Igi Tí Ń kọrin
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KENYA
IGI kan wà tó máa ń kọrin ní àwọn ijù Áfíríkà tó lọ salalu. Ẹ̀yà igi bọn-ọ̀n-ní ni igi ọ̀hún, orúkọ rẹ̀ sì ni igi òfé. Torúkọ yìí ti jẹ́ o? Ó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé nígbà tí ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ bá ń bì lu àwọn ọ̀jẹ̀lẹ́ ẹ̀ka igi náà, ṣe ló máa ń dà bí ẹni pé igi náà ń súfèé.
Ìró títunilára, tí ń dún ròkèrodò ló máa ń jáde nígbà tí ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ bá ń fẹ́ àwọn ẹ̀ka igi náà tó gùn tó sì rí tẹ́ẹ́rẹ́. Ní àfikún sí orin aládùn tí àwọn ẹ̀ka náà ń kọ, àwọn ihò tó wà lára àwọn kókó ara igi náà máa ń súfèé tó ń dún bí ìgbà téèyàn bá ń fẹ́ afẹ́fẹ́ sẹ́nu òfìfo ìgò. Àwọn èèrà ló ń ṣe “ohun èlò orin” wọ̀nyí, torí àwọn la gbọ́ pé wọ́n ń gbẹ́ inú àwọn kókó ara igi náà, láti fi inú wọn kọ́ ilé olóbìrípo wọn, àwọn èèrà wọ̀nyí á sì gbẹ́ ibi àbáwọlé tín-tìn-tín àti àwọn ihò àbájáde sára wọn. Torí pé àwọn kókó àti ihò náà tóbi jura lọ, wọn kì í dún bákan náà. Òfé wọ̀nyí fi kún jíjẹ́ tí igi òfé jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ó sì tún fi kún ẹwà rẹ̀.
Igi yìí rán wa létí ọ̀rọ̀ onísáàmù náà tó sọ lọ́nà àpèjúwe pé: “Kí gbogbo igi igbó fi ìdùnnú bú jáde [nínú orin] níwájú Jèhófà.” (Sáàmù 96:12, 13) Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ bá ń fẹ́ àwọn ẹ̀ka àti kókó wọnnì tí ń dún bíi fèrè, ó máa ń mú ìró títunilára jáde, àní orin Áfíríkà tí ń wọni lákínyẹmí ara.