-
Gbádùn Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́runIlé Ìṣọ́—2002 | December 1
-
-
9 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó pé: “Bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a [ìyẹn òye] bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, . . . ” (Òwe 2:4) Èyí jẹ́ ká ronú nípa èrè àwọn awakùsà látayébáyé tí wọ́n ti ń wá fàdákà àti wúrà táráyé kà sí ìṣúra iyebíye . Àwọn èèyàn ti gbẹ̀mí ara wọn nítorí wúrà. Àwọn mìíràn ti fi gbogbo ìgbésí ayé wọn wá a. Àmọ́, báwo ni wúrà tiẹ̀ ṣe níye lórí tó lóòótọ́? Ká ló o sọ nù sínú aṣálẹ̀ kan tí òùngbẹ sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ ọ́ pa, èwo lo máa yàn nínú: ègé wúrà ńlá kan àti ife omi kan? Síbẹ̀, ẹ wo báwọn èèyàn ṣe ń fi ìtara wá wúrà tó, tó sì jẹ́ pé ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìníyelórí rẹ̀ kò dúró sójú kan!a Nígbà náà, ẹ ò rí i pé ó yẹ ká fi ìtara tó ju èyí lọ wá ọgbọ́n, ìfòyemọ̀, òye Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀! Àwọn àǹfààní wo la sì máa rí nínú wíwá àwọn nǹkan wọ̀nyí?—Sáàmù 19:7-10; Òwe 3:13-18.
-
-
Gbádùn Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́runIlé Ìṣọ́—2002 | December 1
-
-
a Látọdún 1979 ni iye owó wúrà ò ti dúró sójú kan. Àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rin [$850] dọ́là ni wọ́n ń ta wúrà gíráàmù mọ́kànlélọ́gbọ̀n lọ́dún 1980. Nígbà tó fi máa di 1999, ó ti wálẹ̀ sórí iye tó lé ní àádọ́ta-lé-rúgba dọ́là ó lé méjì [$252].
-