ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìkùgbù Máa Ń fa Àbùkù
    Ilé Ìṣọ́—2000 | August 1
    • Ìkùgbù Máa Ń fa Àbùkù

      “Ìkùgbù ha ti dé bí? Nígbà náà, àbùkù yóò dé; ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”—ÒWE 11:2.

      1, 2. Kí ni ìkùgbù, báwo ló sì ṣe mú kí àwọn kan kàgbákò?

      ONÍLARA ọmọ Léfì kan kó àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyànkéèyàn kan sòdí láti bá àwọn aláṣẹ tí Jèhófà yàn sípò jà. Ọmọ ọba kan tó ń kánjú àtidi ọba gbé ọ̀nà àrékérekè kan kalẹ̀ láti gbapò ọba lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ọba kan tí kò ní sùúrù kọ̀ láti tẹ̀ lé ìtọ́ni ṣíṣe kedere tí wòlíì Ọlọ́run fún un. Ohun tó mú kí ìwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí bára mu ni: ìkùgbù.

      2 Ìkùgbù jẹ́ ohun kan tó máa ń dìde látinú ọkàn-àyà, tó sì jẹ́ ewu ńlá tó dojú kọ gbogbo wa. (Sáàmù 19:13) Oníkùgbù ènìyàn máa ń kù gìrì ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe láìsí pé a fún un láṣẹ àtiṣe é. Àgbákò sì ni èyí máa ń já sí lọ́pọ̀ ìgbà. Àní sẹ́, ìkùgbù ti bayé ọba jẹ́, ó sì ti bi ilẹ̀ ọba ṣubú. (Jeremáyà 50:29, 31, 32; Dáníẹ́lì 5:20) Ó tilẹ̀ ti dẹkùn mú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan, ó sì ba tiwọn jẹ́ pátápátá.

      3. Báwo la ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ewu tó wà nínú ìkùgbù?

      3 Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ìkùgbù ha ti dé bí? Nígbà náà, àbùkù yóò dé; ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Bíbélì fún wa láwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé òótọ́ ni òwe yìí. Ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn kan lára ìwọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ewu tó wà nínú kíkọjá àyè ẹni. Nítorí ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò bí ìlara, lílépa ipò ọlá, àti àìnísùúrù ṣe mú kí àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a mẹ́nu kàn níṣàájú fi ìkùgbù hùwà, tó wá yọrí sí àbùkù fún wọn.

      Kórà—Onílara Tó Ṣọ̀tẹ̀

      4. (a) Ta ni Kórà, kí sì ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbígbàfiyèsí tó dájú pé ó wà lára àwọn tó kópa nínú wọn? (b) Ọ̀tẹ̀ ńlá wo ni Kórà dá sílẹ̀ ní òpin ìgbésí ayé rẹ̀?

      4 Ọmọkùnrin Kóhátì, ọmọ Léfì ni Kórà, ó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò baba Mósè òun Áárónì. Ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ló fi jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Kórà ní àǹfààní wíwà lára àwọn táa fi iṣẹ́ ìyanu gbà là ní Òkun Pupa, ó sì ṣeé ṣe kó wà lára àwọn tó mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ lòdì sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jọ́sìn ère ọmọ màlúù ní Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 32:26) Àmọ́, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Kórà wá di baba ìsàlẹ̀ fún Dátánì, Ábírámù, àti Ónì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Rúbẹ́nì pẹ̀lú àwọn àádọ́ta-lérúgba [250] ọkùnrin nínú àwọn ìjòyè ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n dìde ọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì.a Wọ́n sọ fún Mósè àti Áárónì pé: “Ó tó gẹ́ẹ́ yín, nítorí pé gbogbo àpéjọ ni ó jẹ́ mímọ́ ní àtòkèdélẹ̀ wọn, Jèhófà sì wà ní àárín wọn. Kí wá ni ìdí tí ẹ fi gbé ara yín sókè lórí ìjọ Jèhófà?”—Númérì 16:1-3.

      5, 6. (a) Kí ló fà á tí Kórà fi ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì? (b) Èé ṣe táa fi lè sọ pé ó ṣeé ṣe kí Kórà fojú tẹ́ńbẹ́lú ipò tirẹ̀ nínú ìṣètò Ọlọ́run?

      5 Èé ṣe tí Kórà fi ṣọ̀tẹ̀, lẹ́yìn tó ti jẹ́ olóòótọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún? Ó dájú pé Mósè kò fi ipò aṣíwájú ni Ísírẹ́lì lára, nítorí pé ó “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Númérì 12:3) Àmọ́, ó dà bí ẹni pé Kórà ṣe ìlara Mósè àti Áárónì, ó sì kórìíra bí wọ́n ṣe yọrí ọlá, èyí ló mú kí ó sọ̀rọ̀ lọ́nà òdì pé ṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń fi ìmọtara-ẹni-nìkan fẹlá lé ìjọ lórí.—Sáàmù 106:16.

      6 Apá kan lára ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣòro Kórà ni pé kò mọyì àǹfààní tí òun ní nínú ètò Ọlọ́run. Lóòótọ́, àwọn ọmọkùnrin Kóhátì, ọmọ Léfì kì í ṣe àlùfáà, ṣùgbọ́n olùkọ́ni ní Òfin Ọlọ́run ni wọ́n. Àwọn ni wọ́n sì máa ń gbé àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ àti àwọn ohun èlò tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kó wọn láti ibì kan lọ sí ibòmíràn. Ìyẹn kì í sì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá, nítorí pé kìkì àwọn tí wọ́n mọ́ ní ti ìsìn àti ní ti ìwà rere nìkan ló lè gbé àwọn ohun èlò mímọ́ wọ̀nyí. (Aísáyà 52:11) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Mósè ko Kórà lójú, ohun tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ni pé, Ṣé o rò pé iṣẹ́ tìrẹ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ni, tí o tún fi ní láti gba iṣẹ́ àlùfáà síkàáwọ́? (Númérì 16:9, 10) Kórà kùnà láti rí i pé fífi òtítọ́ sin Jèhófà ní ìbámu pẹ̀lú ìṣètò rẹ̀ ni ọlá tó ga jù lọ—kì í ṣe wíwà ní ipò pàtàkì kan.—Sáàmù 84:10.

      7. (a) Báwo ni Mósè ṣe pe Kórà àti àwọn ọkùnrin tó kó jọ níjà? (b) Báwo la ṣe mú ìṣọ̀tẹ̀ Kórà wá sí òpin oníjàǹbá?

