ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • 3. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ṣe?

      Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, “ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.” (Òwe 3:32) Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, kí wọ́n sì máa sá fún ìwà burúkú. Àwọn kan rò pé agbára àwọn ò lè gbé e láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Àmọ́, Jèhófà máa ń gba tiwa rò. Ó máa ń tẹ́wọ́ gba gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tó sì ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.​—Sáàmù 147:11; Ìṣe 10:34, 35.

  • Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo

      Gbogbo wa la mọyì pé káwọn ọ̀rẹ́ wa jẹ́ olóòótọ́. Bákan náà, tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́, kò rọrùn rárá láti jẹ́ olóòótọ́, torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ aláìṣòótọ́ láyé tá a wà yìí. Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo?

      1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká jẹ́ olóòótọ́?

      Tá a bá ń ṣòótọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì bọ̀wọ̀ fún un. Rò ó wò ná: Jèhófà mọ gbogbo ohun tá à ń rò àtohun tá à ń ṣe. (Hébérù 4:13) Ó mọ àwọn ìgbà tá a bá jẹ́ olóòótọ́, ó sì mọyì rẹ̀ gan-an. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Jèhófà kórìíra oníbékebèke, ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ Rẹ̀ tímọ́tímọ́.”​—Òwe 3:32.

      2. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́?

      Jèhófà fẹ́ ká ‘máa bá ara wa sọ òtítọ́.’ (Sekaráyà 8:16, 17) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Bóyá àwọn ìdílé wa là ń bá sọ̀rọ̀, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, kò yẹ ká máa parọ́ tàbí ká fún wọn láwọn ìsọfúnni tó ń ṣini lọ́nà. Àwọn olóòótọ́ kì í ja àwọn míì lólè tàbí kí wọ́n lù wọ́n ní jìbìtì. (Ka Òwe 24:28 àti Éfésù 4:28.) Bákan náà, wọ́n máa ń san àwọn owó tó yẹ kí wọ́n san fún ìjọba. (Róòmù 13:5-7) Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, tá a sì tún ń jẹ́ olóòótọ́ láwọn ọ̀nà míì, ńṣe là ń fi hàn pé a “jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”​—Hébérù 13:18.

      3. Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá jẹ́ olóòótọ́?

      Táwọn èèyàn bá mọ̀ pé olóòótọ́ ni wá, wọ́n máa fọkàn tán wa. Ọkàn àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ á balẹ̀, a sì máa dà bí ọmọ ìyá. Àwa náà á sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Bákan náà, tá a bá jẹ́ olóòótọ́, ńṣe là ń “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́,” èyí sì máa jẹ́ káwọn míì dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn tòótọ́.​—Títù 2:10.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká wo ìdí tí Jèhófà fi fẹ́ kó o jẹ́ olóòótọ́ àti àǹfààní tí wàá rí tó o bá jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tó ò ń ṣe.

      4. Inú Jèhófà máa ń dùn sí àwọn olóòótọ́

      Ka Sáàmù 44:21 àti Málákì 3:16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu kẹ́nì kan rò pé òun lè fi òótọ́ pa mọ́ fún Ọlọ́run?

      • Báwo lo ṣe rò pé ó máa ń rí lára Jèhófà tá a bá ń sọ òótọ́, bí kò bá tiẹ̀ rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀?

      Ọmọbìnrin kan ń bá bàbá ẹ̀ sọ̀rọ̀. Bàbá ẹ̀ wá kúnlẹ̀ kó lè bá a dọ́gba. Ohun mímu ẹlẹ́rìndòdò dà sílẹ̀ látinú ife tó wà lórí tábìlì.

      Inú àwọn òbí máa ń dùn táwọn ọmọ wọn bá jẹ́ olóòótọ́. Bákan náà, tá a bá jẹ́ olóòótọ́, inú Jèhófà máa dùn sí wa

      5. Jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo

      Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé kò bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo nǹkan. Àmọ́, jẹ́ ká wo ìdí tó fi yẹ ká máa jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo. Wo FÍDÍÒ yìí.

