“Aya Ìgbà Èwe Rẹ”
“PANṢAGA fẹrẹẹ dabi iṣẹlẹ ojoojumọ.” Bẹẹ ni ọpọlọpọ awọn ìjìmì sọ, gẹgẹ bi Los Angeles Times ti wi. Ǹjẹ́ iru gbolohun-ọrọ bẹẹ ha yà ọ́ lẹnu bi? Sibẹ, oniṣegun ọpọlọ Frank Pittman fojudiwọn rẹ̀ pe nǹkan bii ipin 50 ninu ọgọrun-un awọn ọkọ ati lati ipin 30 ninu ọgọrun-un si ipin 40 ninu ọgọrun-un ninu awọn aya ni wọn ti jẹ́ alaiṣootọ. Bi iyẹn bá jẹ́ otitọ, ó fẹrẹẹ tó idaji ninu gbogbo awọn ti o ti gbeyawo ti wọn dẹṣẹ panṣaga!
Iyẹn ha tumọsi pe iwapalapala tọna bi? Ki a má ri! Itankalẹ iwa aiṣootọ kò mú un tọna—gẹgẹ bi ilọsoke iwa-ọdaran opopona kò ti mú un tọna lati fipá ja ẹnikan lólè. Iwapalapala ń panilara. Fun apẹẹrẹ, lonii araye ni ajakalẹ awọn àrùn tí a ń ta látaré nipasẹ ibalopọ takọtabo ti ràn gbogbo eyi ti a lè fi tirọruntirọrun ṣekawọ rẹ̀ bi awọn eniyan bá gbe igbesi-aye oniwarere. Àrùn apani naa AIDS kì bá tí ríbi dásẹ̀tẹlẹ̀ bi awọn eniyan kò bá ti jẹ́ aláìníjàánu ninu igbesi-aye ibalopọ takọtabo wọn.
Yatọ si iyẹn, àní awọn ti wọn jẹ́ gbajumọ ati “ọ̀làjú” julọ nimọlara irora gigadabu nigba ti ẹnikeji wọn bá jẹ́ alaiṣotitọ. Ìṣe iwa aiṣootọ kan lè ṣokunfa ọgbẹ́ ti yoo gba ilaji akoko igbesi-aye lati wosan.
Bi o ti wu ki o ri, kókó ti o ṣe pataki julọ ni pe fifi ọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ẹ̀jẹ́ igbeyawo jẹ aibọwọ wiwuwo fun Ọlọrun, niwọn bi o ti jẹ pe oun ni Olupilẹṣẹ igbeyawo. Bibeli wi pe: “Ki igbeyawo ki o ni ọlá laaarin gbogbo eniyan.” A tun kilọ fun wa pe: “Awọn agbere ati awọn panṣaga ni Ọlọrun yoo da lẹjọ.”—Heberu 13:4.
Lori eyi, awọn eniyan ọlọgbọn kiyesi awọn ọ̀rọ̀ onimiisi naa pe: “Yọ̀ tiwọ ti aya igba ewe rẹ.” (Owe 5:18) Wọn wá itẹlọrun ati ayọ pẹlu alabaaṣegbeyawo wọn. Ni ṣiṣe bẹẹ wọn daabobo ilera ti ara ati ti ero-imọlara wọn, ati eyi ti o ṣe pataki ju, wọn mú ọlá wá fun atobilọla Olupilẹṣẹ igbeyawo naa, Jehofa Ọlọrun.