      7 Mósè ké sí Kórà àti gbogbo àwọn tó jẹ́ tirẹ̀ láti pésẹ̀ sí àgọ́ ìpàdé ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí wọ́n sì mú ìkóná àti tùràrí wá. Kórà àtàwọn èèyàn rẹ̀ kò lẹ́tọ̀ọ́ láti sun tùràrí, nítorí pé wọn kì í ṣe àlùfáà. Bí wọ́n bá wá lọ mú ìkóná àti tùràrí wá, èyí yóò fi hàn ní kedere pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣì ń rò pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti ṣe iṣẹ́ àlùfáà—kódà lẹ́yìn tí wọ́n ti fi gbogbo òru gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò. Nígbà tí wọ́n kó ara wọn dé ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jèhófà fi ìbínú rẹ̀ hàn sí wọn lọ́nà tó tọ́. Ní ti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, “ilẹ̀ la ẹnu ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé wọn mì.” Àwọn tó kù, títí kan Kórà, ni iná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run jó run. (Diutarónómì 11:6; Númérì 16:16-35; 26:10) Ìkùgbù Kórà ló fa àbùkù tó ju àbùkù lọ yìí—ìyẹn ìbínú Ọlọ́run!

      Dènà “Ìtẹ̀sí Láti Ṣe Ìlara”

      8. Báwo ni “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara” ṣe lè fara hàn láàárín àwọn Kristẹni?

      8 Ìkìlọ̀ ni ìtàn Kórà jẹ́ fún wa. Níwọ̀n bí “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara” ti wà nínú ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, ó lè fi ara rẹ̀ hàn nínú ìjọ Kristẹni pàápàá. (Jákọ́bù 4:5) Fún àpẹẹrẹ, a lè jẹ́ ẹni tí ọ̀rọ̀ ipò ká lára. Bíi ti Kórà, a lè máa ṣe ìlara àwọn tó láwọn àǹfààní tó ń wù wá. A sì tún lè dà bíi Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nì, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dìótíréfè. Ẹni tó ń bẹnu àtẹ́ lu ọlá àṣẹ táwọn àpọ́sítélì ní, bóyá nítorí pé ó fẹ́ kí ó wà níkàáwọ́ òun. Àní, Jòhánù kọ̀wé pé Dìótíréfè “ń fẹ́ láti gba ipò àkọ́kọ́.”—3 Jòhánù 9.

      9. (a) Irú ẹ̀mí wo la ò gbọ́dọ̀ ní sí àwọn ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ? (b) Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ipò wa nínú ètò Ọlọ́run?

      9 Láìsí àní-àní, kò sí ohun tó burú nínú kí Kristẹni ọkùnrin kan máa nàgà fún àwọn àǹfààní ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Pọ́ọ̀lù pàápàá sọ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Tímótì 3:1) Àmọ́ ṣá o, a ò gbọ́dọ̀ fojú wo àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ bí àmì àṣeyọrí kan, bí ẹni pé bí ọwọ́ wa bá ti lè tẹ̀ ẹ́ báyìí, a ti gun ọ̀kan já nínú àwọn àtẹ̀gùn tó wà fún ìlọsíwájú nìyẹn. Rántí ohun tí Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín, ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.” (Mátíù 20:26, 27) Ní kedere, yóò jẹ́ ohun tó lòdì láti ṣe ìlara àwọn tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ tó pọ̀, bí ẹni pé “ipò” táa wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run ló ń díwọ̀n bí a ṣe níye lórí tó lójú rẹ̀. Jésù sọ pé: “Ará ni gbogbo yín.” (Mátíù 23:8) Bẹ́ẹ̀ ni o, yálà akéde ni wá tàbí aṣáájú ọ̀nà, yálà a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi ni tàbí a ti pẹ́ lẹ́nu pípa ìwà títọ́ mọ́—gbogbo àwọn tó ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà ló ní ipò tó jọjú nínú ètò rẹ̀. (Lúùkù 10:27; 12:6, 7; Gálátíà 3:28; Hébérù 6:10) Ká sòótọ́, ìbùkún ńlá ló jẹ́ láti máa ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí wọ́n ń tiraka láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé: “Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—1 Pétérù 5:5.

      Ábúsálómù—Ajìfà Tó Ń Lépa Ipò Ọlá

      10. Ta ni Ábúsálómù, báwo ló sì ṣe gbìyànjú àtifa ojú àwọn tó ń wá sọ́dọ̀ ọba fún ìdájọ́ mọ́ra?

      10 Ìtàn ìgbésí ayé Ábúsálómù, ọmọkùnrin tí Dáfídì Ọba bí ṣèkẹta, jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn tó ń lépa ipò ọlá. Ajìfà yìí ta gbogbo ọgbọ́n láti fa ojú àwọn tó ń wá sọ́dọ̀ ọba fún ìdájọ́ mọ́ra. Ó kọ́kọ́ dọ́gbọ́n sọ pé Dáfídì kò bìkítà nípa àwọn ìṣòro wọn. Ìgbà tó yá kò tiẹ̀ wá dọ́gbọ́n mọ́, ṣe ló kúkú sọ ohun tó fẹ́ ṣe jáde ní pàtó. Ábúsálómù wá sọ bí ẹni ń kọrin pé: “Ì bá ṣe pé a yàn mí ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí, pé kí olúkúlùkù ènìyàn tí ó bá ní ẹjọ́ tàbí ìdájọ́ lè tọ̀ mí wá! Nígbà náà, èmi ì bá ṣe ìdájọ́ òdodo fún un dájúdájú.” Ábúsálómù ò tiẹ̀ fi àwọn ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀ wọ̀nyí mọ síbì kan. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá sún mọ́ tòsí láti tẹrí ba fún un, òun a na ọwọ́ rẹ̀, a sì rá a mú, a sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Ábúsálómù sì ń ṣe irú nǹkan báyìí sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó bá wọlé tọ ọba wá fún ìdájọ́.” Kí wá ni àbájáde rẹ̀? “Ábúsálómù sì ń jí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ.”—2 Sámúẹ́lì 15:1-6.

