-
Ó Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀ fún Ọlọ́run Nínú ÀdúràTẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
-
-
15, 16. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Hánà lẹ́yìn tó sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Jèhófà, tó sì jọ́sìn rẹ̀ nínú àgọ́ ìjọsìn? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hánà tí ìṣòro bá wọ̀ wá lọ́rùn tàbí tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò?
15 Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Hánà lẹ́yìn tó sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Jèhófà tó sì tún jọ́sìn rẹ̀ nínú àgọ́ ìjọsìn? Bíbélì sọ pé: “Obìnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì jẹun, ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́.” (1 Sám. 1:18) Bíbélì Mímọ́ sọ pé: “Kò sì fa ojú ro mọ́.” Ara tu Hánà. Ìdí ni pé ó ti fa ohun tó jẹ́ ìdààmú ọkàn rẹ̀ lé ẹni tó lágbára jù ú lọ fíìfíì lọ́wọ́, ìyẹn Baba rẹ̀ ọ̀run. (Ka Sáàmù 55:22.) Ǹjẹ́ ìṣòro kan wà tó tóbi jù fún Ọlọ́run? Rárá o, kò tíì sí irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ rí, kò sì lè sí láéláé!
16 Nígbà tí ìṣòro bá wọ̀ wá lọ́rùn tàbí tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò, á dára ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hánà, ká sọ̀rọ̀ fàlàlà fún Ẹni tí Bíbélì pè ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sm. 65:2) Tá a bá ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà wa, àwa náà á rí i pé Ọlọ́run lè fi “àlàáfíà” rẹ̀ “tí ó ta gbogbo ìrònú yọ” rọ́pò ìbànújẹ́ wa.—Fílí. 4:6, 7.
-
-
Ó Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀ fún Ọlọ́run Nínú ÀdúràTẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
-
-
18 Ìgbà wo ló tó hàn sí Pẹ̀nínà pé yẹ̀yẹ́ tí òun ń fi Hánà ṣe ò lè bà á nínú jẹ́ mọ́? Bíbélì kò sọ fún wa, àmọ́ gbólóhùn náà, “ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́” fi hàn pé inú Hánà bẹ̀rẹ̀ sí í dùn láti ìgbà yẹn lọ. Pẹ̀nínà wá rí i nígbà tó yá pé ìwà òǹrorò òun kò tu irun kankan lára Hánà mọ́. Látìgbà yẹn lọ, Bíbélì ò dárúkọ Pẹ̀nínà mọ́.
-