ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀ fún Ọlọ́run Nínú Àdúrà
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 9. Kí la rí kọ́ látinú bí Hánà ṣe yàn láti lọ sí Ṣílò bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ irú ìwà tí Pẹ̀nínà máa hù sí òun?

      9 Láti òwúrọ̀ kùtù ni tọmọdé tàgbà nínú ìdílé Ẹlikénà ti ń di ẹrù, bí wọ́n ṣe ń múra láti rìnrìn-àjò lọ sí Ṣílò. Ìdílé ńlá ni ìdílé Ẹlikénà, wọ́n sì máa rin ìrìn tó ju ọgbọ̀n kìlómítà lọ ní àwọn àgbègbè Éfúráímù tí òkè pọ̀ sí, kí wọ́n tó dé Ṣílò.b Ìrìn-àjò náà máa ń gbà tó ọjọ́ kan tàbí méjì téèyàn bá fi ẹsẹ̀ rìn ín. Hánà mọ ohun tí orogún rẹ̀ máa ṣe. Àmọ́, kò torí ìyẹn jókòó sílé. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere tó ṣì wúlò títí di òní lélẹ̀ fún àwa olùjọ́sìn Ọlọ́run. Kò bọ́gbọ́n mu ká jẹ́ kí ìwà àìtọ́ àwọn míì dí wa lọ́wọ́ láti máa sin Ọlọ́run. Tá a bá jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ sí wa, a ò ní rí ìbùkún Jèhófà gbà mọ́. Ìbùkún yẹn ló sì máa jẹ́ ká lè fara da ipò tó nira.

  • Ó Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀ fún Ọlọ́run Nínú Àdúrà
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • b Ó dà bíi pé ìlú ìbílẹ̀ Ẹlikénà, ìyẹn Rámà, ló wá ń jẹ́ Arimatíà nígbà ayé Jésù. Èyí ló jẹ́ ká mọ bí ìrìn-àjò náà ṣe gùn tó.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́