan bá fẹ́ràn àtimáa ṣe ẹ̀tọ́, kódà kó jẹ́ni tó ní làákàyè, tó bá fi lè gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn tó ń bójú tó ẹjọ́ wọn, láìfura ó lè yí ìdájọ́ po, ó sì lè mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ẹ̀bùn tí wọ́n fún un. Abájọ tí Òfin Ọlọ́run fi kìlọ̀ fáwọn onídàájọ́ pé kí wọ́n kíyè sára, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ èrò wọn nípa ẹnì kan tàbí ẹ̀bùn táwọn èèyàn ń fún wọn lè mú kí wọ́n yí ìdájọ́ po. Òfin yẹn sọ pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ rẹ́ aláìní jẹ tàbí kí ẹ ṣe ojúsàájú sí ọlọ́rọ̀.” (Le 19:15) Torí náà, adájọ́ kan ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò tóun ní nípa ẹnì kan mú kóun gbé àre fún olówó torí pé ó lówó lọ́wọ́, kò sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ torí kó lè rí ojúure àwọn èèyàn.​—Ẹk 23:​2, 3.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́