-
Jẹ́ “Onítara Fún Iṣẹ́ Àtàtà”!Ilé Ìṣọ́—2009 | June 15
-
-
4, 5. Àwọn ọ̀nà wo làwọn ọba Júdà mẹ́rin kan gbà jẹ́ onítara fún iṣẹ́ àtàtà?
4 Ásà, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà àti Jòsáyà ṣètò láti mú ìbọ̀rìṣà kúrò nílẹ̀ Júdà. Ásà “mú àwọn pẹpẹ ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn ibi gíga kúrò, ó sì fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ túútúú, ó sì ké àwọn òpó ọlọ́wọ̀ lulẹ̀.” (2 Kíró. 14:3) Ìtara tí Jèhóṣáfátì ní fún ìjọsìn Jèhófà jẹ́ kó ní ìgboyà láti “mú àwọn ibi gíga àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀ kúrò ní Júdà.”—2 Kíró. 17:6; 19:3.a
-
-
Jẹ́ “Onítara Fún Iṣẹ́ Àtàtà”!Ilé Ìṣọ́—2009 | June 15
-
-
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ibi gíga tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbọ̀rìṣà ni Ásà mú kúrò, kì í ṣàwọn ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn Jèhófà. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n tún àwọn ibi gíga míì kọ́ lọ́wọ́ ìparí ìṣàkóso Ásà, kó wá jẹ́ pé Jèhóṣáfátì ọmọ ẹ̀ ló wá mú àwọn yẹn kúrò.—1 Ọba 15:14; 2 Kíró. 15:17.
-