-
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Wa?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 25
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Wa?
Bíbélì sọ pé ‘ọlọ́jọ́ kúkúrú ni àwa èèyàn, wàhálà tá à ń dojú kọ sì pọ̀ gan-an.’ (Jóòbù 14:1) Ṣé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí nǹkan rí fún wa nìyí? Tó bá jẹ́ pé ohun tó fẹ́ kọ́ nìyẹn, kí wá nìdí tó fi dá wa? Ṣé ayé ṣì máa rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́? Jẹ́ ká wo ohun tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa èyí.
1. Irú ìgbésí ayé wo ni Ọlọ́run ń fẹ́ fún wa?
Ìgbésí ayé tó dáa jù lọ ni Jèhófà ń fẹ́ fún wa. Nígbà tí Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ó fi wọ́n sínú Párádísè kan tó rẹwà, tí Bíbélì pè ní ọgbà Ẹ́dẹ́nì. Lẹ́yìn náà, “Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.’” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Jèhófà fẹ́ kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sọ gbogbo ayé di Párádísè, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn ẹranko. Ó fẹ́ kí àwa èèyàn ní ìlera pípé, ká sì wà láàyè títí láé.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ayé ò tíì rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́,a àwọn ohun rere tó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa kò tíì yí pa dà. (Àìsáyà 46:10, 11) Ó ṣì fẹ́ káwọn onígbọràn máa gbé ayé títí láé, láìsí ìṣòro kankan.—Ka Ìfihàn 21:3, 4.
2. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ gbé ìgbé ayé tó dáa ní báyìí?
Jèhófà dá wa lọ́nà tó fi máa ń wù wá láti wá “ìtọ́sọ́nà” rẹ̀. Ìdí nìyẹn tá a fi ń fẹ́ láti mọ̀ ọ́n, ká sì máa jọ́sìn rẹ̀. (Ka Mátíù 5:3-6.) Ó fẹ́ ká sún mọ́ òun dáadáa, ká máa “rìn ní gbogbo ọ̀nà” òun, ká máa “nífẹ̀ẹ́” òun, ká sì máa sin òun pẹ̀lú “gbogbo ọkàn” wa. (Diutarónómì 10:12; Sáàmù 25:14) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa ní ayọ̀ tòótọ́, láìka àwọn ìṣòro wa sí. Tá a bá ń sin Jèhófà, ayé wa máa dáa, ọkàn wa sì máa balẹ̀.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo bí ọ̀nà tí Jèhófà gbà dá ayé yìí ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an àti ohun tí Bíbélì sọ nípa ìdí tí Jèhófà fi dá wa.
3. Jèhófà fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa
Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé yìí lọ́nà tó rẹwà?
Ka Oníwàásù 3:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, kí ni Jèhófà ń fẹ́ fún wa?
4. Jèhófà ṣì máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé
Ka Sáàmù 37:11, 29 àti Àìsáyà 55:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ṣì máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé?
Tí ilé kan bá bà jẹ́, a lè tún un ṣe. Lọ́nà kan náà, àwọn èèyàn ti ba ayé yìí jẹ́, àmọ́ Ọlọ́run máa tún ayé yìí ṣe fún àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀
5. Tá a bá ń sin Jèhófà, ayé wa máa dáa
Tá a bá mọ ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa, ọkàn wa máa balẹ̀. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Àǹfààní wo ni Terumi rí nígbà tó mọ ìdí tá a fi wà láyé?
Ka Oníwàásù 12:13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tá a bá ronú nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, kí ló yẹ ká máa ṣe láti fi hàn pé a moore?
ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí nìdí tá a fi wà láyé?”
Kí lo máa sọ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jèhófà fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa títí láé, láìsí ìṣòro kankan. Tá a bá ń sìn ín tọkàntọkàn, kódà ní báyìí, ayé wa máa dùn, ọkàn wa sì máa balẹ̀.
