-
Ọkùnrin Kan Tí Ó Tẹ́ Ọkàn Jèhófà Lọ́rùnIlé Ìṣọ́—2011 | September 1
-
-
Iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí Dáfídì ń ṣe kò ṣàìní ewu nínú. Ní àárín àwọn òkè yìí ló ti gbéjà ko kìnnìún àti béárì tó gbé àgùntàn nínú agbo ẹran.a Ọ̀dọ́kùnrin onígboyà yìí lé àwọn ẹranko ajẹranjeegun yìí, ó pa wọ́n, ó sì gba àwọn àgùntàn náà lẹ́nu wọn. (1 Sámúẹ́lì 17:34-36) Ó lè jẹ́ pé ní àkókò yìí ni Dáfídì kọ́ bí ó ṣe lè lo kànnàkànnà. Ibi tí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wà kò jìnnà sí ìlú ìbílẹ̀ Dáfídì. Àwọn tó jẹ́ atamátàsé nínú ẹ̀yà yìí lè fi kànnàkànnà gbọn òkúta ba “fọ́nrán irun tí kò sì ní tàsé.” Bẹ́ẹ̀ náà ni Dáfídì ṣe máa ń gbọn kànnàkànnà bá nǹkan láìtàsé.—Àwọn Onídàájọ́ 20:14-16; 1 Sámúẹ́lì 17:49.
-
-
Ọkùnrin Kan Tí Ó Tẹ́ Ọkàn Jèhófà Lọ́rùnIlé Ìṣọ́—2011 | September 1
-
-
a Béárì aláwọ̀ ilẹ̀ ti orílẹ̀-èdè Síríà, tí wọ́n máa ń rí ní Palẹ́sìnì nígbà kan, wúwo tó ogóje [140] kìlógíráàmù, ó sì lè fi ọwọ́ rẹ̀ pàǹpà tó ní èékánná pa èèyàn àti ẹranko. Ìgbà kan wà tí kìnnìún pọ̀ lágbègbè yẹn. Aísáyà 31:4 sọ pé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn olùṣọ́ àgùntàn” kò ní lè lé “ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀” kúrò nídìí ẹran tó fẹ́ jẹ.
-