ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́—2006 | January 1
    • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

      Ìwé Sáàmù 102:26 sọ pé ayé àti ọ̀run “yóò ṣègbé.” Ṣé ohun tí gbólóhùn yìí túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run yóò pa ilẹ̀ Ayé run?

      Nínú àdúrà tí ẹni tó kọ sáàmù yìí gbà sí Jèhófà, ó sọ pé: “Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni ìwọ ti fi àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Àwọn tìkára wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ tìkára rẹ yóò máa wà nìṣó; àti gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, gbogbo wọn yóò gbó. Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, ìwọ yóò pààrọ̀ wọn, wọn yóò sì lo ìgbà wọn parí.” (Sáàmù 102:25, 26) Àwọn ọ̀rọ̀ tó yí àwọn ẹsẹ yìí ká fi hàn pé kì í ṣe pípa ayé àti ọ̀run rẹ́ làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí kò ṣe wíwà tí Ọlọ́run wà títí ayérayé. Àwọn ọ̀rọ̀ tó yí àwọn ẹsẹ náà ká tún jẹ́ ká mọ ìdí tí kókó pàtàkì yìí fi jẹ́ ìtùnú fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́—2006 | January 1
    • Kódà, a ò lè fi wíwà tí ilẹ̀ ayé àti ọ̀run ti wà tipẹ́tipẹ́ wé bí Jèhófà ṣe wà títí ayérayé. Onísáàmù náà wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àwọn [ayé àti ọ̀run] tìkára wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ tìkára rẹ yóò máa wà nìṣó.” (Sáàmù 102:26) Ayé àti ọ̀run lè ṣègbé. Òótọ́ ni pé lápá ibòmíràn nínú Ìwé Mímọ́, Jèhófà sọ pé ayé àtọ̀run yóò wà títí láé. (Sáàmù 119:90; Oníwàásù 1:4) Àmọ́ wọ́n ṣeé pa run, tó bá jẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ẹ nìyẹn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò lè kú. Nítorí pé Ọlọ́run ń mójú tó àwọn nǹkan tó dá ló jẹ́ kí wọ́n “dúró títí láé.” (Sáàmù 148:6) Bí Jèhófà kò bá sọ àwọn ohun tó dá dọ̀tun mọ́, “gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, [ni] gbogbo wọn yóò gbó.” (Sáàmù 102:26) Bí èèyàn ṣe máa ń wà nìṣó lẹ́yìn tí aṣọ rẹ̀ bá ti gbó, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yóò máa wà nìṣó nígbà táwọn ohun tó dá kò bá sí mọ́, tó bá jẹ́ bó ṣe fẹ́ kó rí nìyẹn. Àmọ́, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn jẹ́ ká mọ̀ pé ìyẹn kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé àṣẹ Jèhófà ni pé kí ayé àti ọ̀run máa wà lọ títí láé.—Sáàmù 104:5.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́