ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jehofa, Olùṣe Awọn Ohun Àgbàyanu-ńlá
    Ilé-Ìṣọ́nà—1992 | December 15
    • 8. Ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ wo ni a lè ní pẹlu Jehofa, bawo sì ni o ṣe fi iwarere-iṣeun rẹ̀ hàn?

      8 Dafidi ṣe ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ onimọlara jijinlẹ siwaju sii pe: “Nitori iwọ, Óò Jehofa, dára o sì ṣetan lati dariji; ati iṣeun-ifẹ naa si gbogbo awọn wọnni ti ń kè pè ọ́ pọ̀ yanturu. Tẹ́tísílẹ̀, Óò Jehofa, si adura mi; ki o sì fiyesilẹ si ohùn awọn ìpàrọwà mi. Ni ọjọ idaamu mi emi yoo képè ọ́ nitori ti iwọ yoo dá mi lóhùn.” (Orin Dafidi 86:5-7, NW) “Óò Jehofa”—leralera ni ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ ọ̀rọ̀ yii mú wa layọ! Ó jẹ́ ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ kan ti a lè mú dàgbà lemọlemọ nipasẹ adura. Dafidi gbadura ni akoko miiran pe: “Awọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà-èwe mi ati awọn iṣọtẹ mi ni ki iwọ jọwọ maṣe ranti. Gẹgẹ bi inurere rẹ ni ki iwọ funraarẹ ranti mi, nititori iwarere iṣeun rẹ, Óò Jehofa.” (Orin Dafidi 25:7, NW) Jehofa ni ẹ̀dàyà-àpẹẹrẹ iwarere-iṣeun gan-an—ninu pipese irapada Jesu, ninu fifi aanu hàn fun awọn ẹlẹṣẹ ti wọn ronupiwada, ati ninu rírọ̀jò iṣeun-ifẹ sori awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ aduroṣinṣin ati onimọriri.—Orin Dafidi 100:3-5; Malaki 3:10.

      9. Imudaniloju wo ni awọn ẹlẹṣẹ oluronupiwada nilati fi sọ́kàn?

      9 Ó ha yẹ ki a bọkànjẹ́ lori awọn asiṣe ìgbà ti o ti kọja bi? Bi a bá ti ń rìn ni ọ̀nà títọ́ nisinsinyi, a o mú ara wa yá gágá nigba ti a bá ranti imudaniloju aposteli Peteru fun awọn onironupiwada pe “akoko itura” yoo wá lati ọdọ Jehofa. (Iṣe 3:19) Ẹ jẹ ki a sunmọ Jehofa pẹkipẹki ninu adura nipasẹ Olurapada wa, Jesu, ẹni ti ó fi tifẹtifẹ sọ pe: “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹyin ti ń ṣíṣẹ̀ẹ́, ti a sì di ẹrù wúwo lé lori, emi ó sì fi isinmi fun yin. Ẹ gba ajaga mi si ọrùn yin, ki ẹ sì maa kọ́ ẹkọ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkàn ni emi; ẹyin ó sì rí isinmi fun ọkàn yin.” Bi awọn Ẹlẹ́rìí aduroṣinṣin ti ń gbadura si Jehofa lonii ni orukọ ṣiṣeyebiye ti Jesu, wọ́n ń rí itura nitootọ.—Matteu 11:28, 29; Johannu 15:16.

  • Jehofa, Olùṣe Awọn Ohun Àgbàyanu-ńlá
    Ilé-Ìṣọ́nà—1992 | December 15
    • 13. Bawo ni awọn òbí ati awọn ọmọ wọn ṣe lè janfaani lati inu iwarere-iṣeun Jehofa?

      13 Laiṣiyemeji, Dafidi tẹ aini naa lati gbarale iwarere-iṣeun Jehofa mọ́ ọmọkunrin rẹ̀ Solomoni lọ́kàn. Nipa bayii, Solomoni lè fun ọmọkunrin tirẹ̀ fúnraarẹ̀ nitọọni pe: “Fi gbogbo àyà rẹ gbẹkẹle Oluwa; má sì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ. Mọ̀ ọ́n ni gbogbo ọ̀nà rẹ: oun ó sì maa tọ́ ipa-ọna rẹ. Maṣe ọlọgbọn ni ojú ara rẹ; bẹru Oluwa, ki o sì kuro ninu ibi.” (Owe 3:5-7) Awọn òbí lonii nilati kọ́ awọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ wọn bakan naa ni bi wọn yoo ti figbẹkẹle gbadura si Jehofa ati ọ̀nà ti wọn yoo gbà koju awọn ìfipákọluni ninu ayé ọlọ́kàn-àyà yíyigbì yii—iru bii ikimọlẹ ojúgbà ni ile-ẹkọ ati awọn ìdẹwò lati dẹ́ṣẹ̀ iwapalapala. Fifi awọn ilana Bibeli silo pẹlu awọn ọmọ rẹ lojoojumọ lè tẹ ifẹ gidi fun Jehofa ati igbarale e taduratadura mọ́ awọn ọmọ rẹ lọ́kàn.—Deuteronomi 6:4-9; 11:18, 19.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́