-
“Ẹ̀san Wà fún Ìgbòkègbodò Yín”Ilé Ìṣọ́—2012 | August 15
-
-
Lẹ́yìn tí Ásà dé látojú ogun, wòlíì Asaráyà lọ pàdé rẹ̀. Ó fún un ní ìṣírí, ó sì tún kìlọ̀ fún un. Ó ní: “Gbọ́ mi, ìwọ Ásà àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì! Jèhófà wà pẹ̀lú yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà pẹ̀lú rẹ̀; bí ẹ bá sì wá a, òun yóò jẹ́ kí ẹ rí òun, ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi í sílẹ̀, òun yóò fi yín sílẹ̀. . . . Ẹ jẹ́ onígboyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọwọ́ yín rọ jọwọrọ, nítorí pé ẹ̀san wà fún ìgbòkègbodò yín.”—2 Kíró. 15:1, 2, 7.
Àwọn ọ̀rọ̀ yìí lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Wọ́n fi hàn pé Jèhófà yóò wà pẹ̀lú wa, tá a bá ń fi ìṣòtítọ́ sìn ín. Wọ́n mú kó dá wa lójú pé ó máa gbọ́ tiwa tá a bá ké pè é fún ìrànlọ́wọ́. Asaráyà sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà.” Ó sábà máa ń gba pé ká jẹ́ onígboyà ká tó lè ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ onígboyà.
-
-
“Ẹ̀san Wà fún Ìgbòkègbodò Yín”Ilé Ìṣọ́—2012 | August 15
-
-
Àmọ́ ṣá o, wòlíì Asaráyà tún mẹ́nu kan ohun búburú tó lè ṣẹlẹ̀. Ó kìlọ̀ pé: “Bí ẹ bá fi [Jèhófà] sílẹ̀, òun yóò fi yín sílẹ̀.” Ká má ṣe gbà kí èyí ṣẹlẹ̀ sí wa láé, torí pé àbájáde rẹ̀ kì í dára! (2 Pét. 2:20-22) Ìwé Mímọ́ kò sọ ìdí tí Jèhófà fi fún Ásà ní ìkìlọ̀ yìí, àmọ́ Ásà kò ṣiṣẹ́ lórí ìkìlọ̀ náà.
-