Kí lo rí kọ́?
Irú ìgbé ayé wo ni Jèhófà fẹ́ kí Ádámù àti Éfà máa gbé?
Báwo la ṣe mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé ò tíì yí pa dà?
Kí la lè ṣe tí ayé wa á fi dáa?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ọgbà Édẹ́nì wà lóòótọ́.
“Ọgbà Édẹ́nì, Ṣé Ó Wà Lóòótọ́ Àbí Àròsọ Ni?” (Ilé Ìṣọ́, January 1, 2011)
Ka ìwé yìí kó o lè rí ìdí tó fi dá wa lójú pé ayé yìí máa wà títí láé.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ pé a lè ṣe tí ayé wa á fi dáa.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ bí ọkùnrin kan tó rò pé òun ti ní gbogbo nǹkan tán ṣe wá rí i pé ohun pàtàkì kan wà tóun ò tíì ní.
a Nínú ẹ̀kọ́ tó kàn, o máa mọ ohun tó fà á tí ayé ò fi tíì rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.
-
-
Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
2. Àwọn wo ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù?
Jésù nìkan kọ́ ló máa dá ṣàkóso. Àwọn èèyàn látinú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè . . . máa ṣàkóso bí ọba lé ayé lórí.” (Ìfihàn 5:9, 10) Àwọn mélòó ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi? Látìgbà tí Jésù ti wá sáyé, àìmọye èèyàn ló ti di Kristẹni. Àmọ́, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) péré lára wọn ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run. (Ka Ìfihàn 14:1-4.) Gbogbo àwọn Kristẹni tó kù láyé sì máa jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run.—Sáàmù 37:29.
-
-
Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe fún AráyéGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe fún Aráyé
Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Láìpẹ́, ó máa tún ayé yìí ṣe. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun rere tá a máa gbádùn nínú Ìjọba Ọlọ́run.
1. Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa mú kí àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo jọba láyé?
Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn burúkú run, ó sì máa fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn. (Ìfihàn 16:14, 16) Tó bá dìgbà yẹn, ohun tó wà ní Sáàmù 37:10 máa ṣẹ láìkù síbì kan. Ó ní: “Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́.” Jésù máa lo Ìjọba Ọlọ́run láti mú kí àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo jọba ní gbogbo ayé.—Ka Àìsáyà 11:4.
2. Báwo ni ayé ṣe máa rí nígbà tí gbogbo èèyàn bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́?
Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, “àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.” (Sáàmù 37:29) Fojú inú wo bí ayé ṣe máa rí nígbà tí gbogbo èèyàn bá jẹ́ olódodo, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn! Àwọn èèyàn ò ní máa ṣàìsàn mọ́, wọ́n á sì wà láàyè títí láé.
3. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe lẹ́yìn tí àwọn èèyàn burúkú bá ti pa run?
Lẹ́yìn tí àwọn èèyàn burúkú bá ti pa run, Jésù máa ṣàkóso ayé fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. Nígbà yẹn, Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa bá a ṣàkóso á sọ gbogbo èèyàn tó wà láyé di pípé. Tí ẹgbẹ̀rún ọdún yẹn bá fi máa parí, ayé á ti di Párádísè, àwọn èèyàn tó jẹ́ aláyọ̀ torí pé wọ́n ń gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu ló sì máa wà ní gbogbo ayé. Lẹ́yìn náà, Jésù máa dá àkóso pa dà fún Jèhófà Bàbá rẹ̀. ‘Orúkọ Jèhófà á wá di mímọ́’ lọ́nà tó ga jù lọ. (Mátíù 6:9, 10) Ó máa wá hàn kedere pé Alákòóso tó dáa ni Jèhófà, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Jèhófà á wá pa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù run, títí kan gbogbo àwọn èèyàn tó ń ta ko Ìjọba Ọlọ́run. (Ìfihàn 20:7-10) Tí Ìjọba Ọlọ́run bá ti tún ayé yìí ṣe, kò tún ní sí ìṣòro kankan mọ́ títí láé!
