ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jerúsálẹ́mù ní Àkókò Tí A Kọ Bíbélì—Kí Ni Ẹ̀kọ́ Ìwalẹ̀pìtàn Ṣí Payá?
    Ilé Ìṣọ́—1997 | June 15
    • Ẹnu ọ̀nà omi ìgbàanì tí ó jẹ́ ti ìlú ńlá náà wà lẹ́bàá ògiri yìí, apá kan èyí tí ó dà bí èyí tí ó ti wà láti ọjọ́ Dáfídì. Àwọn gbólóhùn kan nínú Bíbélì nípa ihò omi Jerúsálẹ́mù ti gbé ọ̀pọ̀ ìbéèrè dìde. Fún àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé “ẹnikẹ́ni tí ó bá kọlu àwọn ará Jébúsì, kí ó gba ti ibi ihò omi kan” ọ̀tá “lára.” (Sámúẹ́lì Kejì 5:8, NW) Jóábù olórí ogun Dáfídì ṣe èyí. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ihò omi” túmọ̀ sí gan-an?

  • Jerúsálẹ́mù ní Àkókò Tí A Kọ Bíbélì—Kí Ni Ẹ̀kọ́ Ìwalẹ̀pìtàn Ṣí Payá?
    Ilé Ìṣọ́—1997 | June 15
    • Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ pé ṣẹ́lẹ̀rú Gíhónì ni orísun omi ìlú ńlá ìgbàanì náà. Ó wà lẹ́yìn ògiri ìlú ńlá náà, ṣùgbọ́n ó sún mọ́ ọn gan-an tí ó fi ṣeé ṣe láti gbẹ́ ọ̀nà omi kan àti ihò tí ó jìn ní mítà 11, tí yóò jẹ́ kí àwọn olùgbé ibẹ̀ lè máa pọn omi láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa jáde sẹ́yìn odi. A mọ èyí sí Ihò Warren, tí a sọ ní orúkọ Charles Warren, tí ó ṣàwárí ihò náà ní 1867. Ṣùgbọ́n nígbà wo ni a gbẹ́ ọ̀nà omi àti ihò náà? Wọ́n ha ti wà ní àkókò Dáfídì bí? Èyí ha ni ihò omi tí Jóábù lò bí? Dan Gill dáhùn pé: “Láti mọ̀ bóyá Ihò Warren ní tòótọ́ jẹ́ iho oníṣẹ́ṣẹ́ funfun ti àgbàrá gbẹ́, a ṣàyẹ̀wò èépá calcium carbonate lára ogiri rẹ̀ gbágungbàgun láti wò ó bóyá ó ní carbon-14. Kò ní i rárá, èyí tí ó fi hàn pé èépá náà tí wà fún ohun tí ó lé ní 40,000 ọdún: Èyí pèsè ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé kì í ṣe ènìyàn ni ó gbẹ́ ihò náà.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́