ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nígbà Tí ‘Ọkàn Tí Ó Ní Ìròbìnújẹ́ Tí Ó sì Wó Palẹ̀’ Bá Tọrọ Ìdáríjì
    Ilé Ìṣọ́—2010 | May 1
    • Kí Dáfídì má bàa wá àwáwí, Nátánì sọ ìtàn kan tó dájú pé ó máa wọ ọba tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn yìí lọ́kàn. Ìtàn náà dá lórí ọkùnrin méjì, ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ tálákà. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ní “àgùntàn àti màlúù púpọ̀ gan-an,” àmọ́ “abo ọ̀dọ́ àgùntàn kan” ni ọkùnrin tálákà náà ní. Àlejò wá kí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà, ó sì fẹ́ se oúnjẹ fún un. Àmọ́ dípò kó mú ọ̀kan lára àwọn àgùntàn rẹ̀, àgùntàn kan ṣoṣo tó jẹ́ ti ọkùnrin tálákà yẹn ló mú. Dáfídì rò pé ìtàn yẹn ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, ló bá fi ìbínú sọ pé: “Ikú tọ́ sí ọkùnrin tí ó ṣe èyí!” Kí nìdí? Dáfídì ṣàlàyé, ó ní: “Nítorí pé kò ní ìyọ́nú.”a—Ẹsẹ 2 sí 6.

  • Nígbà Tí ‘Ọkàn Tí Ó Ní Ìròbìnújẹ́ Tí Ó sì Wó Palẹ̀’ Bá Tọrọ Ìdáríjì
    Ilé Ìṣọ́—2010 | May 1
    • a Pípa àgùntàn fún àlejò jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà ṣeni lálejò. Àmọ́ ìwà ọ̀daràn ni téèyàn bá jí àgùntàn, ìjìyà tó wà fún ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, á san mẹ́rin dípò ẹyọ kan tí ó jí. (Ẹ́kísódù 22:1) Lójú Dáfídì, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn kò láàánú rárá bó ṣe mú àgùntàn yẹn. Ńṣe ló tipasẹ̀ ohun tó ṣe yìí gba ẹran tó lè máa pèsè wàrà àti irun àgùntàn tí ìdílé ọkùnrin tálákà náà nílò, tó sì máa bí àwọn ọmọ tó máa di agbo àgùntàn ọkùnrin yìí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́