      FÍDIÒ: Kí Lá Jẹ́ Kó O Láyọ̀?​—Ẹ̀rí Ọkàn Tó Mọ́ (2:32)

      Àwòrán apá kan látinú fídíò ‘Kí Lá Jẹ́ Kó O Láyọ̀?​—Ẹ̀rí Ọkàn Tó Mọ́.’ Lẹ́yìn tí Ben sọ fún ọ̀gá ẹ̀ pé òun ti ṣe àṣìṣe ńlá kan, ọ̀gá ẹ̀ bọ̀ ọ́ lọ́wọ́.

      Ka Hébérù 13:18, lẹ́yìn náà kó o sọ bá a ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ . . .

      • nínú ìdílé wa.

      • ní ibiṣẹ́ tàbí iléèwé.

      • nínú àwọn nǹkan míì.

      6. A máa jàǹfààní púpọ̀ tá a bá jẹ́ olóòótọ́

      Nígbà míì, ó lè dà bíi pé òótọ́ tá a sọ ló kó wa sí wàhálà. Àmọ́, nígbà tó bá yá àwa náà á rí i pé kò sóhun tó dáa tó kéèyàn jẹ́ olóòótọ́. Ka Sáàmù 34:12-16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo?

      A.Ọkọ àtìyàwó kan jọ ń sọ̀rọ̀, wọ́n sì ń mu kọfí. B. Mẹkáníìkì kan wà lẹ́nu iṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń tún mọ́tò ṣe, ọ̀gá rẹ̀ sì ń gbóríyìn fún un. C. Ọkùnrin kan wà nínú mọ́tò ẹ̀, ó sì ń fi ìwé ọkọ̀ han ọlọ́pàá kan.
      1. A. Táwọn tọkọtaya bá jẹ́ olóòótọ́, wọ́n á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn

      2. B. Táwọn òṣìṣẹ́ bá jẹ́ olóòótọ́, ọ̀gá wọn á fọkàn tán wọn

      3. D. Táwọn aráàlú bá jẹ́ olóòótọ́, wọ́n á lórúkọ rere lọ́dọ̀ ìjọba

      ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò sóhun tó burú téèyàn bá ń pa irọ́ kéékèèké.”

      • Kí nìdí tó o fi gbà pé gbogbo irọ́ ni Jèhófà kórìíra?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn.

      Kí lo rí kọ́?

      • Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́?

      • Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu kẹ́nì kan ronú pé òun lè fi òótọ́ pa mọ́ fún Jèhófà?

      • Kí nìdí tó fi wù ẹ́ láti máa jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti jẹ́ olóòótọ́?

      Jẹ́ Olóòótọ́ (1:44)

      Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń mú ìlérí wa ṣẹ?

      Mú Ohun Tó O Ṣèlérí Ṣẹ, Kó O sì Gba Ìbùkún (9:09)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ̀ bóyá ó yẹ kó o máa sanwó orí, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ò fàwọn owó náà ṣohun tó yẹ kí wọ́n fi ṣe.

      “Ṣé Dandan Ni Kéèyàn Máa San Owó Orí?” (Ilé Ìṣọ́, September 1, 2011)

      Kí ló mú kí ọkùnrin oníjìbìtì kan yíwà pa dà tó sì di olóòótọ́?

      “Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Pé Jèhófà Jẹ́ Aláàánú Ó sì Ń Dárí Jini” (Ilé Ìṣọ́, May 1, 2015)

  • Fọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • 2. Báwo ni ìpinnu tó o bá ṣe nípa àwọn tó ò ń bá ṣọ̀rẹ́ ṣe kan Ọlọ́run?

      Jèhófà kì í mú ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti rí lọ́rẹ̀ẹ́. “Àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ Rẹ̀ tímọ́tímọ́.” (Òwe 3:32) Ṣé inú Jèhófà máa dùn tó bá jẹ́ pé àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ la mú lọ́rẹ̀ẹ́? Ó dájú pé inú ẹ̀ ò ní dùn! (Ka Jémíìsì 4:4.) Àmọ́, inú Jèhófà máa dùn sí wa, á sì sún mọ́ wa tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti sún mọ́ ọn, tá a mú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, tá a sì yẹra fún àwọn tí ò tẹ̀ lé òfin rẹ̀.​—Sáàmù 15:1-4.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́