      11. Báwo ni Ábúsálómù ṣe gbìyànjú àtigba ìtẹ́ Dáfídì lọ́wọ́ rẹ̀?

      11 Ábúsálómù pinnu láti fi tipátipá gba ipò ọba lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ọdún márùn-ún ṣáájú àkókò yẹn ló sọ pé kí wọ́n pa Ámínónì, àrẹ̀mọkùnrin Dáfídì, tó sì dà bí ẹni pé ó ṣe bẹ́ẹ̀ láti gbẹ̀san ipá tíyẹn fi bá Támárì, àbúrò Ábúsálómù, lò pọ̀. (2 Sámúẹ́lì 13:28, 29) Àmọ́ o, ó lè jẹ́ ọ̀nà bí Ábúsálómù ṣe máa dórí ìtẹ́ ló ń wá nígbà yẹn, kó sì ti rò pé pípa Ámínónì ló máa jẹ́ kí nǹkan rọrùn, tí kò fi ní sẹ́ni tó máa bá òun dupò.b Ká má fọ̀rọ̀ gùn, nígbà tí ọjọ́ pé, Ábúsálómù gbé ìgbésẹ̀ tó fẹ́ gbé. Ó polongo ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà.—2 Sámúẹ́lì 15:10.

      12. Ṣàlàyé bí ìkùgbù ṣe fa àbùkù fún Ábúsálómù.

      12 Ábúsálómù kẹ́sẹ járí fúngbà díẹ̀, nítorí pé “tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun náà sì túbọ̀ ń le sí i, àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú Ábúsálómù sì ń pọ̀ sí i níye.” Nígbà tó yá, ó di dandan kí Dáfídì Ọba sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 15:12-17) Àmọ́, kò pẹ́ tí gbogbo làlàkokofẹ̀fẹ̀ Ábúsálómù fi dópin, nígbà tí Jóábù pa á, tó gbé e sọ sínú kòtò ńlá kan, tó sì kó òkúta bò ó mọ́lẹ̀. Fojú inú wò ó ná—àní wọn ò tilẹ̀ sin òkú ọkùnrin tó ń lépa àtidi ọba yìí lọ́nà ẹ̀yẹ!c Lóòótọ́, ìkùgbù fa àbùkù fún Ábúsálómù.—2 Sámúẹ́lì 18:9-17.

      Yàgò fún Lílépa Ipò Ọlá Onímọtara-Ẹni-Nìkan

      13. Báwo ni ẹ̀mí ìlépa ipò ọlá ṣe lè ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà Kristẹni kan?

      13 Bí Ábúsálómù ṣe yára gòkè dé ipò agbára àti bó ṣe ṣubú láìpẹ́ ọjọ́ jẹ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì fún wa. Nínú ayé oníwàkiwà yìí, kì í ṣe nǹkan àjèjì mọ́ kí àwọn èèyàn máa pá kúbẹ́kúbẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá, nítorí pé wọ́n ń wá ojú rere ọ̀gá, kíyẹn sáà lè kà wọ́n sí tàbí bóyá kó lè fún wọn ní àwọn àǹfààní kan tàbí ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́. Nígbà kan náà, wọ́n tún lè máa fọ́nnu lójú àwọn tó kéré sí wọn, ní ìrètí pé wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ fajú àwọn yẹn mọ́ra, àti kí àwọn yẹn lè máa tì wọ́n lẹ́yìn. Bí a kò bá ṣọ́ra, irú ẹ̀mí ìlépa ipò ọlá bẹ́ẹ̀ lè ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà wa. Ó hàn gbangba pé èyí ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn kan ní ọ̀rúndún kìíní, tó mú kó pọndandan fún àwọn àpọ́sítélì láti fúnni ní ìkìlọ̀ lílágbára nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.—Gálátíà 4:17; 3 Jòhánù 9, 10.

      14. Èé ṣe tí a fi ní láti yẹra fún ẹ̀mí ìgbéra-ẹni-ga àti ti ìlépa ipò ọlá?

      14 Jèhófà kò ní àyè kankan fún àwọn tó ń hùmọ̀ àtigbé ara wọn ga ju àwọn ẹlòmíì lọ nínú ètò àjọ rẹ̀, ìyẹn àwọn tó ń gbìyànjú láti “máa wá ògo ara wọn.” (Òwe 25:27) Àní, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Jèhófà yóò ké gbogbo ètè dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in kúrò, ahọ́n tí ń sọ àwọn ohun ńláńlá.” (Sáàmù 12:3) Ábúsálómù ní ètè dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in. Ó ń sọ àwọn ohun kàǹkà-kàǹkà fún àwọn tó ń wá ojú rere wọn—gbogbo ẹ̀ gbògbò ẹ̀ kó sáà lè rí ipò ọlá tí kò tọ́ sí i gbà ni. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, ẹ wo ìbùkún ńlá tó jẹ́ fún wa láti wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará tí wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “[Ẹ má ṣe] ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ . . . kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.”—Fílípì 2:3.

      Sọ́ọ̀lù—Ọba Tí Kò Ní Sùúrù

      15. Báwo ni Sọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun mẹ̀tọ́mọ̀wà nígbà kan?

      15 Ìgbà kan wà tí Sọ́ọ̀lù, tó wá di ọba Ísírẹ́lì, jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Fún àpẹẹrẹ, gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ yẹ̀ wò. Nígbà tí Sámúẹ́lì wòlíì Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ìwúrí nípa rẹ̀, Sọ́ọ̀lù dáhùn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “Èmi kì í ha ṣe ọmọ Bẹ́ńjámínì tí ó kéré jù lọ nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, tí ìdílé mi sì jẹ́ èyí tí ìjámọ́ pàtàkì rẹ̀ kéré jù lọ nínú gbogbo ìdílé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Nítorí náà, èé ṣe tí o fi sọ irú ohun yìí fún mi?”—1 Sámúẹ́lì 9:21.

      16. Ọ̀nà wo ni Sọ́ọ̀lù gbà fi ẹ̀mí àìnísùúrù hàn?

      16 Àmọ́, lẹ́yìn náà, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Sọ́ọ̀lù pòórá. Nígbà tó lọ bá àwọn Filísínì jagun, ó lọ sí Gílígálì, níbi tó yẹ kó dúró sí de Sámúẹ́lì láti wá fi ẹbọ tu Ọlọ́run lójú. Nígbà tí Sámúẹ́lì ò dé ní àkókò tí wọ́n dá, Sọ́ọ̀lù fi ìkùgbù rú ẹbọ sísun náà fúnra rẹ̀. Bó ṣe ń parí rẹ̀ gẹ́ẹ́ ni Sámúẹ́lì dé. Sámúẹ́lì wá béèrè pé: “Kí ni ohun tí ìwọ ṣe?” Sọ́ọ̀lù fèsì pé: “Mo rí i pé àwọn ènìyàn ti fọ́n ká kúrò lọ́dọ̀ mi, àti ìwọ—ìwọ kò wá láàárín àwọn ọjọ́ tí a dá . . . Nítorí náà, mo ṣe é ní ọ̀ranyàn fún ara mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ sísun náà.”—1 Sámúẹ́lì 13:8-12.

