Awọn Ará Gibioni—Wọn Wá Alaafia
ILU-NLA ori òkè ti o wà loke yii ni a ti dámọ̀ gẹgẹ bi eyi ti ó wà ni ọgangan ibi ti Gibioni igbaani duro si, nǹkan bii ibusọ mẹfa si ariwa Jerusalẹmu.
Ó ṣeeṣe ki o mọ pe Gibioni di ayọri-ọla laipẹ lẹhin ti Joṣua ṣamọna Isirẹli wọnu Ilẹ Ileri ti ó sì ṣẹgun Jẹriko. Awọn ará Kenani ti Gibioni mọ pe awọn kò lè duro lẹgbẹẹ Isirẹli, ti o ṣe kedere pe wọn ni itilẹhin atọrunwa. Ki ni ṣiṣe? Ni didọgbọn arúmọjẹ, awọn ara Gibioni ran awọn aṣoju ti wọn farahan gẹgẹ bi awọn arinrin-ajo lati ilẹ jijinna réré wá. Isapa yii siha alaafia ṣaṣeyọri, nitori pe Isirẹli dá majẹmu pẹlu wọn. Nigba ti ọgbọn àyínìke wọn di eyi ti a jádìí, awọn ará Gibioni di aṣẹ́gi ati apọnmi.
Ọlọrun kò ti nilati banujẹ pẹlu awọn eniyan ti wọn wá alaafia yii. Ó ti igbeja Joṣua fun awọn ará Gibioni lẹhin nigba ti awọn ọba marun-un doju ìjà kọ wọn. Jehofa tilẹ ṣe iṣẹ iyanu nipa mímú imọlẹ ọjọ gùn fun ìjà-ogun yẹn.—Joṣua 9:3-27; 10:1-14.
Awọn awalẹ̀ rí kòtò jijin, tabi adágún, ti a gbẹ́ sinu apata líle gbandi lori gegele yii. Awọn ará Gibioni lè tẹ àtẹ̀gùn wọnu eyi lọ ki wọn sì pọn omi lati inu iyàrá abẹ́lẹ̀ kan. Eyi ha ti lè jẹ́ “adágún Gibioni” ti a mẹnukan ni 2 Samuẹli 2:13 bi? Awọn awalẹpitan tun ṣàwárí awọn yàrá-abẹ́lẹ̀ ti a gbẹ́ wọnu apata naa ati ọpọ rẹpẹtẹ awọn irin-iṣẹ ti a fi ń ṣe waini. Bẹẹni, ó dabi pe Gibioni jẹ́ ibudo kan fun ṣiṣe waini.
Ni akoko Dafidi, àgọ́ tabi àgọ́-isin, ti Ọlọrun tootọ ni a fi si ìhín. Ọba Solomọni wá sihin-in lati ṣe awọn irubọ. Jehofa farahan Solomọni ninu àlá ó sì ṣeleri “ọkàn ọgbọn ati imoye” fun un bakan naa sì ni ọrọ̀ pẹlu. (1 Ọba 3:4-14; 2 Kironika 1:3) Ọrọ-ẹkọ ti ó wà ni oju-iwe 12 si 17 ninu itẹjade yii fihan pe awọn atọmọdọmọ awọn eniyan naa ti wọn gbé níhìn-ín ní Gibioni ni wọn ni anfaani lọna akanṣe laaarin orilẹ-ede Ọlọrun ni ikẹhin akoko. Iwọ ha mọ bi ó ti rí bi?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.