ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”
    Ilé Ìṣọ́—2000 | November 15
    • Ọba náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ràn bíi ti bàbá pé: “Ọmọ mi, pa àwọn àsọjáde mi mọ́, kí o sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ. Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì máa bá a lọ ní wíwà láàyè, àti òfin mi bí ọmọlójú rẹ.”—Òwe 7:1, 2.

  • “Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”
    Ilé Ìṣọ́—2000 | November 15
    • Ẹ̀kọ́ àwọn òbí tún lè ní àwọn ìlànà mìíràn nínú—ìyẹn ni àwọn òfin ìdílé. Àǹfààní àwọn mẹ́ńbà ìdílé lèyí wà fún. Lóòótọ́, àwọn òfin náà lè yàtọ̀ látinú ìdílé kan sí òmíràn, ó sinmi lórí àwọn ohun tó jẹ́ àìní wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, iṣẹ́ àwọn òbí ni láti pinnu ohun tó dára jù lọ fún ìdílé wọn. Àwọn òfin tí wọ́n bá sì ṣe náà jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n fi ń fi ojúlówó ìfẹ́ wọn àti àníyàn wọn hàn. Ìmọ̀ràn tí a gba àwọn ọ̀dọ́ ni pé kí wọ́n pa àwọn òfin wọ̀nyí mọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tí àwọn òbí wọn ń fún wọn. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìdí wà fún pípa àwọn ìtọ́ni yẹn mọ́ “bí ọmọlójú rẹ”—kóo tọ́jú wọn gidigidi. Ọ̀nà tóo lè gbà yẹra fún àbájáde tó ń ṣekú pani tí ṣíṣàìka àwọn ìlànà Jèhófà sí máa ń mú wá nìyẹn o, tí wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ “máa bá a lọ ní wíwà láàyè.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́