      17. (a) Táa bá kọ́kọ́ wo ọ̀ràn náà, èé ṣe tó fi lè dà bí ẹni pé kò sí ohun tó burú nínú ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe? (b) Èé ṣe tí Jèhófà fi dẹ́bi fún Sọ́ọ̀lù nítorí àìnísùúrù rẹ̀?

      17 Táa bá kọ́kọ́ wo ọ̀ràn náà, ó lè dà bí ẹni pé ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe kò burú. Ó ṣe tán, àwọn èèyàn Ọlọ́run wà “nínú hílàhílo,” a ni wọ́n “lára dé góńgó,” wọ́n sì ń wárìrì nítorí ipò àìnírètí tí wọ́n wà. (1 Sámúẹ́lì 13:6, 7) Ká sọ tòótọ́, kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn lo ìdánúṣe nígbà tí ipò nǹkan bá béèrè pé ká ṣe bẹ́ẹ̀.d Àmọ́ ṣá o, rántí pé Jèhófà rí ọkàn-àyà wa, ó sì mọ èrò inú wa. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Nítorí ìdí èyí, ó ti ní láti rí àwọn nǹkan kan lára Sọ́ọ̀lù tí Bíbélì ò ròyìn ní tààràtà. Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà ti lè rí i pé ìgbéraga ló fà á tí Sọ́ọ̀lù kò fi ní sùúrù. Ó ṣeé ṣe kí Sọ́ọ̀lù ti bínú gan-an pé òun—ọba gbogbo Ísírẹ́lì—ní láti dúró de ẹnì kan tó wò gẹ́gẹ́ bí wòlíì kan tó ti darúgbó, tó ń fònídónìí-fọ̀ladọ́la. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, Sọ́ọ̀lù rò pé pípẹ́ tí Sámúẹ́lì pẹ́ ti fún òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìfẹ́ inú òun, kí òun sí fojú di ìtọ́ni ṣíṣe kedere tí wọ́n fún òun. Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Inú Sámúẹ́lì kò dùn sí ìdánúṣe tí Sọ́ọ̀lù lò rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bá Sọ́ọ̀lù wí gidigidi, ó sọ pé: “Ìjọba rẹ kì yóò pẹ́ . . . nítorí pé ìwọ kò pa ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún ọ mọ́.” (1 Sámúẹ́lì 13:13, 14) Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìkùgbù tún fa àbùkù.

      Yẹra fún Àìnísùúrù

      18, 19. (a) Ṣàpèjúwe bí àìnísùúrù ṣe lè mú kí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan hu ìwà ìkùgbù lóde òní. (b) Kí ló yẹ kí a rántí nípa ọ̀nà tí ìjọ Kristẹni ń gbà ṣiṣẹ́?

      18 Àkọsílẹ̀ ìwà ìkùgbù Sọ́ọ̀lù yìí wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àǹfààní wa. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Ó rọrùn fún wa gan-an láti bínú nítorí àìpé àwọn arákùnrin wa. Bíi ti Sọ́ọ̀lù, a lè ṣe aláìnísùúrù, kí a máa rò pé bí a bá fẹ́ kí nǹkan yọrí sí rere, a gbọ́dọ̀ ṣe wọ́n fúnra wa. Fún àpẹẹrẹ, ká sọ pé arákùnrin kan tayọ nínú bíbójútó àwọn ètò kan. Ó máa ń tẹ̀ lé àkókò, ó mọ gbogbo ìtọ́ni tó dé gbẹ̀yìn, ó sì lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó wá rí pé àwọn tó kù ò tiẹ̀ sún mọ́ òun rárá nínú ṣíṣe gbogbo nǹkan fínnífínní, wọn ò sì já fáfá tó bí òun ṣe fẹ́. Ṣé èyí wá sọ pé kó máà ní sùúrù? Ṣé ó wá yẹ kó máa ṣe lámèyítọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀, bóyá kó máa ṣe bí ẹni pé tí kì í bá ṣe nítorí ìsapá òun ni, kò sí ohun kan tí wọn ì bá ṣe yanjú, ìjọ ì bá sì ti fọ́? Èyí yóò jẹ́ ìkùgbù!

      19 Ní ti gidi, kí ló so ìjọ àwọn Kristẹni pọ̀ ṣọ̀kan? Ṣé mímọ bí a ṣe ń ṣe àbójútó ni? tàbí jíjẹ́ ọ̀jáfáfá? àbí bí ìmọ̀ ẹnì kan ṣe jinlẹ̀ tó? Lóòótọ́, àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe pàtàkì kí nǹkan lè máa lọ déédéé nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 14:40; Fílípì 3:16; 2 Pétérù 3:18) Àmọ́, Jésù sọ pé ìfẹ́ ni ohun àkọ́kọ́ tí a fi máa dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀. (Jòhánù 13:35) Ìdí nìyẹn tí àwọn alàgbà tó bìkítà, tí wọ́n sì wà létòlétò, fi mọ̀ pé ìjọ kì í ṣe ibi ìṣòwò kan tó nílò ọwọ́ líle; dípò ìyẹn, àwọn àgùntàn tí wọ́n ń fẹ́ àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ló wà níbẹ̀. (Aísáyà 32:1, 2; 40:11) Fífi ìkùgbù kọ̀ láti tẹ̀ lé irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ sábà máa ń yọrí sí asọ̀. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, àlàáfíà ni wíwà létòlétò lọ́nà ti Ọlọ́run máa ń mú wá.—1 Kọ́ríńtì 14:33; Gálátíà 6:16.

      20. Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

      20 Ìtàn Bíbélì nípa Kórà, Ábúsálómù, àti Sọ́ọ̀lù fi hàn kedere pé ìkùgbù ń fa àbùkù, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sínú ìwé Òwe orí kọkànlá ẹsẹ ìkejì. Àmọ́, ẹsẹ Bíbélì kan náà yẹn tún fi kún un pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” Kí ni ìmẹ̀tọ́mọ̀wà? Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ànímọ̀ yìí dáadáa, báwo la sì ṣe lè fi hàn pé a mẹ̀tọ́mọ̀wà lónìí? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.