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo ohun tó mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe gbogbo àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
4. Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí ìjọba èèyàn
“Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Jèhófà máa lo Ìjọba rẹ̀ láti fòpin sí ìyà tí ìjọba èèyàn fi ń jẹ aráyé.
Ka Dáníẹ́lì 2:44 àti 2 Tẹsalóníkà 1:6-8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ni Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ máa ṣe sí ìjọba èèyàn àtàwọn tó ń ti ìjọba èèyàn lẹ́yìn?
Báwo ni ohun tó o mọ̀ nípa Jèhófà àti Jésù ṣe mú kó dá ẹ lójú pé wọ́n máa ṣe ohun tó tọ́ àtohun tó yẹ fún gbogbo èèyàn?
5. Jésù ni Ọba tó yẹ wá
Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó sì máa ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa ṣe aráyé láǹfààní. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè rí bí Jésù ṣe fi hàn pé ó ń wu òun gan-an láti ran àwa èèyàn lọ́wọ́ àti pé ó máa lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe. Èwo lára àwọn ohun rere tó wà nísàlẹ̀ yìí ló ń wù ẹ́ jù? Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun rere náà.
NÍGBÀ TÍ JÉSÙ WÀ LÁYÉ, Ó . . .
LÁTỌ̀RUN, JÉSÙ MÁA . . .
mú kí ìjì líle pa rọ́rọ́.—Máàkù 4:36-41.
mú kí ayé di ibi tó rẹwà, tó sì tura láti gbé—Àìsáyà 35:1, 2.
fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ní oúnjẹ.—Mátíù 14:17-21.
mú kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ wà láyé, ó sì máa kárí gbogbo èèyàn.—Sáàmù 72:16.
mú ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn lára dá.—Lúùkù 18:35-43.
mú kí ara gbogbo èèyàn jí pépé.—Àìsáyà 33:24.
jí àwọn òkú dìde.—Lúùkù 8:49-55.
jí àwọn òkú dìde, àwọn èèyàn ò sì ní máa kú mọ́.—Ìfihàn 21:3, 4.
6. Ìjọba Ọlọ́run máa mú káyé tura gan-an
Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún àwa èèyàn níbẹ̀rẹ̀. Àwọn èèyàn á máa gbé ayé títí láé. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè rí bí Jèhófà ṣe máa lo Ọmọ rẹ̀, Jésù, láti ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn fún àwa èèyàn.
Ka Sáàmù 145:16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ló ṣe rí lára ẹ bó o ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́”?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Táwa èèyàn bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, a lè yanjú àwọn ìṣòro tó wà láyé fúnra wa.”
Àwọn ìṣòro wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa yanjú, àmọ́ tó jẹ́ pé ìjọba èèyàn ò lè yanjú wọn láé?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ fún àwa èèyàn. Ó máa sọ gbogbo ayé di Párádísè, àwọn èèyàn rere nìkan ló máa wà ní gbogbo ayé, wọ́n á sì máa jọ́sìn Jèhófà títí láé.
Kí lo rí kọ́?
Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́?
Kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe gbogbo àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
Èwo lára àwọn ohun rere tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe ló ń wù ẹ́ jù?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Amágẹ́dọ́nì jẹ́.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí Jésù pè ní “ìpọ́njú ńlá.”—Mátíù 24:21.
Wo fídíò yìí kó o lè rí bí àwọn ìdílé ṣe lè máa ronú nípa àwọn ohun rere tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe.
Ka ìtàn tí àkòrí ẹ̀ sọ pé, “Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè Ń Jà Gùdù Lọ́kàn Mi,” kó o lè rí bí ọkùnrin kan tó máa ń bá ìjọba fa wàhálà ṣe rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè tó ń wá.
“Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, January 1, 2012)
-