-
Mímọrírì Ìdí Tá A Fi Ń Báni WíIlé Ìṣọ́—2003 | October 1
-
-
Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbáwí yàtọ̀. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba kọ̀wé pé: “Ìwọ ọmọ mi, má kọ ìbáwí Jèhófà.” (Òwe 3:11) Ọ̀rọ̀ yìí ò tọ́ka sí ìbáwí lásán, bí kò ṣe “ìbáwí Jèhófà,” ìyẹn ìbáwí tá a gbé karí ìlànà gíga látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ ló ń ṣeni láǹfààní nípa tẹ̀mí—kódà á nílò rẹ̀ gan-an. Ní òdìkejì èyí, ìbáwí tá a gbé karí èrò ènìyàn tó tako ìlànà gíga látọ̀dọ̀ Jèhófà sábà máa ń ní àṣejù nínú ó sì máa ń pani lára. Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fojú tó dára wo ìbáwí.
Kí nìdí tá a fi rọ̀ wá láti gba ìbáwí tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà? Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe ìbáwí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń fi ìfẹ́ hàn sí ẹ̀dá ènìyàn. Ìdí nìyẹn tí Sólómọ́nì fi ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, àní gẹ́gẹ́ bí baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.”—Òwe 3:12.
Kí Ni Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ìbáwí àti Ìfìyàjẹni?
Ìbáwí pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ọ́ nínú Bíbélì—ó wà fún amọ̀nà, ìtọ́ni, ìdánilẹ́kọ̀ọ́, ìbáwí àfitọ́nisọ́nà, ìtọ́sọ́nà, kódà o tún wà fún ìfìyàjẹni pàápàá. Àmọ́, ní gbogbo ọ̀nà, ìfẹ́ ló ń mú kí Jèhófà báni wí, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ káwọn tó bá fara mọ́ ìbáwí rẹ̀ lè ṣe ara wọn láǹfààní. Kì í ṣe nítorí àtifi ìyà jẹni nìkan ni Jèhófà ṣe ń báni wí.
-
-
Mímọrírì Ìdí Tá A Fi Ń Báni WíIlé Ìṣọ́—2003 | October 1
-
-
Ọ̀nà wo ni àwọn ìjìyà wọ̀nyí gbà fi “àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀”? Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà, ó tọ́ka sí àkókò tá a wà yìí gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi mú “ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere.” Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Àwọn wọ̀nyí gan-an yóò fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.” (2 Tẹsalóníkà 1:8, 9) Ó hàn gbangba pé irú ìyà bẹ́ẹ̀ kò wà fún kíkọ́ àwọn èèyàn náà lẹ́kọ̀ọ́ tàbí fún yíyọ́ wọn mọ́. Àmọ́ ṣá o, nígbà tí Jèhófà bá rọ àwọn olùjọsìn rẹ̀ láti tẹ́wọ́ gba ìbáwí, kì í ṣe ìyà tó máa fi jẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé Bíbélì kò ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jẹ́ pé kìkì ìyà ló máa ń fi jẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sábà máa ń sọ nípa rẹ̀ ni pé ó jẹ́ olùkọ́ tó nífẹ̀ẹ́ àti ẹni tó ń fi sùúrù kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. (Jóòbù 36:22; Sáàmù 71:17; Aísáyà 54:13) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìbáwí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tá a lò láti fi tọ́ni sọ́nà máa ń fìgbà gbogbo ní ìfẹ́ àti sùúrù nínú. Tá a bá lóye ìdí tá a fi ń bá wa wí, kò lè ṣòro rárá fún àwọn Kristẹni láti fi ẹ̀mí rere gba ìbáwí kí àwọn náà sì máa fi ẹ̀mí rere báni wí.
-