ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Obìnrin Títayọ Lọ́lá”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 22, 23. (a) Kí ló ṣeé ṣe kí ẹ̀bùn tí Bóásì fún Rúùtù túmọ̀ sí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Kí ni Náómì sọ pé kí Rúùtù ṣe?

      22 Nígbà tí Rúùtù pa dà délé ní ìdájí ọjọ́ yẹn, Náómì sọ pé: “Ta ni ọ́, ọmọbìnrin mi?” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilẹ̀ tí kò tíì mọ́ ló mú kí Náómì béèrè bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó tún fẹ́ mọ̀ bóyá opó tí kò tíì ní ẹnikẹ́ni lọ́kàn ni Rúùtù tàbí ó ti ní ẹni tó máa fẹ́. Láìjáfara, Rúùtù sọ gbogbo bí nǹkan ṣe lọ sí láàárín òun àti Bóásì fún ìyá ọkọ rẹ̀. Ó tún fi ọkà bálì tí Bóásì fi rán an sí Náómì jíṣẹ́.c—Rúùtù 3:16, 17.

  • “Obìnrin Títayọ Lọ́lá”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • c Òṣùwọ̀n mẹ́fà ọkà bálì ni Bóásì bù fún Rúùtù, àmọ́ Bíbélì kò sọ ohun tó fi díwọ̀n rẹ̀. Bóyá ńṣe ni Bóásì ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé bí ìsinmi Sábáàtì ṣe máa ń tẹ̀ lé ọjọ́ iṣẹ́ mẹ́fà, bákan náà ni Ọlọ́run ṣe máa tó fi ọkọ àti ilé aláyọ̀ rọ́pò gbogbo ọjọ́ tí Rúùtù ti fi jìyà gẹ́gẹ́ bí opó. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tó fà á tó fi bu òṣùwọ̀n mẹ́fà, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹ̀kún ṣọ́bìrì mẹ́fà, fún Rúùtù ni pé kò lè gbé ju ìyẹn lọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́