-
Ṣé Wàá Fọkàn sí Àwọn Ohun Tá A Ti Kọ Sílẹ̀?Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017 | March
-
-
12 Bíbélì ò sọ ohun tó fà á tí Hesekáyà fi di agbéraga. Ṣó ṣeé ṣe kó jẹ́ tìtorí pé ó ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Ásíríà àbí torí pé Ọlọ́run wò ó sàn lọ́nà ìyanu? Ṣó lè jẹ́ torí pé ó ní “ọrọ̀ àti ògo” tó pọ̀ gan-an? Ohun yòówù kó jẹ́, torí pé Hesekáyà gbéra ga, kò mọyì àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ṣe fún un. Ó mà ṣe o! Lóòótọ́ ọkàn tó pérépéré ni Hesekáyà fi sin Jèhófà, síbẹ̀ ìgbà kan wà tó ṣe ohun tí kò tọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, “Hesekáyà rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,” Jèhófà sì pinnu pé òun ò ní fìyà jẹ Hesekáyà àtàwọn èèyàn rẹ̀.—2 Kíró. 32:25-27; Sm. 138:6.
-
-
Ṣé Wàá Fọkàn sí Àwọn Ohun Tá A Ti Kọ Sílẹ̀?Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017 | March
-
-
14 Á dáa ká rántí ọ̀rọ̀ Jésù nígbà táwọn èèyàn bá ń yìn wá, ó ní: “Nígbà tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn lé yín lọ́wọ́ tán, ẹ wí pé, ‘Àwa jẹ́ ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun. Ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe.’ ” (Lúùkù 17:10) Ẹ jẹ́ ká máa rántí àpẹẹrẹ Hesekáyà táwọn èèyàn bá ń yìn wá. Ẹ̀mí ìgbéraga ni kò jẹ́ kí Hesekáyà mọyì àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ṣe fún un. Tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣe fún wa, a ò ní gbéra ga. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà la máa gbógo fún. Ó ṣe tán, Jèhófà ló fún wa ní Ìwé Mímọ́, òun náà ló sì ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tì wá lẹ́yìn.
-