ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 18. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Módékáì fi kọ̀ láti tẹrí ba fún Hámánì? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Lóde òní, báwo ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ní ìgbàgbọ́ ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Módékáì?

      18 Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Hámánì di ẹni ńlá láàfin Ahasuwérúsì. Ọba yan Hámánì sí ipò tó ga jù lọ ní ilẹ̀ ọba náà, ó fi í ṣe olórí agbani-nímọ̀ràn àti igbá kejì rẹ̀. Ọba tiẹ̀ tún pàṣẹ pé gbogbo ẹni tó bá rí olóyè yìí gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún un. (Ẹ́sít. 3:1-4) Ó ṣòro fún Módékáì láti pa àṣẹ yẹn mọ́. Ó mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí ọba, àmọ́ kì í ṣe débi tí òun á fi ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Òótọ́ kan ni pé ọmọ Ágágì ni Hámánì. Ìyẹn fi hàn pé àtọmọdọ́mọ Ágágì, ìyẹn ọba Ámálékì tí Sámúẹ́lì wòlíì Ọlọ́run pa, ni ọ̀gbẹ́ni yìí. (1 Sám. 15:33) Àwọn ọmọ Ámálékì yìí burú débi pé wọ́n sọ ara wọn di ọ̀tá Jèhófà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, ẹni tí ìparun tọ́ sí lójú Ọlọ́run ni gbogbo àwọn ọmọ Ámálékì.c (Diu. 25:19) Báwo wá ni Júù kan tó jẹ́ adúróṣinṣin á ṣe máa tẹrí ba fún Hámánì tó jẹ́ ará Ámálékì? Módékáì ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ó kọ̀ láti tẹrí ba fún un. Títí dòní, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ní ìgbàgbọ́ ti fi ẹ̀mí ara wọn jin ikú torí kí wọ́n lè tẹ̀ lé ìlànà inú Bíbélì tó sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

  • Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • c Ìgbà ayé Hesekáyà Ọba ni wọ́n ti pa “àṣẹ́kù” àwọn ọmọ Ámálékì, torí náà, ó ṣeé ṣe kí Hámánì wà lára àwọn tó gbẹ̀yìn pátápátá lára wọn.—1 Kíró. 4:43.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́