ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 19. Kí ni Hámánì fẹ́ ṣe? Báwo ló ṣe yí ọba lérò pa dà?

      19 Inú bí Hámánì gan-an. Àmọ́ kò wù ú kó jẹ́ pé Módékáì nìkan ló máa wá ọ̀nà láti pa. Ńṣe ló fẹ́ pa gbogbo àwọn èèyàn Módékáì run! Kí Hámánì bàa lè yí ọba lérò pa dà, ó sọ̀rọ̀ àwọn Júù láìdáa. Kò dárúkọ wọn fún ọba, àmọ́ ó jẹ́ kí ọba rí wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Ó pè wọ́n ní àwọn èèyàn “tí a tú ká, tí a sì yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ènìyàn.” Èyí tó tún wá burú jù níbẹ̀ ni bó ṣe sọ pé wọn kò pa àwọn àṣẹ ọba mọ́, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ paraku. Ó sọ pé òun máa san owó púpọ̀ jaburata sínú ibi ìṣúra ọba, kí wọ́n lè ná an láti fi pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní ilẹ̀ ọba náà run.d Ahasuwérúsì fún Hámánì ní òrùka àmì àṣẹ rẹ̀ pé kó fi lu àṣẹ èyíkéyìí tó bá ní lọ́kàn láti pa ní òǹtẹ̀.—Ẹ́sít. 3:5-10.

  • Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • d Hámánì sọ pé òun á fún ọba ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] tálẹ́ńtì fàdákà. Lóde òní, iye yẹn tó ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù dọ́là. Tó bá jẹ́ pé Ahasuwérúsì yìí ni Sásítà Kìíní, owó tí Hámánì sọ yìí ti ní láti wọ̀ ọ́ lójú. Ìdí ni pé Sásítà nílò owó rẹpẹtẹ tó máa ná sórí ogun tó ti wà lọ́kàn rẹ̀ tipẹ́ láti bá ilẹ̀ Gíríìsì jà, síbẹ̀ kò rọ́wọ́ mú nínú ogun náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́