ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ohun Tí O Jẹ́jẹ̀ẹ́, San Án”
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017 | April
    • 7. (a) Ẹ̀jẹ́ wo ni Hánà jẹ́, kí sì nìdí tó fi jẹ́jẹ̀ẹ́ náà? Kí ló wá ṣẹlẹ̀? (b) Kí ni ẹ̀jẹ́ tí Hánà jẹ́ máa gba pé kí Sámúẹ́lì ṣe? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      7 Àpẹẹrẹ ẹlòmíì tó ṣe ohun tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà ni Hánà. Nǹkan ò dẹrùn fún un lásìkò tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà torí pé kò rọ́mọ bí, bẹ́ẹ̀ sì ni orogún rẹ̀ ń fojú pọ́n ọn. (1 Sám. 1:​4-7, 10, 16) Hánà sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Jèhófà, ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, láìkùnà, bí ìwọ yóò bá wo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ níṣẹ̀ẹ́, tí o sì rántí mi ní ti tòótọ́, tí ìwọ kì yóò sì gbàgbé ẹrúbìnrin rẹ, tí o sì fún ẹrúbìnrin rẹ ní ọmọ tí ó jẹ́ ọkùnrin ní ti tòótọ́, èmi yóò fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ fẹ́lẹ́ kì yóò sì kan orí rẹ̀.”a (1 Sám. 1:11) Ọlọ́run gbọ́ àdúrà Hánà, ó sì bímọ ọkùnrin. Ẹ wo bí ìyẹn ṣe máa múnú rẹ̀ dùn tó! Síbẹ̀, kò gbàgbé ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún Ọlọ́run. Nígbà tó bí ọmọ náà, ó sọ pé: “Ọwọ́ Jèhófà ni mo ti béèrè rẹ̀.”​—1 Sám. 1:20.

  • “Ohun Tí O Jẹ́jẹ̀ẹ́, San Án”
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017 | April
    • a Ẹ̀jẹ́ tí Hánà jẹ́ fi hàn pé ọmọ náà máa jẹ́ Násírì jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé a máa ya ọmọ náà sọ́tọ̀, á sì fi gbogbo ọjọ́ ayé ẹ̀ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà.​—Núm. 6:​2, 5, 8.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́