-
Yọ̀ǹda Ara Rẹ Tinútinú, Kí Ìyìn Lè Jẹ́ ti Jèhófà!Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017 | April
-
-
6. Kí ló jẹ́ kó dà bíi pé wẹ́rẹ́ làwọn ọmọ ogun Jábínì máa ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
6 Fún ogún [20] ọdún ni Jábínì tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Kénáánì fi “ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára lọ́nà lílekoko.” Ìnira náà le débi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé lábúlé kò láyà láti jáde nílé. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní nǹkan ìjà tí wọ́n lè fi gbéjà ko àwọn ọ̀tá wọn, wọn ò sì léyìí tí wọ́n á fi dáàbò bo ara wọn tógun bá dé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun onídòjé irin làwọn ọ̀tá wọn ní.—Oníd. 4:1-3, 13; 5:6-8.a
-
-
Yọ̀ǹda Ara Rẹ Tinútinú, Kí Ìyìn Lè Jẹ́ ti Jèhófà!Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017 | April
-
-
a Irin gígùn tí ẹnu rẹ̀ mú bérébéré ni dòjé irin tí ẹsẹ yìí ń sọ, nígbà míì ó máa ń dà bí akọ́rọ́, ó sì máa ń yọ síta látinú àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà. Ta ló máa gbójúgbóyà sún mọ́ irú kẹ̀kẹ́ ogun tó ń bani lẹ́rù bẹ́ẹ̀?
-