ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 11/1 ojú ìwé 32
  • “Ta Ní Fi Ọgbọ́n Sínú Àwọn Ipele Àwọsánmà”?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ta Ní Fi Ọgbọ́n Sínú Àwọn Ipele Àwọsánmà”?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 11/1 ojú ìwé 32

“Ta Ní Fi Ọgbọ́n Sínú Àwọn Ipele Àwọsánmà”?

“NÍGBÀ tí ẹ bá rí àwọsánmà tí ń ṣú ní apá ìwọ̀-oòrùn, ní kíá ẹ̀yin a sọ pé, ‘Ìjì ń bọ̀,’ yóò sì rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ẹ bá sì rí pé ẹ̀fúùfù gúúsù ń fẹ́, ẹ̀yin a sọ pé, ‘Ìgbì ooru yóò wà,’ yóò sì ṣẹlẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ wọ̀nyí, tí Lúùkù, òǹkọ̀wé Ìhìnrere, kọ sílẹ̀, jẹ́ àpẹẹrẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ojú ọjọ́, bí wọ́n ti ń sọ ọ́ ní Palẹ́sìnì ìgbàanì. (Lúùkù 12:54, 55) Nínú àwọn ipò kan, àwọn ará ìgbàanì lè mọ àwọn àmì, kí wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ onígbà kúkúrú.

Lónìí, àwọn onímọ̀ ìwojú-ọjọ́-sàsọtẹ́lẹ̀ ń lo àwọn ohun èlò tó lágbára, bí àwọn sátẹ́láìtì tí ń yí ayé po, ohun èlò Doppler onírédíò, àti àwọn kọ̀ǹpútà lílágbára, láti mọ bí ipò ojú ọjọ́ yóò ṣe rí fún àkókò tó pẹ́ ju ti ìgbà yẹn lọ. Ṣùgbọ́n àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọn máa ń forí ṣánpọ́n lọ́pọ̀ ìgbà. Kí ló fà á?

Àwọn ohun tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ pípéye nípa ojú ọjọ́ ṣòro pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìyípadà òjijì nínú ìwọ̀n ìgbóná tàbí ìtutù ojú ọjọ́, ọ̀rinrin, ìwọ̀n ìwúwo afẹ́fẹ́, ìwọ̀n ìyára bí afẹ́fẹ́ ṣe ń fẹ́, àti ìhà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ gbà lè dojú nǹkan rú. Láfikún sí ìwọ̀nyí ni àjọṣe dídíjú tó wà láàárín oòrùn, kùrukùru, àti òkun, èyí tí kò tíì yé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní kíkún. Nítorí ìdí yẹn, sísọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ojú ọjọ́ ṣì jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ tí kò ṣe pàtó.

Ìmọ̀ kéréje tí ènìyàn ní nípa ojú ọjọ́ rán wa létí àwọn ìbéèrè tí a bi Jóòbù pé: “Ta ní bí ìrì tí ń sẹ̀? Ikùn ta ni omi dídì ti jáde wá ní ti gidi? . . . Ìwọ ha lè gbé ohùn rẹ sókè àní dé àwọsánmà, kí ìrọ́sókè-sódò àgbájọ omi lè bò ọ́? . . . Ta ní fi ọgbọ́n sínú àwọn ipele àwọsánmà, tàbí tí ó fi òye fún ohun àrà ojú sánmà? Ta ní lè fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmà ní pàtó, tàbí àwọn ìṣà omi ọ̀run—ta ní lè mú wọn dà jáde?”—Jóòbù 38:28-37.

Ìdáhùn gbogbo ìbéèrè wọ̀nyí ni, Ènìyàn kọ́, Jèhófà Ọlọ́run ni. Ní tòótọ́, bí ó ti wù kí ó jọ pé ènìyàn gbọ́n tó, ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa ga jìnnàjìnnà. Ó jẹ́ ìwà onífẹ̀ẹ́ fún un pé ó ti mú kí ọgbọ́n rẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa nínú àwọn ojú ìwé Bíbélì, kí a lè ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé wa.—Òwe 5:1, 2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́