      [Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Níwọ̀n bí Rúbẹ́nì ti jẹ́ àkọ́bí Jékọ́bù, àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tí Kórà mú ṣọ̀tẹ̀ ti ní láti kórìíra bí Mósè—tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Léfì—ṣe ní àṣẹ lé wọn lórí.

      b A ò dárúkọ Ṣílíábù, tó jẹ́ ọmọkùnrin tí Dáfídì bí ṣèkejì mọ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti bí i. Ó ṣeé ṣe kó ti kú ṣáájú àkókò tí Ábúsálómù bẹ̀rẹ̀ wàhálà rẹ̀.

      c Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, sísin òkú ẹnì kan jẹ́ ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì gan-an ni. Nítorí náà, fífi irú ìsìnkú bẹ́ẹ̀ du ẹnì kan sábà máa ń jẹ́ àbùkù gbáà, ó sì fi hàn pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kùnà ojú rere Ọlọ́run.—Jeremáyà 25:32, 33.

      d Fún àpẹẹrẹ, Fíníhásì yára kánkán láti dá àrùn lùkúlùkú tó pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dúró, Dáfídì sì gba àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ tí ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lù pa níyànjú láti dara pọ̀ mọ́ òun nínú jíjẹ búrẹ́dì àfihàn tó wà nínú “ilé Ọlọ́run.” Kò sí èyí tí Ọlọ́run dẹ́bi fún pé ó jẹ́ ìkùgbù nínú ọ̀ràn méjèèjì yìí.—Mátíù 12:2-4; Númérì 25:7-9; 1 Sámúẹ́lì 21:1-6.

  • “Ọgbọ́n Wà Pẹ̀lú Àwọn Amẹ̀tọ́mọ̀wà”
    Ilé Ìṣọ́—2000 | August 1
    • “Ọgbọ́n Wà Pẹ̀lú Àwọn Amẹ̀tọ́mọ̀wà”

      “Kí . . . ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé . . . kí o jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—MÍKÀ 6:8.

      1, 2. Kí ni ìmẹ̀tọ́mọ̀wà, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí ìkùgbù?

      ÀPỌ́SÍTÉLÌ kan tó lókìkí kọ̀ láti pe àfiyèsí sí ara rẹ̀. Onídàájọ́ kan tó jẹ́ onígboyà ní Ísírẹ́lì pe ara rẹ̀ ní ẹni tí ó kéré jù lọ nínú agbo ilé baba rẹ̀. Ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí gbà pé ó ní ibi tí ọlá àṣẹ òun mọ. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ló fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn.

      2 Òdìkejì ìkùgbù ni ìmẹ̀tọ́mọ̀wà. Ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ni ẹni tí kì í ka agbára àti àwọn ohun tó mọ̀ ọ́n ṣe sí bàbàrà, kì í sì í jọra rẹ̀ lójú tàbí kí ó máa ruga. Dípò tí ì bá fi máa gbéra ga, kí ó máa fẹgẹ̀, tàbí kí ó máa lépa ipò ọlá, ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà kì í kọjá àyè rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, ó sì máa ń gba ti ìmọ̀lára àti ojú ìwòye wọn rò.

      3. Ní ọ̀nà wo ni ọgbọ́n fi “wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà”?

      3 Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà jẹ́ ọlọgbọ́n nítorí pé ó ń tẹ̀ lé ipa ọ̀nà tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, ó sì ń yẹra fún ẹ̀mí ìkùgbù tó ń yọrí sí àbùkù. (Òwe 8:13; 1 Pétérù 5:5) Ọgbọ́n tó wà nínú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ni a rí nínú ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn bíi mélòó kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mẹ́ta táa mẹ́nu kàn nínú ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ yẹ̀ wò.

      Pọ́ọ̀lù—“Òṣìṣẹ́ Ọmọ Abẹ́” àti “Ìríjú”

      4. Kí ni àwọn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ní?

      4 Ẹnì kan tó gbajúmọ̀ gan-an ni Pọ́ọ̀lù jẹ́ láàárín àwọn Kristẹni ìjímìjí, a sì mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó rin ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà lójú òkun àti lórí ilẹ̀, ó sì dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀. Láfikún sí i, Jèhófà fi rírí àwọn ìran àti ẹ̀bùn fífi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀ jíǹkí Pọ́ọ̀lù. (1 Kọ́ríńtì 14:18; 2 Kọ́ríńtì 12:1-5) Ó tún mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ mẹ́rìnlá lára àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì báyìí. Ní kedere, a lè sọ pé òpò tí Pọ́ọ̀lù ṣe pọ̀ ju ti gbogbo àwọn àpọ́sítélì yòókù lọ.—1 Kọ́ríńtì 15:10.

      5. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà?

      5 Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ló ń mú ipò iwájú nínú ìgbòkègbodò Kristẹni, àwọn kan lè máa retí àtirí i kó máa yan fanda kiri, kódà kó tiẹ̀ máa fi ọlá àṣẹ tó ní ṣe fọ́rífọ́rí pàápàá. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Ó pe ara rẹ̀ ní ẹni tí ó “kéré jù lọ nínú àwọn àpọ́sítélì,” ó fi kún un pé: “Èmi kò sì yẹ ní ẹni tí a ń pè ní àpọ́sítélì, nítorí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 15:9) Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni tẹ́lẹ̀, Pọ́ọ̀lù ò lè gbàgbé láé pé tí kì í bá ṣe inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ni, òun ì bá máà ní ìbátan kankan pẹ̀lú Ọlọ́run, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti bó ṣe gbádùn àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Jòhánù 6:44; Éfésù 2:8) Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn, Pọ́ọ̀lù ò ronú pé àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀ tí òun gbé ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ti mú kí òun sàn ju àwọn yòókù lọ.—1 Kọ́ríńtì 9:16.

      6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nínú bó ṣe bá àwọn ará Kọ́ríńtì lò?

      6 Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Pọ́ọ̀lù fara hàn kedere nínú bó ṣe bá àwọn ará Kọ́ríńtì lò. Ó hàn gbangba pé àwọn kan lára wọn ń kan sáárá sí àwọn alábòójútó tí wọ́n kà sí gbajúmọ̀ láàárín wọn, títí kan Àpólò, Kéfà, àti Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 1:11-15) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò bẹ àwọn ará Kọ́ríńtì rí pé kí wọ́n gbóríyìn fún òun bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tó fẹ́ fi ìkansáárá wọn ṣe. Nígbà tó bá ń bẹ̀ wọ́n wò, kì í wá “pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọrégèé tàbí ọgbọ́n.” Dípò ìyẹn, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara rẹ̀ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni pé: “Kí ènìyàn díwọ̀n wa bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ọmọ abẹ́ Kristi àti ìríjú àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run.”a—1 Kọ́ríńtì 2:1-5; 4:1.

      7. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn, kódà nígbà tí ó ń fúnni ní ìmọ̀ràn?

