ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Hùwà Ọlọgbọ́n
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 10 Báwo làwọn ọmọ ogun Dáfídì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ àṣekára yìí ṣe máa ń ṣe sí àwọn darandaran Nábálì? Tó bá wù wọ́n, wọ́n lè máa pa àgùntàn wọn jẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n dà bí ògiri tó ń dàábò bo agbo ẹran àtàwọn ìránṣẹ́ Nábálì. (Ka 1 Sámúẹ́lì 25:15, 16.) Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ewu ló máa ń wu àwọn àgùntàn àti àwọn tó ń dà wọ́n. Àwọn ẹranko ẹhànnà pọ̀ níbẹ̀ gan-an. Ààlà ilẹ̀ Ísírẹ́lì lápá gúúsù ò sì jìnnà síbẹ̀, torí náà àwọn onísùnmọ̀mí àti àwọn olè máa ń ti ilẹ̀ ibòmíì wá ṣọṣẹ́ lágbègbè náà lọ́pọ̀ ìgbà.b

  • Ó Hùwà Ọlọgbọ́n
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • b Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì máa rò ó pé iṣẹ́ ìsìn sí Jèhófà Ọlọ́run ni òun ń ṣe bí òun ṣe ń dáàbò bo àwọn onílẹ̀ àgbègbè yẹn àti agbo ẹran wọn. Nígbà yẹn, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù máa gbé ilẹ̀ náà. Torí náà, dídáàbò bo ilẹ̀ yẹn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá àtàwọn agbésùnmọ̀mí jẹ́ iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọ́run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́