-
Obìnrin Náà Gbàdúrà Àtọkànwá sí Ọlọ́runIlé Ìṣọ́—2010 | July 1
-
-
ỌWỌ́ Hánà dí bo ṣe ń múra sílẹ̀ fún ìrìn àjò tí wọ́n fẹ́ lọ, ìyẹn ló gbà á lọ́kàn. Àkókò ayọ̀ ló yẹ kí àkókò náà jẹ́ nítorí ó jẹ́ àṣà Ẹlikénà, ọkọ rẹ̀, láti máa kó ìdílé rẹ̀ lọ ṣèjọsìn lọ́dọọdún ní àgọ́ ìjọsìn tó wà ní Ṣílò. Àkókò ìdùnnú ni Jèhófà fẹ́ kí àkókò yìí jẹ́. (Diutarónómì 16:15) Kò sí àní-àní pé látìgbà èwe ni inú Hánà ti máa ń dùn sí àwọn àjọyọ̀ yẹn. Àmọ́, àwọn nǹkan ti yí pa dà fún un láwọn ọdún àìpẹ́ yìí.
-
-
Obìnrin Náà Gbàdúrà Àtọkànwá sí Ọlọ́runIlé Ìṣọ́—2010 | July 1
-
-
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ọwọ́ gbogbo àwọn ará ilé dí bí wọ́n ṣe ń kó àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ lò. Àní gbogbo wọn, títí kan àwọn ọmọdé ni wọ́n ń múra ìrìn àjò náà. Ìrìn àjò tí gbogbo ìdílé náà máa rìn lọ sí Ṣílò yóò ju ọgbọ̀n kìlómítà lọ ní ìgbèríko Éfúráímù olókè.c Tí wọ́n bá fi ẹsẹ̀ rìn, yóò gbà wọ́n ní ọjọ́ kan tàbí méjì. Hánà mọ ohun tí orogún rẹ̀ lè ṣe. Àmọ́, kò dúró sílé. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn olùjọ́sìn Jèhófà títí di òní, pé kò bọ́gbọ́n mu láti jẹ́ kí ìwà àìtọ́ àwọn ẹlòmíràn ṣèdíwọ́ fún ìjọsìn wa sí Ọlọ́run. Tá a bá jẹ́ kí ìyẹn ṣẹlẹ̀, a ó pàdánù okun táá mú ká lágbára láti máa fara dà á.
-
-
Obìnrin Náà Gbàdúrà Àtọkànwá sí Ọlọ́runIlé Ìṣọ́—2010 | July 1
-
-
c Bí ìrìn àjò náà ṣe jìn tó yìí lè jẹ́ nítorí pé Rámà ìlú ìbílẹ̀ Ẹlikénà ni ibi tá a wá mọ̀ sí Arimatíà ní ọjọ́ Jésù.
-