-
Jèhófà—Alágbára ŃláIlé Ìṣọ́—2000 | March 1
-
-
5. Kí ni ẹ̀rí agbára Jèhófà tí a rí nínú iṣẹ́ rẹ̀?
5 Tí a bá ‘wá iṣẹ́ Ọlọ́run kiri’ bí Dáfídì ti ṣe, a ó rí ẹ̀rí agbára rẹ̀ níbi gbogbo—ì báà jẹ́ nínú ẹ̀fúùfù àti ìgbì omi, nínú àrá àti mànàmáná, tàbí nínú àwọn alagbalúgbú odò àtàwọn òkè ńláńlá. (Sáàmù 111:2; Jóòbù 26:12-14) Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe rán Jóòbù létí, àwọn ẹranko pàápàá ń jẹ́rìí sí i pé Ó lágbára tó pọ̀. Lára àwọn wọ̀nyí ni Béhémótì, tàbí erinmi. Jèhófà sọ fún Jóòbù pé: “Agbára rẹ̀ wà ní ìgbáròkó rẹ̀ . . . Egungun rẹ̀ lílágbára dà bí àwọn ọ̀pá irin àsèjiná.” (Jóòbù 40:15-18) Bí ẹní mowó ní wọ́n ṣe mọ̀ nípa agbára tí akọ màlúù ìgbẹ́ ní láwọn àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì, Dáfídì sì gbàdúrà pé kí a pa òun mọ́ kúrò ‘ní ẹnu kìnnìún àti kúrò lọ́wọ́ ìwo akọ màlúù ìgbẹ́.”—Sáàmù 22:21; Jóòbù 39:9-11.
6. Kí ni akọ màlúù ṣàpẹẹrẹ nínú Ìwé Mímọ́, èé ṣe tí ó sì fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
6 Nítorí agbára tí akọ màlúù ní, a lò ó nínú Bíbélì láti ṣàpèjúwe agbára Jèhófà.c Ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nípa ìtẹ́ Jèhófà ṣàpèjúwe ẹ̀dá alààyè mẹ́rin, tí ọ̀kan nínú wọn ní ojú bíi ti akọ màlúù. (Ìṣípayá 4:6, 7) Láìsí àní-àní, ọ̀kan lára ànímọ́ Jèhófà tó ṣe kókó tí àwọn kérúbù wọ̀nyí ń fi hàn ni agbára. Àwọn mìíràn ni ìfẹ́, ọgbọ́n, àti ìdájọ́ òdodo. Níwọ̀n bí a ti rí i pé agbára jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, lílóye agbára rẹ̀ dáradára, kí a sì mọ bó ṣe ń lò ó yóò mú kí a túbọ̀ sún mọ́ ọn, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti fara wé àpẹẹrẹ rẹ̀ nípa lílo agbára èyíkéyìí tó bá wà níkàáwọ́ wa dáradára—Éfésù 5:1.
-
-
Jèhófà—Alágbára ŃláIlé Ìṣọ́—2000 | March 1
-
-
c Akọ màlúù ìgbẹ́ tí a tọ́ka sí nínú Bíbélì ní láti jẹ́ ẹhànnà akọ màlúù (urus lédè Látìn). Ní ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, a rí àwọn ẹranko wọ̀nyí ní Gaul (tí a ń pè ní ilẹ̀ Faransé báyìí), ohun tí Julius Caesar sì kọ nípa wọn nìyí: “Àwọn urí wọ̀nyí tóbi tó erin dáadáa, àmọ́, nínú ìṣe, àwọ̀, àti ní ìrísí wọn, akọ màlúù ni wọ́n. Agbára wọn pọ̀, eré sì ń bẹ lẹ́sẹ̀ wọn: tí wọn bá fi lè rí ènìyàn tàbí ẹranko, kíá ni wọn óò yọwọ́ ìjà.”
-