      7 Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nígbà tó yẹ kó fúnni ní ìbáwí líle koko àti ìtọ́ni. Ó “fi ìyọ́nú Ọlọ́run” pàrọwà sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ “nítorí ìfẹ́” kì í ṣe lọ́lá àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì. (Róòmù 12:1, 2; Fílémónì 8, 9) Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi ṣe èyí? Nítorí pé ó ka ara rẹ̀ sí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” àwọn arákùnrin rẹ̀, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ‘ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ wọn.’ (2 Kọ́ríńtì 1:24) Láìsí àní-àní, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Pọ́ọ̀lù ló fà á tó fi jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún àwọn ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní.—Ìṣe 20:36-38.

      Fífi Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Lo Àwọn Àǹfààní Táa Ní

      8, 9. (a) Èé ṣe tó fi yẹ ká jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà? (b) Báwo ni àwọn tó ní ẹrù iṣẹ́ ṣe lè fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn?

      8 Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni lónìí. Bó ti wù kí ẹrù iṣẹ́ tí a gbé lé wa lọ́wọ́ ti tó, kò sí èyíkéyìí nínú wa tó gbọ́dọ̀ ronú pé òun sàn ju àwọn yòókù lọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan èrò inú ara rẹ̀ jẹ.” (Gálátíà 6:3) Èé ṣe? Nítorí pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23; 5:12) Bẹ́ẹ̀ ni, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé gbogbo wa ló jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú látọ̀dọ̀ Ádámù. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ táa ní kò lè mú wa kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Oníwàásù 9:2) Bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Pọ́ọ̀lù, tí kì í bá ṣe inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ni, ẹ̀dá ènìyàn ì bá máà lájọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti sísìn ín ní àwọn ipò pàtàkì kan.—Róòmù 3:12, 24.

      9 Mímọ èyí kò ní jẹ́ kí ẹnì kan tó mẹ̀tọ́mọ̀wà máa fi àwọn àǹfààní tó ní yangàn tàbí kó máa ganpá nítorí àwọn àṣeyọrí rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 4:7) Nígbà tó bá ń fúnni nímọ̀ràn tàbí ìtọ́sọ́nà, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ni—kì í ṣe bí ọ̀gá. Dájúdájú, yóò jẹ́ ohun tí kò dára rárá kí ẹnì kan tí òye rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ kan tayọ máa wá ìyìn látọ̀dọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tàbí kí ó fẹ́ kí wọ́n máa kan sáárá sí òun. (Òwe 25:27; Mátíù 6:2-4) Kìkì ìyìn tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn wá ni ojúlówó ìyìn—ó sì gbọ́dọ̀ ti ọkàn wọn wá láìjẹ́ pé a bẹ̀bẹ̀ fún un. Bí irú ìyìn bẹ́ẹ̀ bá wá, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó mú wa ro ara wa ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.—Òwe 27:2; Róòmù 12:3.

      10. Ṣàlàyé bí àwọn kan tó dà bíi pé wọ́n wà ní ipò rírẹlẹ̀ ṣe lè jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́” ní ti gidi.

      10 Nígbà tí a bá gbé àwọn ẹrù iṣẹ́ kan lé wa lọ́wọ́, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún pípe àfiyèsí sí ara wa jù, kí a máa fún àwọn ará ní ìmọ̀lára pé tí kì í bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ ìsapá àti agbára tiwa ni, ìjọ ì bá má lè dúró. Fún àpẹẹrẹ, a lè ní ẹ̀bùn ìkọ́ni tó tayọ. (Éfésù 4:11, 12) Àmọ́, bí a bá jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, a ó mọ̀ pé kì í ṣe orí pèpéle nìkan ni gbogbo ẹ̀kọ́ pàtàkì-pàtàkì tí à ń kọ́ nínú ìpàdé ìjọ ti ń wá. Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ kì í wú ọ lórí nígbà tóo bá rí obí anìkantọ́mọ tó ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba déédéé? Tàbí ọkàn kan tó sorí kọ́ tí kì í pa ìpàdé jẹ láìka ìmí ẹ̀dùn pé òun kò já mọ́ nǹkankan tó máa ń ní sí? Tàbí ọ̀dọ́ kan tó ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí lójú gbogbo ipa búburú tí ilé ìwé àti àwọn ibòmíràn máa ń ní lórí ẹni? (Sáàmù 84:10) Àwọn wọ̀nyí lè má gbajúmọ̀. Àwọn ẹlòmíràn lè má tiẹ̀ mọ gbogbo àdánwò ìwà títọ́ tí wọ́n dójú kọ. Síbẹ̀, wọ́n lè jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́” bíi ti àwọn tó gbajúmọ̀. (Jákọ́bù 2:5) Ó ṣe tán, ní àbárèbábọ̀, ìṣòtítọ́ ni yóò mú wa jèrè ojú rere Jèhófà.—Mátíù 10:22; 1 Kọ́ríńtì 4:2.

      Gídíónì—Ẹni Tí “Ó Kéré Jù Lọ” ní Ilé Baba Rẹ̀

      11. Ọ̀nà wo ni Gídíónì gbà fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nígbà tó ń bá áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ̀rọ̀?

      11 Gídíónì, ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ akíkanjú látinú ẹ̀yà Mánásè gbé ayé ní àkókò kan tí rúkèrúdò wà nínú ìtàn Ísírẹ́lì. Fún ọdún méje gbáko ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run fi jìyà lábẹ́ ìnilára àwọn Mídíánì. Àmọ́, àkókò wá tó wàyí tí Jèhófà yóò dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè. Nítorí náà, áńgẹ́lì kan fara han Gídíónì, ó sì wí fún un pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ akíkanjú, alágbára ńlá.” Gídíónì mẹ̀tọ́mọ̀wà, nítorí náà kò wá bẹ̀rẹ̀ sí yan kọ́ńdú-kọ́ńdú kiri nítorí àpọ́nlé tí kò retí yìí. Dípò ìyẹn, ó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Dákun, olúwa mi, ṣùgbọ́n bí Jèhófà bá wà pẹ̀lú wa, èé ṣe nígbà náà, tí gbogbo èyí fi wá sórí wa?” Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé bí ọ̀ràn ṣe rí, ó sì wí fún Gídíónì pé: “Dájúdájú, ìwọ yóò sì gba Ísírẹ́lì là kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ Mídíánì.” Báwo ni Gídíónì ṣe fèsì? Kàkà tí Gídíónì ì bá fi bẹ́ mọ́ iṣẹ́ yìí, kí ó gbà á gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan fún òun láti di akọni ní gbogbo ilẹ̀ náà, ńṣe ló fèsì pé: “Dákun, Jèhófà. Kí ni kí n fi gba Ísírẹ́lì là? Wò ó! Ẹgbẹ̀rún tèmi ni èyí tí ó kéré jù lọ ní Mánásè, èmi sì ni ó kéré jù lọ ní ilé baba mi.” Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà gidi lèyí!—Àwọn Onídàájọ́ 6:11-15.

      12. Báwo ni Gídíónì ṣe fi ọgbọ́n inú hàn nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un?

      12 Jèhófà dán Gídíónì wò kó tó di pé ó rán an lọ sójú ogun. Lọ́nà wo? A sọ fún Gídíónì pé kí ó wó pẹpẹ tí bàbá rẹ̀ kọ́ fún Báálì, kí ó sì gé òpó ọlọ́wọ̀ tí ó wà ní ẹgbẹ́ rẹ̀ lulẹ̀. Iṣẹ́ yìí gba ìgboyà, àmọ́ Gídíónì tún fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ọgbọ́n inú hàn nínú ọ̀nà tó gbà ṣe iṣẹ́ náà. Dípò tí Gídíónì ì bá fi fi ara rẹ̀ ṣe ìran àpéwò, òru ọ̀gànjọ́ ló fi ṣe iṣẹ́ náà, nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lè rí i. Síwájú sí i, tìṣọ́ratìṣọ́ra ni Gídíónì ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un yìí. Ó mú àwọn ìránṣẹ́ mẹ́wàá—bóyá ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí àwọn kan lè máa ṣọ́nà nígbà tí àwọn tó kù bá ń ràn án lọ́wọ́ láti wó pẹpẹ àti òpó ọlọ́wọ̀ náà.b Bó ti wù kó rí, pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà, Gídíónì ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un, nígbà tí àkókò sì tó, Ọlọ́run lò ó láti gba Ísírẹ́lì là lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì.—Àwọn Onídàájọ́ 6:25-27.

      Fífi Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti Ọgbọ́n Inú Hàn

      13, 14. (a) Báwo la ṣe lè fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nígbà tí a bá nawọ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn sí wa? (b) Báwo ni Arákùnrin A. H. Macmillan ṣe fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ nínú fífi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn?

      13 Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ látinú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Gídíónì. Fún àpẹẹrẹ, báwo la ṣe máa hùwà nígbà táa bá nawọ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn sí wa? Ṣé ohun tó kọ́kọ́ máa wá sọ́kàn wa ni ọlá àti iyì táa máa rí níbẹ̀? Àbí ṣé a máa fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wo tàdúràtàdúrà, kí a sì wò ó bóyá a kún ojú ìwọ̀n ohun tí iṣẹ́ náà ń béèrè? Arákùnrin A. H. Macmillan, tí ó parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní ọdún 1966, fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún wa lórí ọ̀ràn yìí. C. T. Russell, tí ó jẹ́ ààrẹ àkọ́kọ́ fún Watch Tower Society, nígbà kan béèrè èrò Arákùnrin Macmillan nípa ẹni tó lè bójú tó iṣẹ́ yìí nígbà tí òun bá ṣe aláìsí. Nínú ìjíròrò tí ó tẹ̀ lé e, Arákùnrin Macmillan kò kàn ṣe báyẹn yan ara rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Níkẹyìn, Arákùnrin Russell ké sí Arákùnrin Macmillan pé kó gbé títẹ́wọ́gba iṣẹ́ náà yẹ̀ wò. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Arákùnrin Macmillan kọ̀wé pé: “Ńṣe ni iyè mi kàn fò lọ lórí ìdúró. Mo ronú nípa rẹ̀ dáadáa, mo rò ó, mo tún un rò, mo sì gbàdúrà nípa rẹ̀ fúngbà díẹ̀ kí n tó wá sọ fún un níkẹyìn pé inú mi yóò dùn láti ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́.”

      14 Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí Arákùnrin Russell kú, tí àyè ààrẹ Watch Tower Society sì ṣófo. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Arákùnrin Macmillan ló di ipò yìí mú ní àwọn àkókò tí Arákùnrin Russell lò kẹ́yìn nínú ìrìn àjò ìwàásù rẹ̀, arákùnrin kan wá sọ fún un pé: “Mac, ọ̀nà ti ṣí sílẹ̀ fún ọ láti gorí àlééfà báyìí. Ìwọ ni àkànṣe aṣojú Arákùnrin Russell láti ìgbà tó ti lọ, ó sì sọ fún gbogbo wa pé ohun tóo bá ti sọ ni ká máa ṣe. Tóò, ó ti lọ báyìí, kò sì lè padà wá mọ́. Ó dà bí ẹni pé ìwọ ni ọpọ́n sún kàn.” Arákùnrin Macmillan fèsì pé: “Arákùnrin, bí o ṣe ń ronú yẹn kọ́ lọ̀rọ̀ rí. Iṣẹ́ Olúwa lèyí, kìkì ipò tí o sì lè dé nínú ètò Olúwa ni èyí tí Olúwa bá rí i pé ó yẹ láti fún ọ; ó sì dá mi lójú pé èmi kọ́ ni iṣẹ́ yẹn tọ́ sí.” Arákùnrin Macmillan wá dámọ̀ràn ẹlòmíràn fún ipò náà. Bíi tí Gídíónì, òun náà mọ̀wọ̀n ara rẹ̀—ì bá dára tí àwa náà bá lè ṣe bẹ́ẹ̀.

      15. Àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ wo la lè gbà lo ìfòyemọ̀ nígbà táa bá ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn?

      15 Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà nínú ọ̀nà tí a gbà ń ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wa. Gídíónì jẹ́ olóye, ó sì gbìyànjú láti má ṣe mú àwọn alátakò rẹ̀ bínú láìnídìí. Bákan náà, nínú iṣẹ́ ìwàásù wa, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà, kí a sì jẹ́ olóye nípa bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀. Lóòótọ́, ogun tẹ̀mí là ń jà láti dojú “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” àti “àwọn ìrònú” dé. (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ tó máa tàbùkù àwọn ẹlòmíràn tàbí kí a ṣe ohunkóhun tó lè mú wọn bínú sí iṣẹ́ wa. Dípò ìyẹn, a gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ojú ìwòye wọn, kí a tẹnu mọ́ ohun ti àwa àtàwọn jọ gbà pé òótọ́ ni, kí a sì máa darí àfiyèsí wọn sí àwọn apá tó lè ṣe wọ́n láǹfààní nínú iṣẹ́ wa.—Ìṣe 22:1-3; 1 Kọ́ríńtì 9:22; Ìṣípayá 21:4.

      Jésù—Àpẹẹrẹ Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Tó Ga Jù Lọ

      16. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun?

      16 Àpẹẹrẹ ìmẹ̀tọ́mọ̀wà tó ga jù lọ ni ti Jésù Kristi.c Pẹ̀lú bí Jésù ṣe ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba rẹ̀ tó, kò lọ́ tìkọ̀ láti gbà pé àwọn ọ̀ràn kan wà tó kọjá ibi tí ọlá àṣẹ òun mọ. (Jòhánù 1:14) Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí màmá Jákọ́bù àti Jòhánù wá bá a pé kí àwọn ọmọ òun jókòó sí ẹ̀gbẹ́ Jésù nínú ìjọba rẹ̀, Jésù sọ pé: “Jíjókòó yìí ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní òsì mi kì í ṣe tèmi láti fi fúnni.” (Mátíù 20:20-23) Ní àkókò mìíràn, Jésù gbà láìjanpata pé: “Èmi kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara mi . . . kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mo ń wá, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 5:30; 14:28; Fílípì 2:5, 6.

      17. Báwo ni Jésù ṣe fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nínú bó ṣe hùwà sí àwọn ẹlòmíràn?

      17 Gbogbo ọ̀nà ni Jésù fi ga ju ẹ̀dá ènìyàn aláìpé lọ, ó sì ní ọlá àṣẹ tí kò láfiwé láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, Baba rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, Jésù mẹ̀tọ́mọ̀wà nínú bó ṣe hùwà sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Kì í ṣe pé ó kan ń rọ́ ìmọ̀ sórí wọn, kí wọ́n lè máa kan sáárá sí i. Ọ̀rọ̀ wọn ká a lára, ó fi ìyọ́nú hàn sí wọn, ó sì gba ti àìní wọn rò. (Mátíù 15:32; 26:40, 41; Máàkù 6:31) Nípa bẹ́ẹ̀, bí Jésù tilẹ̀ jẹ́ ẹni pípé, kì í ṣe aṣefínnífínní dóríi bíńtín. Kò béèrè ohun tó ju agbára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ wọn rí, kò sì gbé ẹrù tí wọn ò lè rù kà wọ́n lórí. (Jòhánù 16:12) Abájọ tí ọ̀pọ̀ fi rí ìtura lọ́dọ̀ rẹ̀!—Mátíù 11:29.

      Fara Wé Àpẹẹrẹ Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Jésù

      18, 19. Báwo la ṣe lè fara wé ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Jésù nínú (a) ojú tí a fi ń wo àwọn ẹlòmíràn, àti (b) bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò?

      18 Bí ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí bá mẹ̀tọ́mọ̀wà, a jẹ́ pé àwa náà gbọ́dọ̀ mẹ̀tọ́mọ̀wà gan-an nìyẹn. Kì í sábà rọrùn fún ẹ̀dá ènìyàn aláìpé láti gbà pé àwọn ò ní ọlá àṣẹ tí kò láàlà. Àmọ́ ṣá o, kí àwọn Kristẹni lè fara wé Jésù, wọ́n ń tiraka láti mẹ̀tọ́mọ̀wà. Wọn kì í jọ ara wọn lójú débi tí wọn kò fi ní lè fi ẹrù iṣẹ́ lé àwọn tó bá tóótun lọ́wọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni wọn kì í ṣe agbéraga tàbí ẹni tí kì í fẹ́ gba ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ àwọn tó láṣẹ láti tọ́ni sọ́nà. Nípa fífi ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ hàn, wọ́n ń jẹ́ kí ohun gbogbo nínú ìjọ ṣẹlẹ̀ “lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́ríńtì 14:40.

      19 Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà yóò tún sọ wá di ẹni tí ń fòye báni lò nínú ohun tí a ń retí látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, yóò sì jẹ́ kí a máa gba ti àìní wọn rò. (Fílípì 4:5) A lè ní agbára àti okun táwọn ẹlòmíì ò ní. Síbẹ̀, tí a bá jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, a ò ní máa retí pé ohun tí a fẹ́ ni àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ máa ṣe ní gbogbo ìgbà. Ní mímọ̀ pé olúkúlùkù ló ní ibi tí agbára rẹ̀ mọ, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà yóò jẹ́ kí a fara da ìkùdíẹ̀-káàtó àwọn ẹlòmíràn. Pétérù kọ̀wé pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”—1 Pétérù 4:8.

      20. Kí la lè ṣe láti borí ìtẹ̀sí èyíkéyìí láti di aláìmẹ̀tọ́mọ̀wà?

      20 Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́ tẹ́lẹ̀, ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní tòótọ́. Àmọ́, tí o bá wá rí i pé o ní ìtẹ̀sí láti di aláìmẹ̀tọ́mọ̀wà tàbí oníkùgbù ńkọ́? Má ṣe banú jẹ́. Dípò ìyẹn, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì, tó gbàdúrà pé: “Fa ìránṣẹ́ rẹ sẹ́yìn kúrò nínú àwọn ìṣe ìkùgbù; má ṣe jẹ́ kí wọ́n jọba lé mi lórí.” (Sáàmù 19:13) Nípa fífarawé ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn bíi Pọ́ọ̀lù, Gídíónì, àti—lékè gbogbo ẹ̀dá ènìyàn mìíràn—Jésù Kristi, àwa fúnra wa yóò rí òtítọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ náà pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”—Òwe 11:2.

      [Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí “òṣìṣẹ́ ọmọ abẹ” lè túmọ̀ sí ẹrú kan tí ó ń fi àjẹ̀ tukọ̀ lórí ìjókòó ìsàlẹ̀ nínú ọkọ̀ òkun ńlá kan. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, “ìríjú” lè jẹ́ ẹni tí a fi ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, bíi pé kó máa bójú tó dúkìá kan. Síbẹ̀síbẹ̀, lójú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀gá, ìríjú ò yàtọ̀ sí ẹrú nínú ọkọ̀ òkun alájẹ̀.

      b A ò gbọ́dọ̀ ka ọgbọ́n inú àti ìṣọ́ra tí Gídíónì lò sí ìwà ojo. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí jíjẹ́ ojo, ìwé Hébérù 11:32-38 jẹ́rìí sí ìwà akin rẹ̀, níbi tí a ti ka Gídíónì mọ́ àwọn tí “a sọ . . . di alágbára” àti àwọn tí “wọ́n di akíkanjú nínú ogun.”

      c Nítorí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ní ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni nínú, a kò lè sọ pé Jèhófà jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Àmọ́ o, ó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.—Sáàmù 18:35.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́